Orin 42
“Ṣèrànwọ́ fún Àwọn Tí Wọ́n Jẹ́ Aláìlera”
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ọ̀pọ̀ àìlera ló wà
Tí gbogbo wa ní.
Ṣùgbọ́n Jèhófà ńfìfẹ́
Tọ́jú wa síbẹ̀.
Àánú rẹ̀ pọ̀ púpọ̀,
Ìfẹ́ rẹ̀ pọ̀ jọjọ.
Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ laó ní,
Sáwọn tára ńni.
2. ‘Ta ló rẹ̀ tí kò kàn mí?’
Ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù ni.
Ẹ̀jẹ̀ Jésù ló rà wá,
Ká lè ríyè gbà.
Jáà ńwo aláìlera,
Torí òun ló dá wọn.
Ẹ jẹ́ ká gba tiwọn rò,
Ká rẹ̀ wọ́n lẹ́kún.
3. Má ṣe bú aláìlera,
Ká fi sọ́kàn pé
Táa bá ṣèrànwọ́, wọ́n tún
Lè pa dà lókun.
Sapá gidigidi,
Ká fún wọn níṣìírí;
Báa bá sì ṣàánú fún wọn,
Wọn yóò rítùnú.
(Tún wo 2 Kọ́r. 11:29; Aísá. 35:3, 4; Gál. 6:2.)