Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní February 25, 2013. A fi déètì tá a máa jíròrò kókó ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan sínú àwọn ìbéèrè náà kẹ́ ẹ lè ṣèwádìí wọn nígbà tẹ́ ẹ bá ń múra sílẹ̀ fún ilé ẹ̀kọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.
1. Kí nìdí tí Jésù fi sọ pé “àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀” jẹ́ aláyọ̀? (Mát. 5:4) [Jan. 7, w09 2/15 ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 6]
2. Nínú àdúrà àwòṣe tí Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, kí ni àdúrà náà “má sì mú wa wá sínú ìdẹwò” túmọ̀ sí? (Mát. 6:13) [Jan. 7, w04 2/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 13]
3. Kí nìdí tí Jésù fi sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun kì yóò lọ yíká lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù “títí Ọmọ ènìyàn yóò fi dé”? (Mát. 10:23) [Jan. 14, w10 9/15 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 12; w87 8/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 1]
4. Àwọn nǹkan méjì wo ni àpèjúwe Jésù nípa hóró músítádì jẹ́ ká mọ̀? (Mát. 13:31, 32) [Jan. 21, w08 7/15 ojú ìwé 17 àti18 ìpínrọ̀ 3 sí 8]
5. Ẹ̀kọ́ wo ni Jésù ń kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà tó sọ pé: “Láìjẹ́ pé ẹ yí padà, kí ẹ sì dà bí àwọn ọmọ kéékèèké, ẹ kì yóò wọ ìjọba ọ̀run lọ́nàkọnà”? (Mát. 18:3) [Jan. 28, w07 2/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 3 àti 4]
6. Kí ni ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé “ìwọ fúnra rẹ wí i”? (Mát. 26:63, 64) [Feb. 11, w11 6/1 ojú ìwé 18]
7. Kí nìdí tí Jésù fi sọ pé Ọmọ ènìyàn jẹ́ “Olúwa, àní ti sábáàtì pàápàá”? (Máàkù 2:28) [Feb. 18, w08 2/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 7]
8. Kí nìdí tí Jésù fi sọ ohun tó sọ nípa ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀? Ẹ̀kọ́ wo sì lèyí kọ́ wa? (Máàkù 3:31-35) [Feb. 18, w08 2/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 5]
9. Bó ṣe wà nínú ìwé Máàkù 8:22-25, kí ló lè jẹ́ ìdí tí Jésù fi la ojú ọkùnrin afọ́jú náà ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀-lé? Kí sì nìyẹn kọ́ wa? [Feb. 25, w00 2/15 ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 7]
10. Kí la rí kọ́ nínú bí Jésù ṣe fèsì ìbáwí mímúná tí Pétérù fún un bó ṣe wà nínú ìwé Máàkù 8:32-34? [Feb. 25, w08 2/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 6]