Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní February: Ẹ lo ọ̀kan lára àwọn ìwé olójú ewé méjì-lé-lọ́gbọ̀n yìí: Tẹ́tí sí Ọlọ́run, Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé tàbí Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run! Kẹ́ ẹ sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà ìpadàbẹ̀wò, ẹ lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tàbí èyí tẹ́ ẹ bá rí i pé ó máa túbọ̀ wúlò dáadáa fún onílé lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ náà. March àti April: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Nígbà ìpadàbẹ̀wò, ẹ lè fún onílé ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tàbí èyí tẹ́ ẹ bá rí i pé ó máa nífẹ̀ẹ́ sí nínú ìwé pẹlẹbẹ Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé, kẹ́ ẹ sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. May: Ẹ lo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tẹ́ ẹ bá ní lọ́wọ́. Bí onílé bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa, ẹ fi bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án. Kí ẹ lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé.
◼ A ti ṣe ìwé àsọyé tuntun tí àwọn olùbánisọ̀rọ̀ yóò máa lò nígbà Ìrántí Ikú Kristi bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 2013. Àkòrí rẹ̀ ni, “Ǹjẹ́ O Mọyì Ohun Tí Kristi Ṣe Fún Ọ?”
◼ Ẹṣin ọ̀rọ̀ àkànṣe àsọyé fún gbogbo ènìyàn ní àkókò Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún 2013 ni “Ṣé Ikú Ni Òpin Ìgbésí Ayé Ẹ̀dá?”