ORÍ 17
Má Ṣe Fi Ètò Jèhófà Sílẹ̀
JÉMÍÌSÌ tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, á sì sún mọ́ yín.” (Jém. 4:8) A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà ò fojú pa wá rẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kò jìnnà sí wa, bá a tiẹ̀ jẹ́ aláìpé ó máa ń gbọ́ àdúrà wa. (Ìṣe 17:27) Ọ̀nà wo la lè gbà sún mọ́ Ọlọ́run? A lè sún mọ́ ọn tá a bá ń sa gbogbo ipá wa láti di ọ̀rẹ́ rẹ̀, ìyẹn á sì gba pé ká máa gbàdúrà sí i látọkànwá. (Sm. 39:12) A tún lè sún mọ́ Ọlọ́run pẹ́kípẹ́kí tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ déédéé. Nípa bẹ́ẹ̀, àá mọ ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run jẹ́, ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe àtohun tó fẹ́ ká ṣe. (2 Tím. 3:16, 17) Èyí á mú ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, á sì mú ká máa kíyè sára ká má bàa ṣe ohun tó máa bà á nínú jẹ́.—Sm. 25:14.
2 Àmọ́ o, nípasẹ̀ Jésù, Ọmọ Ọlọ́run nìkan ṣoṣo la lè gbà sún mọ́ Jèhófà. (Jòh. 17:3; Róòmù 5:10) Jésù nìkan ló lè jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ dáadáa, kò sí ẹlòmíì tó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ó mọ Baba rẹ̀ gan-an débi tó fi sọ pé: ‘Kò sẹ́ni tó mọ ẹni tí Baba jẹ́, àfi Ọmọ àti ẹnikẹ́ni tí Ọmọ bá fẹ́ ṣí i payá fún.’ (Lúùkù 10:22) Torí náà, tá a bá ń ka àwọn ìwé Ìhìn Rere, tá a sì ń rí bí Jésù ṣe ń ronú àti bí nǹkan ṣe ń rí lára rẹ̀, ńṣe là ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe ń ronú àti bí nǹkan ṣe ń rí lára rẹ̀. Irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run wa.
3 Tá a bá fira wa sábẹ́ Jésù tó jẹ́ Aṣáájú wa, tá a sì ń jẹ́ kí apá tó ṣeé fojú rí lára ètò Jèhófà máa tọ́ wa sọ́nà, àá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Àsọtẹ́lẹ̀ inú Mátíù 24:45-47 ti ń ṣẹ báyìí torí pé Jésù Kristi tó jẹ́ Ọ̀gá náà ti yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti máa pèsè ‘oúnjẹ ní àkókò tó yẹ’ fún agbo ilé ìgbàgbọ́. Lónìí, ẹrú olóòótọ́ ń fún wa ní oúnjẹ tẹ̀mí lọ́pọ̀ yanturu. Jèhófà ń tipasẹ̀ ẹrú yìí gbà wá níyànjú pé ká máa ka Ọ̀rọ̀ òun lójoojúmọ́, ká máa lọ sípàdé déédéé ká sì máa kópa tó jọjú nínú iṣẹ́ ìwàásù “ìhìn rere Ìjọba” Ọlọ́run. (Mát. 24:14; 28:19, 20; Jóṣ. 1:8; Sm. 1:1-3) Ká má ṣe rò ó láé pé ńṣe ni ẹrú olóòótọ́ náà kàn ń ṣe ohun tó wù ú. Ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé a ò kúrò nínú ètò Jèhófà, ká sì máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí wọ́n ń fún wa. Èyí á jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run wa, á jẹ́ ká lè fara da ìṣòro, ọkàn wa á sì balẹ̀.
