Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ July 27
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JULY 27
Orin 18 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 28 ìpínrọ̀ 1 sí 9 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Àwọn Ọba 15-17 (8 min.)
No. 1: 1 Àwọn Ọba 15:16-24 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ran Àwọn Aya Lọ́wọ́?—igw ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 3 àti 4 (5 min.)
No. 3: Ìdí Tí Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Fi Gbà Pé Ọlọ́run Wà—Ják. 2:19 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: ‘Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn.’ —Mát. 28:19, 20.
7 min: “Ìkésíni Tààràtà.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Tí ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 3, ní ṣókí, ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè fún àwọn èèyàn ní ìwé ìkésíni náà.
10 min: “Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Àpéjọ Àgbègbè.” Ìjíròrò. Akọ̀wé ni kó ṣe iṣẹ́ yìí. Pe àfiyèsí àwọn ará sí àwọn ìlànà Bíbélì tó wà nínú àwọn ìpínrọ̀ náà, kó o sì sọ bá a ṣe lè fi wọ́n sílò ní àpéjọ àgbègbè ti ọdún 2015. Bákan náà, kẹ́ ẹ jíròrò àwọn kókó tó bá yẹ látinú lẹ́tà August 3, 2013 nípa bá a ṣe lè dènà jàǹbá láwọn ìpàdé wa.
7 min: Máa Fi Ìwé “Ohun Tó Wà Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” Kọ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Rẹ. Ìjíròrò. Ẹ sọ̀rọ̀ nípa bí a ṣe lè lo àwọn ohun tó wà nínú ìwé yìí láti fi ran ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ kó lè mọ bá a ṣe ń lo Bíbélì: (1) “Bó O Ṣe Lè Wá Àwọn Ẹsẹ Bíbélì Rí.” (2) Ìbéèrè 19: “Kí ló wà nínú oríṣiríṣi ìwé tó para pọ̀ di Bíbélì?” (3) Ìbéèrè 20: “Báwo lo ṣe lè ka Bíbélì kó sì yé ọ dáadáa?” Ní ṣókí, ṣe àṣefihàn bí akéde kan ṣe ń jíròrò ọ̀kan lára àwọn ohun tó wà nínú ìwé náà pẹ̀lú ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́yìn tí wọ́n parí ìkẹ́kọ̀ọ́.
6 min: “Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 125 àti Àdúrà