ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/13 ojú ìwé 4
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ March

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ March
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MARCH 4
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
km 2/13 ojú ìwé 4

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ March

Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MARCH 4

Orin 62 àti Àdúrà

□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:

jr orí 6 ìpínrọ̀ 7 sí 12 àti àpótí tó wà lójú ìwé 73 (30 min.)

□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:

Bíbélì kíkà: Máàkù 9-12 (10 min.)

No. 1: Máàkù 11:19–12:11 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

No. 2: Kí Ni Èso Tí Ọlọ́run Kà Léèwọ̀ Lọ́gbà Édẹ́nì?—td 15D (5 min.)

No. 3: Ìdí Tá A Fi Máa Ń Láyọ̀ Tá A Bá Ya Ara Wa sí Mímọ́ fún Ọlọ́run—Ìṣe 20:35 (5 min.)

□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:

Orin 7

10 min: Àwọn Àbá Tá A Lè Lò Láti Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù March. Ìjíròrò. Fi àwọn ìbéèrè yìí darí ìjíròrò náà: Láwọn òpin ọ̀sẹ̀ tó bọ́ sí ìgbà tá a máa pín ìwé ìkésíni síbi Ìrántí Ikú Kristi, kí ló máa pinnu bóyá a tún lè fún àwọn èèyàn ní ìwé ìròyìn? Kí la lè sọ tá a bá fẹ́ fún àwọn èèyàn ní ìwé ìròyìn wa lẹ́yìn tá a ti fún wọn ní ìwé ìkésíni? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbéèrè àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ máa ń wà nínú àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a dábàá fún wa, báwo la ṣe lè gbé ọ̀rọ̀ wa kalẹ̀ ní ṣókí? Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan ìwé ìròyìn náà lọni pẹ̀lú ìwé ìkésíni síbi Ìrántí Ikú Kristi.

10 min: Jàǹfààní Látinú Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2013. Ìjíròrò. Ní ṣókí, jíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2013 bó ṣe wà lójú ìwé 3 àti 4 nínú ìwé náà. Kó o sì tún jíròrò ohun tó wà lójú ìwé 5 lábẹ́ àkòrí tá a pè ní “Bó O Ṣe Máa Lo Ìwé Yìí.” Ní kí àwọn ará sọ ìgbà tí wọ́n máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ojoojúmọ́, kí wọ́n sì sọ àǹfààní tí wọ́n ti rí nínú rẹ̀. Ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ, gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n máa ka ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ déédéé.

10 min: Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

Orin 119 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́