ÌDÍ TÍ ÌṢÒRO FI Ń PỌ̀ SÍ I
4 Ṣó ti pẹ́ díẹ̀ tó o ti wà nínú òtítọ́? Ó dájú pé ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń dán ìgbàgbọ́ ẹni wò ni wàá ti là kọjá. Ká tiẹ̀ ní kò tíì pẹ́ tó o mọ Jèhófà tó o sì ń dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn rẹ̀, ìwọ náà mọ̀ pé ṣe ni Sátánì Èṣù máa ń gbógun ti àwọn tó gba Jèhófà ní Ọba Aláṣẹ wọn. (2 Tím. 3:12) Yálà ọjọ́ pẹ́ tó o ti ń kojú àdánwò ìgbàgbọ́ tàbí kò tíì pẹ́, má bẹ̀rù, má sì rẹ̀wẹ̀sì. Jèhófà ṣèlérí pé òun á wà pẹ̀lú rẹ, òun á sì fún ọ ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Héb. 13:5, 6; Ìfi. 2:10.
5 Ó ṣeé ṣe kí gbogbo wa ṣì dojú kọ àdánwò kí ayé Sátánì yìí tó kógbá sílé. Látìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́dún 1914, ni wọn ò ti gba Sátánì láyè mọ́ lọ́run níbi tí Jèhófà wà. Wọ́n lé e jù sí ayé pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ búburú. Ìdí nìyẹn tí nǹkan fi ń burú sí i láyé torí pé Sátánì ń bínú gidigidi, ó sì ń ṣe inúnibíni tó gbóná sáwa ìránṣẹ́ Jèhófà. Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yìí sì tún jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ọjọ́ tó kẹ́yìn ìṣàkóso Sátánì lórí aráyé là ń gbé yìí.—Ìfi. 12:1-12.
6 Inú ń bí Sátánì gan-an torí wọ́n lé e kúrò ní ọ̀run, ó sì mọ̀ pé òun ò ní pẹ́ pa run. Òun àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ wá ń sa gbogbo ipá wọn láti dí iṣẹ́ ìwàásù wa lọ́wọ́, wọ́n sì ń wá bí wọ́n á ṣe da àárín àwa èèyàn Jèhófà rú. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ṣe là ń bá àwọn ẹ̀mí èṣù jagun, ogun yìí ni Bíbélì tọ́ka sí nígbà tó sọ pé a ní “ìjà kan, kì í ṣe pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara, àmọ́ ó jẹ́ pẹ̀lú àwọn alákòóso, pẹ̀lú àwọn aláṣẹ, pẹ̀lú àwọn alákòóso ayé òkùnkùn yìí, pẹ̀lú agbo ọmọ ogun àwọn ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run.” Tá a bá fẹ́ borí nínú ogun yìí, a ò gbọ́dọ̀ dẹra nù rárá, ṣe ni ká jẹ́ kí ìhámọ́ra tẹ̀mí wa dúró digbí. Ká rí i pé a “dúró gbọn-in láti dojú kọ àwọn àrékérekè Èṣù.” (Éfé. 6:10-17) Èyí gba pé ká lo ìfaradà.
BÁ A ṢE LÈ NÍ ÌFARADÀ
7 Ẹni tó ní ìfaradà kì í juwọ́ sílẹ̀ nígbà ìṣòro tàbí ìnira. Tó bá kan ọ̀rọ̀ ìjọsìn, ẹni tó ní ìfaradà máa ń dúró ṣinṣin, ó sì máa ń ṣe ohun tó tọ́ àtohun tó yẹ bó tiẹ̀ dojú kọ ìṣòro, àtakò, inúnibíni tàbí àwọn nǹkan míì tó lè mú kó kẹ̀yìn sí Ọlọ́run. Àwa Kristẹni máa ń kọ́ ìfaradà ni, ó sì máa ń gba àkókò. Téèyàn bá ṣe ń lóye òtítọ́ sí i, bẹ́ẹ̀ lèèyàn á ṣe túbọ̀ máa ní ìfaradà. Àwọn àdánwò pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ sábà máa ń yọjú téèyàn bá ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, àmọ́ tá a bá fara dà á, àá lè fara da àwọn àdánwò tó le koko tó wà níwájú. (Lúùkù 16:10) Ká má ṣe dúró dìgbà táwọn ìṣòro ńlá bá dé ká tó pinnu pé a ò ní jẹ́ kí ohunkóhun bi ìgbàgbọ́ wa ṣubú. Ìsinsìnyí ló yẹ ká ti pinnu, kì í ṣe ìgbà tí àdánwò bá dé. Àpọ́sítélì Pétérù gbà wá níyànjú pé ká ní ìfaradà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ànímọ́ dáadáa míì, ó ní: “Ẹ sa gbogbo ipá yín láti fi ìwà mímọ́ kún ìgbàgbọ́ yín, ìmọ̀ kún ìwà mímọ́ yín, ìkóra-ẹni-níjàánu kún ìmọ̀ yín, ìfaradà kún ìkóra-ẹni-níjàánu yín, ìfọkànsin Ọlọ́run kún ìfaradà yín, ìfẹ́ ará kún ìfọkànsin Ọlọ́run yín, ìfẹ́ kún ìfẹ́ ará yín.”—2 Pét. 1:5-7; 1 Tím. 6:11.
