Bá A Ṣe Máa Pe Àwọn Èèyàn Síbi Àpéjọ Àgbègbè “Máa Tọ Kristi Lẹ́yìn!”
Tá A Máa Ṣe Jákèjádò Ayé Àwọn Akéde Tún Máa Pín Àkànṣe Ìwé Ìléwọ́
1 Ìwé ìléwọ́ tá a pín kárí ayé lọ́dún tó kọjá láti pe àwọn olùfìfẹ́hàn wá síbi Àpéjọ Àgbègbè “Ìdáǹdè Kù sí Dẹ̀dẹ̀!” ṣe gudugudu méje. Àwọn tó jẹ́ ìpè àkànṣe yẹn fúngbà àkọ́kọ́ fojú ara wọn rí àpèjẹ tẹ̀mí tí ń gbéni ró táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń gbádùn. (Aísá. 65:13) Inú wọn sì dùn láti wà láàárín ẹgbẹ́ ará wa tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́, tó sì wà níṣọ̀kan kárí ayé. (Sm. 133:1) Nítorí káwọn èèyàn bàa lè gbọ́ nípa Àpéjọ Àgbègbè “Máa Tọ Kristi Lẹ́yìn!” tó ń bọ̀ lọ́nà yìí, kí wọ́n sì wá, a tún máa pín ìwé ìléwọ́ kan tá a dìídì ṣe láti fi pè wọ́n.
2 Àṣeyọrí Ọdún Tó Kọjá: Ìròyìn tá a gbọ́ kárí ayé fi hàn pé ìbùkún yabuga ni fífi tá a fi ìwé pe àwọn èèyàn sí Àpéjọ Àgbègbè “Ìdáǹdè Sún Mọ́lé!” yọrí sí. Lọ́pọ̀ ibi làwọn oníròyìn ti bá wa gbé ìpolongo náà sójú táyé lọ́nà tó wúni lórí. Bí àpẹẹrẹ, ní ìlú kan, ìwé ìròyìn kan tẹ àpilẹ̀kọ olópòó ìlà mẹ́fà jáde nípa ìpolongo náà, ó ní: “Káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bàa lè rí gbogbo èèyàn pè síbi àpéjọ wọn tó ń bọ̀ lọ́nà, ńṣe ni wọ́n ṣètò àkànṣe kan láti wá àwọn aládùúgbò wọn rí, wọ́n fi kún wákàtí tó yẹ kí wọ́n fi wá wọn, wọ́n ń rin lọ sáwọn ibi tó jìnnà gan-an, wọn ò sì jáfara.” Ètò tá a ṣe láti pín ìwé ìléwọ́ yẹn jọ àwọn oníròyìn nílùú kan báyìí lójú débi táwọn náà fi gbé e sáfẹ́fẹ́, èyí sì mú kí ìpolongo náà túbọ̀ délé dóko. Ó kéré tán, ìwé ìròyìn mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló sọ ohun tó dáa nípa ìgbòkègbodò wa ṣáájú àpéjọ náà. Ó ju ojú ìwé méjì lọ tí ọ̀gbẹ́ni akọ̀ròyìn kan fi kọ àpilẹ̀kọ tó kún rẹ́rẹ́ mélòó kan nípa wa sínú ìwé ìròyìn kan tó máa ń jáde lọ́jọọjọ́ Sunday. Àwọn àpilẹ̀kọ náà ṣàlàyé nípa àwọn nǹkan tá a gbà gbọ́, nípa ìṣọ̀kan tó wà láàárín wa, nípa ìwé ìléwọ́ tá a pín àti àpéjọ àgbègbè yẹn. Nígbà tí arábìnrin wa kan fi ìwé náà han onílé kan, ńṣe ni obìnrin onílé náà gba ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu, ó ní: “Àbẹ́ ò rí nǹkan, òun gan-an ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kà nípa rẹ̀ nínú ìwé ìròyìn yìí o!” Onílé míì sọ pé: “Ọ̀rọ̀ nípa yín ni mò ń kà lọ́wọ́ tẹ́ ẹ fi dé yìí! Ṣé ìwé ìléwọ́ tèmi lẹ mú wá?” Ó tún wá sọ pé, “Ohun tó yẹ kẹ́yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ṣe gan-an lẹ̀ ń ṣe yìí!”
