Ìpolongo Kárí Ayé Tá A Ó Fi Kéde Àpéjọ Àgbègbè “Ìdáǹdè Kù Sí Dẹ̀dẹ̀!”
Gbogbo Akéde Ìjọ Kọ̀ọ̀kan Ló Máa Pín Àkànṣe Ìwé Ìkésíni Yìí
1 A máa tó bẹ̀rẹ̀ sí í pín àkànṣe ìwé ìkésíni tá a dìídì ṣe láti polongo àpéjọ àgbègbè tá a máa ṣe káàkiri ayé nílẹ̀ tó tó ọgọ́jọ ó dín márùn-ún [155]. Ìpolongo ọ̀hún á bẹ̀rẹ̀ lóṣù May ọdún 2006 yìí títí dìgbà tá a bá ṣe èyí tó máa kẹ́yìn nínú ọ̀wọ́ àpéjọ náà. Ìpolongo yìí á tún kan àkànṣe àpéjọ tó máa wáyé lóṣù July àti ní ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ nínú oṣù August ọdún 2006 lórílẹ̀-èdè Jámánì, lórílẹ̀-èdè Czech àti lórílẹ̀-èdè Poland.
2 Pẹ̀lú bó ṣe jẹ́ pé ìgbà ìkẹyìn nínú àkókò òpin yìí là ń gbé, ṣe ló yẹ kí ọ̀wọ́ àpéjọ yìí, níbi tá a ti máa jíròrò ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa dá wa nídè kúrò nínú ayé burúkú yìí, wọ àwọn aláìlábòsí lọ́kàn. Ṣe ló yẹ kí ìpolongo yẹn mú kí wọ́n ronú nípa ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀. Kí ẹgbàágbèje èèyàn lè gbọ́ ọ̀rọ̀ tó máa tù wọ́n nínú tó sì máa fún wọn nírètí la ṣe rọ gbogbo ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó tó ẹgbẹ̀rún méjìdínlọ́gọ́rùn-ún [98,000] káàkiri ayé láti fi ìtara ké sí àwọn èèyàn ká lè jọ lọ sí àpéjọ náà.
3 A ó fi ìwé ìkésíni tó pọ̀ tó ránṣẹ́ sí ìjọ yín kí akéde kọ̀ọ̀kan bàa lè ní ìwé ìkésíni tó tó àádọ́ta [50] lọ́wọ́. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó wà nínú ìjọ lè lo èyí tó bá ṣẹ́ kù. Ìjọ kọ̀ọ̀kan á bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìpolongo náà tó bá ti ku ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tí àpéjọ tá a yan ìjọ wọ́n sí á bẹ̀rẹ̀. Èyí ló máa jẹ́ kẹ́ ẹ lè ní àkókò tó pọ̀ tó láti lè pín in dé ibi tó pọ̀ jù lára ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ yín, ká tiẹ̀ ní ẹ ò lè pín in dé gbogbo ẹ̀.
4 Àbá wa ni pé bó bá ṣeé ṣe kẹ́ ẹ rí i pé ẹ fi ìwé ìkésíni náà lé gbogbo ẹni tẹ́ ẹ bá bá pàdé lọ́wọ́. Bí àwọn kan ò bá sí nílé, ẹ lè fi ìwé ìkésíni kan há ibi tó bá dáa lẹ́nu ọ̀nà wọn. Ẹ jẹ́ ká ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti pín gbogbo ìwé ìkésíni náà tán láàárín ọ̀sẹ̀ mẹ́ta yẹn.
5 Ó dá wa lójú pé bá a ṣe ń polongo Àpéjọ Àgbègbè “Ìdáǹdè Kù sí Dẹ̀dẹ̀!” yìí kárí ayé, gẹ́gẹ́ bá a ṣe ṣàlàyé síbí, iṣẹ́ ìjẹ́rìí ọ̀hún á délé dóko. Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà tì ọ́ lẹ́yìn lọ́nà àrà bó o ṣe ń sapá láti kópa nínú ìpolongo kárí ayé yìí.