Ìkésíni Tààràtà
1. Ìgbà wo la máa bẹ̀rẹ̀ sí í pín ìwé ìkésíni sí àpéjọ àgbègbè?
1 Tó o bá náwó nára gan-an láti se àkànṣe àsè kan fún àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ rẹ, ó dájú pé ó máa yá ọ lára láti pe àwọn èèyàn wá síbi àpèjẹ náà. Bákan náà, iṣẹ́ ti lọ gan-an lórí àsè tẹ̀mí tá a máa gbádùn ní àpéjọ àgbègbè wa tó ń bọ̀. Tí àpéjọ àgbègbè wa bá ti ku ọ̀sẹ̀ mẹ́ta, Jèhófà fún wa láǹfààní láti bẹ̀rẹ̀ sí í pe àwọn èèyàn wá sí àpéjọ náà. Kí ló máa mú kó yá wa lára láti pe àwọn èèyàn wá sí àpéjọ yìí?
2. Kí ló máa mú ká kópa kíkún nínú pípín ìwé ìkésíni sí àpéjọ àgbègbè yìí?
2 Tá a bá ronú nípa bí àwa fúnra wa ṣe máa ń jàǹfààní látinú àsè tẹ̀mí tó ń tuni lára tí Jèhófà ń pèsè fún wa láwọn àpéjọ wa, èyí á mú ká kópa kíkún nínú pínpín ìwé ìkésíni sí àpéjọ yìí. (Aísá. 65:13, 14) Ó yẹ ká rántí pé àwọn ìwé ìkésíni tí à ń pín lọ́dọọdún máa ń méso rere jáde. (Wo àpótí náà, “Ó Ń Méso Rere Jáde.”) Àwọn kan lára àwọn tá a fún ní ìwé ìkésíni máa wá sí àpéjọ náà, àwọn kan ò sì ní wá. Iye èèyàn yòówù kó wá sí àpéjọ náà, akitiyan tá a ṣe nígbà tí à ń pín ìwé ìkésíni yìí máa mú ìyìn bá orúkọ Jèhófà, á sì tún fi hàn pé a jẹ́ ọ̀làwọ́ bíi tirẹ̀.—Sm. 145:3, 7; Ìṣí. 22:17.
3. Báwo la ṣe máa pín ìwé ìkésíni náà?
3 Ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ìjọ kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu bí ìjọ ṣe máa pín ìwé ìkésíni yìí tó fi máa délé-dóko láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn. Àwọn ló sì máa sọ bóyá a lè fi ìwé ìkésíni sí ẹnu ọ̀nà àwọn tí kò bá sí nílé tàbí bóyá kí a pín in nígbà tá a bá ń wàásù láwọn ibi tí èrò pọ̀ sí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. Tá a bá ń pín ìwé ìkésíni lópin ọ̀sẹ̀, a lè fún àwọn èèyàn ní ìwé ìròyìn pẹ̀lú ìwé ìkésíni náà níbi tá a bá ti rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn tá a bá ti pín ìwé ìkésíni náà tán, ẹ wo bí inú wa ṣe máa dùn tó láti mọ̀ pé àwa náà fi ìtara kópa nínú rẹ̀ tá a sì tún pe ọ̀pọ̀ èèyàn láti wá gbádùn àsè tẹ̀mí tí Jèhófà pèsè!