Bá a ṣe ń dojú kọ ìṣòro lójoojúmọ́, tá a sì ń borí ẹ̀, ṣe ni àá túbọ̀ máa ní ìfaradà
8 Jémíìsì jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká ní ìfaradà nígbà tó kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin ará mi, tí oríṣiríṣi àdánwò bá dé bá yín, ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìgbàgbọ́ yín tí a dán wò ní ti bó ṣe jẹ́ ojúlówó tó máa mú kí ẹ ní ìfaradà. Àmọ́ ẹ jẹ́ kí ìfaradà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ láṣeparí, kí ẹ lè pé pérépéré, kí ẹ sì máa ṣe ohun tó tọ́ nínú ohun gbogbo, láìkù síbì kan.” (Jém. 1:2-4) Jémíìsì sọ pé kí àwa Kristẹni máa retí àdánwò, ká sì máa yọ̀ nígbà tí àdánwò bá dé torí pé á jẹ́ ká lè ní ìfaradà. Ṣé ìwọ náà gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí? Jémíìsì wá sọ pé ìfaradà níṣẹ́ tó ń ṣe nígbèésí ayé àwa Kristẹni, ó ń jẹ́ ká ní àwọn ànímọ́ rere, ó sì ń jẹ́ kí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà wá. Ó dájú pé bá a ṣe ń dojú kọ ìṣòro lójoojúmọ́, tá a sì ń borí rẹ̀, ṣe ni àá túbọ̀ máa ní ìfaradà. Ìfaradà yìí á wá mú ká ní àwọn ìwà rere míì tá a nílò.
9 Inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá ní ìfaradà; ìyẹn á sì mú kó fún wa ní èrè ìyè àìnípẹ̀kun. Jémíìsì tún sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tó ń fara da àdánwò, torí tó bá rí ìtẹ́wọ́gbà, ó máa gba adé ìyè, tí Jèhófà ṣèlérí pé òun máa fún àwọn tí ò yéé nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀.” (Jém. 1:12) Ìyè àìnípẹ̀kun tá à ń retí ń jẹ́ ká lè máa fara dà á. Tá ò bá ní ìfaradà, a ò ní lè dúró nínú òtítọ́. Tá a bá gbà kí ayé sọ wá dà bó ṣe dà, wẹ́rẹ́ báyìí la máa pa dà sínú ayé. Bí a kò bá sì ní ìfaradà, ńṣe ni ẹ̀mí Jèhófà máa fi wá sílẹ̀, a ò sì ní lè hùwà tí Ọlọ́run ń fẹ́.
