Ìpolongo Tó Méso Rere Jáde
Tó bá ku ọ̀sẹ̀ mẹ́ta ká lọ sí àpéjọ àgbègbè wa, a tún máa bẹ̀rẹ̀ sí í pín ìwé ìkésíni láti pe àwọn èèyàn sí àpéjọ náà. Ó ní ìdí pàtàkì tá a fi ń pín ìwé ìkésíni yìí lọ́dọọdún. Àwọn tá a pè tí wọ́n sì wá sí àpéjọ náà máa ń gbádùn àwọn àsọyé Bíbélì, wọ́n tún máa ń mọyì bí nǹkan ṣe ń lọ létòlétò tó sì jẹ́ pé olùyọ̀ǹda ara ẹni ni gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Wọ́n tún máa ń mọrírì ìṣọ̀kan tó wà láàárín wa àti ìwà rere tá à ń hù. (Sm. 110:3; 133:1; Aísá. 65:13, 14) Ǹjẹ́ ìwé ìkésíni tá à ń pín yìí máa ń méso rere jáde, pàápàá tó bá jẹ́ pé àwọn tá a pè gbọ́dọ̀ rin ìrìn-àjò ọ̀nà jíjìn lọ sí àpéjọ náà?
Lẹ́yìn àpéjọ àgbègbè ọdún 2011, obìnrin kan tó rí ìwé ìkésíni lẹ́nu ilẹ̀kùn rẹ̀ kọ lẹ́tà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa kan. Obìnrin yìí máa ń sá pa mọ́ nígbàkigbà tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá ti kan ilẹ̀kùn rẹ̀. Ohun tó kọ nìyí: “Mo ní ilé tó rẹwà gan-an, mo ní ọkọ gidi, mo sì gbà pé mo ti ní ohun gbogbo tó lè fún mi láyọ̀. Àmọ́ mi ò láyọ̀, mi ò sì mọ ibi tí ìgbésí ayé mi dorí kọ. Ìdí nìyí tí mo fi pinnu pé màá rin ìrìn-àjò nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti ogún [320] kìlómítà lọ sí àpéjọ náà lọ́jọ́ Sátidé.” Torí bó ṣe gbádùn àpéjọ yẹn tó, ó pe ọkọ rẹ̀ lórí fóònù pé òun máa sùn di ọjọ́ kejì láti gbádùn ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ Sunday. Ó sọ pé: “Gbogbo àsọyé tí wọ́n sọ níbẹ̀ ni mo tẹ́tí sí, mo sì bá ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófa pàdé níbẹ̀, mo bá pinnu pé mi ò fẹ́ kó parí síbẹ̀.” Nígbà tó délé, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, oṣù mẹ́rin lẹ́yìn náà ló di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi. Ó ní: “Mo dúpẹ́ pé mo rí ìwé ìkésíni yẹn lẹ́nu ọ̀nà mi, ìgbésí ayé mi ti wá nítumọ̀ báyìí!”
Àwọn kan lára àwọn tá a bá fún ní ìwé ìkésíni máa wá. Torí náà, rí i pé o fi ìtara kópa nínú ìpolongo yìí. Kó èyí tó bá ṣẹ́ kù lára ìwé náà wá sí àpéjọ náà, kó o lè lò ó láti fi wàásù láìjẹ́ bí àṣà.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]
Báwo La Ṣe Máa Pín Ìwé Ìkésíni Náà?
Ká bàa lè pín ìwé ìkésíni yìí kárí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, ó gba pé ká má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa pọ̀. Lẹ́yìn tá a bá ti kí onílé, a lè sọ pé: “Ibi gbogbo kárí ayé la ti ń fi ìwé yìí pe àwọn èèyàn. Tiyín rèé. Ẹ máa rí àlàyé púpọ̀ sí i nínú ìwé ìkésíni yìí.” Fi ọ̀yàyà sọ̀rọ̀. Tẹ́ ẹ bá ń pín ìwé ìkésíni náà lópin ọ̀sẹ̀, kẹ́ ẹ tún fi ìwé ìròyìn lọ àwọn èèyàn, tẹ́ ẹ bá rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀.