O Ò Ṣe Ṣiṣẹ́ Díẹ̀ Sí I?
Àwọn akéde kan sábà máa ń ṣíwọ́ lóde ẹ̀rí ní àkókò kan pàtó, ó lè jẹ́ ní aago méjìlà ọ̀sán. Òótọ́ ni pé àwọn nǹkan kan lè mú kó pọn dandan fún àwọn kan láti tètè ṣíwọ́ lóde ẹ̀rí. Àmọ́, ṣé torí pé àwọn tẹ́ ẹ jọ jáde òde ẹ̀rí ṣíwọ́ ni ìwọ náà ṣe máa ń ṣíwọ́? Ó lè ti di àṣà àwọn kan pé kí wọ́n máa ṣíwọ́ ní àkókò kan pàtó. O ò ṣe máa gbìyànjú láti ṣiṣẹ́ díẹ̀ sí i lóde ẹ̀rí? Kó o fi àǹfààní yẹn wàásù fún àwọn èèyàn ní òpópónà tàbí láwọn ibòmíì. O tiẹ̀ lè ṣe ìpadàbẹ̀wò kan tàbí méjì bó o ṣe ń darí lọ sílé. Ronú nípa àṣeyọrí tó o máa ṣe tó o bá tún rí ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa tàbí tó o bá tún fún ẹnì kan tó ń kọjá lọ ní àwọn ìwé ìròyìn wa. Tí a kò bá tètè ṣíwọ́ lóde ẹ̀rí, tá a sì gbìyànjú láti ṣiṣẹ́ díẹ̀ sí i, ọ̀nà kan tó rọrùn nìyẹn tá a lè gbà fi kún “ẹbọ iyìn” wa sí Jèhófà.”—Héb. 13:15.