10 Tá a bá fẹ́ máa fara dà á nìṣó lákòókò tí nǹkan le koko yìí, ó ṣe pàtàkì káwa Kristẹni máa fojú tó tọ́ wo ìyà tó ń jẹ wá. Ká rántí ohun tí Jémíìsì sọ pé: “Ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀.” Ká sòótọ́, ìyà ò dáa lára, torí ìrora àti ìdààmú ọkàn tó máa ń bá a rìn. Àmọ́ ká máa rántí pé àfi ká fara dà á, ká tó lè rí ìyè àìnípẹ̀kun. Ohun kan tó ṣẹlẹ̀ sáwọn àpọ́sítélì jẹ́ ká rí i pé a lè máa yọ̀ bá a tiẹ̀ ń jìyà. Ìtàn náà wà nínú ìwé Ìṣe, ó kà pé: “Wọ́n sì pe àwọn àpọ́sítélì, wọ́n nà wọ́n lẹ́gba, wọ́n sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n má sọ̀rọ̀ nípa orúkọ Jésù mọ́, wọ́n wá fi wọ́n sílẹ̀. Torí náà, wọ́n jáde kúrò níwájú Sàhẹ́ndìrìn, wọ́n ń yọ̀ nítorí a ti kà wọ́n yẹ láti jìyà nítorí orúkọ Jésù.” (Ìṣe 5:40, 41) Àwọn àpọ́sítélì yẹn mọ̀ pé torí àwọn ń ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù làwọn èèyàn ṣe ń fìyà jẹ àwọn, ó sì tún jẹ́ kó dá wọn lójú pé Jèhófà tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, nígbà tí Ọlọ́run mí sí Pétérù láti kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́, ó jẹ́ káwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ mọ̀ pé ohun iyì ni bí wọ́n bá ń jìyà nítorí òdodo.—1 Pét. 4:12-16.
11 Àpẹẹrẹ míì ni ti Pọ́ọ̀lù àti Sílà. Nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì nílùú Fílípì, àwọn aláṣẹ mú wọn, wọ́n sì fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n ń dí àlàáfíà ìlú lọ́wọ́ àti pé wọ́n ń kéde àṣà tí kò bófin mu. Nítorí ìyẹn, wọ́n nà wọ́n lẹ́gba bí ẹni-máa-kú, wọ́n tún fi wọ́n sí àtìmọ́lé. Bíbélì sọ fún wa pé nígbà tí wọ́n ṣì wà lẹ́wọ̀n pẹ̀lú ọgbẹ́ tí wọn ò bá wọn tọ́jú, “láàárín òru, Pọ́ọ̀lù àti Sílà ń gbàdúrà, wọ́n ń fi orin yin Ọlọ́run, àwọn ẹlẹ́wọ̀n sì ń fetí sí wọn.” (Ìṣe 16:16-25) Pọ́ọ̀lù àti Sílà gbà pé ìyà tí àwọn ń jẹ torí Kristi fi hàn pé olùṣòtítọ́ làwọn lójú Ọlọ́run àti èèyàn, yàtọ̀ síyẹn, wọ́n gbà pé àǹfààní ló jẹ́ fún wọn láti túbọ̀ jẹ́rìí fáwọn tó fẹ́ gbọ́ ìhìn rere náà. Wọ́n tún mọ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù táwọn ń ṣe ń gba ẹ̀mí àwọn èèyàn là. Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, ẹni tó ń ṣọ́ ẹ̀wọ̀n náà àti ìdílé rẹ̀ tẹ́tí sílẹ̀, wọ́n sì di ọmọlẹ́yìn. (Ìṣe 16:26-34) Pọ́ọ̀lù àti Sílà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, wọ́n mọ̀ pé ó lágbára láti gbà wọ́n sílẹ̀ àti pé á fún àwọn lókun káwọn lè fara da ìyà náà. Jèhófà ò sì já wọn kulẹ̀.
12 Bákan náà lónìí, Jèhófà ti fún wa ní gbogbo ohun tó máa jẹ́ ká lókun ká má bàa bọ́hùn nígbà ìṣòro. Ó fẹ́ ká fara dà á. Lára ohun tó fún wa ni Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ká lè ní ìmọ̀ tó péye nípa àwọn ohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé. Òye tá a ní yìí sì ń gbé ìgbàgbọ́ wa ró. Ohun míì ni pé à ń kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin a sì jọ ń sin Jèhófà. A tún láǹfààní láti máa bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àdúrà, èyí sì ń mú ká túbọ̀ sún mọ́ ọn. Ó máa ń fetí sí wa nígbà tá a bá ń dúpẹ́ oore tó ṣe fún wa àti nígbà tá a bá ń bẹ̀ ẹ́ tọkàntọkàn pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa jẹ́ mímọ́. (Fílí. 4:13) A ò sì ní gbàgbé pé a tún máa ń lókun láti fara dà á nígbà tá a bá ń ronú nípa àwọn ìbùkún tá a máa gbádùn lọ́jọ́ iwájú.—Mát. 24:13; Héb. 6:18; Ìfi. 21:1-4.
