Orin 135
Fífara Dà Á Dópin
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ìlérí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Mú ká nífaradà.
Ẹ̀kọ́ tóo kọ́ tóo sì nífẹ̀ẹ́,
Wọ́n fìdí múlẹ̀ ṣinṣin.
Dúró ṣinṣin ń’nú ìgbàgbọ́,
Fọjọ́ Ọlọ́run sọ́kàn.
Máa pa ìwà títọ́ rẹ mọ́;
Ìdánwò yóò yọ́ ọ mọ́.
2. Rọ̀ mọ́ ìfẹ́ rẹ àkọ́kọ́,
Torí ó lè sọ nù.
Àdánwò yòówù tó lè dé,
Fara dàá láìyẹsẹ̀.
Bó ti wù kí’dánwò le tó,
Má bẹ̀rù má ṣe mikàn.
Jèhófà ńṣọ̀nà àsálà,
Kò ní fi wa sílẹ̀ láé.
3. Àwọn tó fara dàá dópin
Làwọn tí aó gbà là.
A ó kọ orúkọ wọn sílẹ̀,
Sínú ìwé ìyè náà.
Torí náà lo ìfaradà;
Jẹ́ kó ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pé.
Wàá rí ojúure Jèhófà;
Ayọ̀ rẹ yóò sì pọ̀ gan-an.
(Tún wo Héb. 6:19; Ják. 1:4; 2 Pét. 3:12; Ìṣí. 2:4.)