3 Ọ̀pọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn ló mú ìwé ìpè yẹn dání wọ Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Àwọn olùfìfẹ́hàn kan ò tiẹ̀ fi bó ṣe nira tó láti wakọ̀ fún ọ̀pọ̀ wákàtí pè, wọ́n rí i pé àwọn wà ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ yẹn. Ìsapá tá a fi taratara ṣe láti pe àwọn ẹlòmíì wá ló jẹ́ kí iye àwọn tó wá pọ̀ bẹ́ẹ̀. Orílẹ̀-èdè kan ti ẹ̀ wà tó jẹ́ pé, àwọn tó wá tó ìlọ́po mẹ́ta àwọn tèṣí.
4 Bá A Ṣe Lè Kárí Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Wa: Ẹ lè bẹ̀rẹ̀ sí í pín ìwé ìléwọ́ yìí nígbà tí àpéjọ tá a yan ìjọ yín sí bá ti ku ọ̀sẹ̀ mẹ́ta. Ẹ sa gbogbo ipá yín kẹ́ ẹ bàa lè kárí gbogbo ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Àwọn ìjọ tí ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn bá pọ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìwé ìléwọ́ náà há ibi tó bá bójú mu lẹ́nu ọ̀nà àwọn tí ò bá sí nílé, bí àpéjọ tá a yan ìjọ wọn sí bá ti ku ọ̀sẹ̀ kan. Kí ìjọ kọ̀ọ̀kan sapá láti pín gbogbo ìwé ìléwọ́ tá a bá kó ránṣẹ́ sí wọn tán, kí wọ́n sì rí i pé àwọn kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ wọn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Ẹ lè kó èyí tó bá ṣẹ́ kù fáwọn aṣáájú-ọ̀nà.
5 Ohun Tó O Máa Sọ: O lè sọ pé: “Kárí ayé là ń fi ìwé yìí pe àwọn èèyàn síbi àpéjọ pàtàkì kan tó ń bọ̀ lọ́nà. Tiyín nìyí. Àwọn nǹkan míì tẹ́ ẹ ní láti mọ̀ wà nínú ìwé yìí.” Tá a bá jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa mọ níwọ̀n, á rọrùn fún wa láti pín ìwé náà dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn. Bá a bá sì rẹ́ni tó béèrè ìbéèrè lẹ́yìn tó o ti fún un níwèé yìí, ohun tó tọ́ ni pé kó o dá a lóhùn. Bí ẹni náà bá sì nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ tó o bá a sọ, kọ àwọn nǹkan tó ò ní fẹ́ gbà gbé nípa rẹ̀ sílẹ̀, kó o má sì pẹ́ ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀.
6 Ẹ ò rí i bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká sapá láti tọ Kristi lẹ́yìn! (Jòh. 3:36) Àpéjọ àgbègbè tó ń bọ̀ lọ́nà á ran gbogbo àwọn tó bá wá síbẹ̀ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Kò síyè méjì pé a óò tún jẹ́rìí délé dóko bí gbogbo wa bá tún sapá lọ́tẹ̀ yìí láti pín ìwé ìléwọ́ tá a máa fi pe àwọn èèyàn síbi Àpéjọ Àgbègbè “Máa Tọ Kristi Lẹ́yìn!” Nítorí náà, sapá láti rí i pé o pe ọ̀pọ̀ èèyàn. Ǹjẹ́ kí Jèhófà bù kún ìsapá yín bẹ́ ẹ ṣe ń gbìyànjú láti ṣe gbogbo ohun tẹ́ ẹ bá lè ṣe láti rí i pé ìwé ìléwọ́ náà dọ́wọ́ àwọn èèyàn.