BÁ A ṢE LÈ MÁA FARA DA ONÍRÚURÚ ÀDÁNWÒ
13 Irú àwọn àdánwò tí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi dojú kọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní làwa náà ń kojú lónìí. Lóde òní, ọ̀rọ̀ èké táwọn alátakò gbọ́ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti mú kí wọ́n rọ̀jò èébú lé wa lórí, àwọn míì sì ti fìyà jẹ wá. Bíi tìgbà àwọn àpọ́sítélì, àwọn agbawèrèmẹ́sìn ló sábà máa ń rúná sí àwọn àtakò náà torí pé à ń lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti jẹ́ káráyé mọ̀ pé ẹ̀kọ́ wọn àti ìwà wọn kò bá Ìwé Mímọ́ mu. (Ìṣe 17:5-9, 13) Láwọn ìgbà míì, àwa èèyàn Jèhófà máa ń bọ́ lọ́wọ́ wọn nígbà tá a bá lo ẹ̀tọ́ tá a ní lábẹ́ òfin ìjọba. (Ìṣe 22:25; 25:11) Àmọ́, àwọn aláṣẹ pẹ̀lú máa ń fòfin de iṣẹ́ wa kí wọ́n bàa lè fòpin sí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. (Sm. 2:1-3) Tó bá ti rí bẹ́ẹ̀, ṣe la máa ń fìgboyà ṣe bí àwọn àpọ́sítélì Jésù tó sọ pé: “A gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí alákòóso dípò èèyàn.”—Ìṣe 5:29.
14 Pẹ̀lú bí ẹ̀mí orílẹ̀-èdè tèmi lọ̀gá ṣe ń gbilẹ̀ kárí ayé, bẹ́ẹ̀ làwọn èèyàn túbọ̀ ń fúngun mọ́ àwa tá à ń wàásù ìhìn rere ká lè pa iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ tì. Gbogbo àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run la lóye ìkìlọ̀ tó wà nínú Ìfihàn 14:9-12 dáadáa pé ká má ṣe jọ́sìn “ẹranko náà àti ère rẹ̀.” A ò sì kóyán ọ̀rọ̀ Jòhánù kéré, èyí tó sọ pé: “Ibi tó ti gba pé káwọn ẹni mímọ́ ní ìfaradà nìyí, àwọn tó ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́ tí wọ́n sì rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ Jésù.”
15 Ohun kan ni pé, ó lè má ṣeé ṣe fún ẹ láti pé jọ pẹ̀lú àwọn ará tàbí wàásù ní gbangba torí àwọn àdánwò kan, irú bí ogun, rògbòdìyàn òṣèlú tàbí inúnibíni, ìjọba sì lè fòfin de iṣẹ́ wa. Ó lè má ṣeé ṣe fún yín láti ṣèpàdé bí ìjọ. Ẹ tiẹ̀ lè má lè kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì rárá. Ó lè má ṣeé ṣe fún alábòójútó àyíká láti bẹ ìjọ wò. Ẹ lè má tiẹ̀ rí àwọn ìtẹ̀jáde gbà. Bí èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan yìí bá ṣẹlẹ̀, kí ló yẹ kó o ṣe?
16 Ṣe ló yẹ kó o ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe nínú ipò èyíkéyìí tó o bá bára rẹ. Kò yẹ kí ohunkóhun dí ẹ lọ́wọ́ láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́. Ìwọ̀nba ẹ̀yin mélòó kan lè kóra jọ nílé ẹnì kan láti jọ kẹ́kọ̀ọ́. Ẹ lè máa lo àwọn ìwé tá a ti kà kọjá tàbí kẹ́ ẹ kúkú lo Bíbélì láti fi ṣe ìpàdé. Fọkàn balẹ̀, má sì bẹ̀rù. Bó ṣe sábà máa ń rí, kò ní pẹ́ tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí á fi wá ọ̀nà láti kàn sí àwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú.
