Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ February 25
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ FEBRUARY 25
Orin 120 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 6 ìpínrọ̀ 1 sí 6 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Máàkù 5-8 (10 min.)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (20 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: “O Ò Ṣe Ṣiṣẹ́ Díẹ̀ Sí I?” Ìjíròrò.
10 min: A Ní Láti Jẹ́rìí Nípa Jésù Bá A Ti Ń Polongo Ìhìn Rere. Àsọyé tó ń tani jí tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Bẹ̀rẹ̀ ní ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ tó wà lójú ìwé 275 sí ìparí ojú ìwé 278.
15 min: Jèhófà Ń Fún Wa Ní Okun Ká Lè Wàásù. (Fílí. 4:13) Fi ọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde méjì tàbí mẹ́ta tó máa ń fìtara kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù láìka ìṣòro àìlera tí wọ́n ní sí. Àwọn ìṣòro wo ni wọ́n ní? Kí ni kò jẹ́ kí wọ́n gba ìrẹ̀wẹ̀sì láyè? Ọ̀nà wo ni àwọn ará nínú ìjọ ti gbà ràn wọ́n lọ́wọ́? Àwọn àǹfààní wo ni wọ́n ti rí nínú lílọ sóde ẹ̀rí déédéé?
Orin 42 àti Àdúrà