17 Ká tiẹ̀ wá sọ pé ìwọ nìkan ṣoṣo lo rí ara rẹ, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé kì í ṣe ìwọ nìkan lo dá wà, Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi wà pẹ̀lú rẹ. Má sọ̀rètí nù. Jèhófà á máa gbọ́ àdúrà rẹ, á sì lo ẹ̀mí rẹ̀ láti fún ẹ lókun. Máa bẹ̀ ẹ́ pé kó tọ́ ẹ sọ́nà. Má ṣe gbàgbé pé ìránṣẹ́ Jèhófà ni ẹ, ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi sì ni ẹ, torí náà, máa wá ọ̀nà láti wàásù. Ó dájú pé Jèhófà máa bù kún ìsapá rẹ, kó o tó mọ̀ àwọn èèyàn lè dara pọ̀ mọ́ ẹ nínú òtítọ́.—Ìṣe 4:13-31; 5:27-42; Fílí. 1:27-30; 4:6, 7; 2 Tím. 4:16-18.
18 Àmọ́, táwọn alátakò bá fi ikú halẹ̀ mọ́ ẹ, bí wọ́n ṣe ṣe fáwọn àpọ́sítélì àtàwọn míì, gbẹ́kẹ̀ lé “Ọlọ́run tó ń gbé òkú dìde.” (2 Kọ́r. 1:8-10) Rántí pé Jèhófà ṣèlérí pé òun máa jí òkú dìde, ìdánilójú yìí á mú kó o fara dà á kódà lójú àtakò tó nira gan-an. (Lúùkù 21:19) Àpẹẹrẹ Kristi Jésù là ń tẹ̀ lé; Jésù mọ̀ pé bóun bá jẹ́ olóòótọ́ dójú ikú, ìṣírí ló máa jẹ́ fún àwọn míì láti fara da àdánwò. Tí ìwọ náà bá ṣe bíi ti Jésù, àpẹẹrẹ tìẹ náà máa fún àwọn ará níṣìírí.—Jòh. 16:33; Héb. 12:2, 3; 1 Pét. 2:21.
19 Yàtọ̀ sí inúnibíni àti àtakò, àwọn ìṣòro míì lè yọjú tó máa gba pé kó o lo ìfaradà. Bí àpẹẹrẹ, ìrẹ̀wẹ̀sì ti bá àwọn ará wa kan torí pé àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn kì í tẹ́tí sí ìwàásù. Àìsàn tàbí ìdààmú ọkàn làwọn ará wa kan ń bá yí, nígbà tó sì jẹ́ pé ara tó ti di hẹ́gẹhẹ̀gẹ nìṣòro àwọn míì. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà fara da àwọn àdánwò kan tí kò jẹ́ kó lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ bó ṣe fẹ́, ó tiẹ̀ máa ń ni ín lára lọ́pọ̀ ìgbà. (2 Kọ́r. 12:7) Ẹpafíródítù ará Fílípì tó jẹ́ Kristẹni ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní náà níṣòro tiẹ̀, ó “ní ẹ̀dùn ọkàn torí [àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀] ti gbọ́ pé ó ṣàìsàn.” (Fílí. 2:25-27) Àìpé tiwa àti tàwọn ẹlòmíì lè dá ìṣòro sílẹ̀, ó sì lè nira gan-an láti fara dà á. Èdèkòyédè lè wáyé láàárín àwa tá a jọ jẹ́ Kristẹni tàbí nínú ìdílé. Àmọ́ téèyàn bá ń fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò, ó máa lè fara da àwọn ìṣòro yìí, á sì borí wọn.—Ìsík. 2:3-5; 1 Kọ́r. 9:27; 13:8; Kól. 3:12-14; 1 Pét. 4:8.
PINNU PÉ WÀÁ JẸ́ OLÓÒÓTỌ́
20 Ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé a rọ̀ mọ́ ẹni tí Jèhófà yàn láti jẹ́ Orí ìjọ, ìyẹn Kristi Jésù. (Kól. 2:18, 19) Ká máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” àtàwọn tá a yàn sípò àbójútó. (Héb. 13:7, 17) Tá a bá ń tẹ̀ lé ètò tí Jèhófà ṣe, tá a sì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń mú ipò iwájú, a máa wà létòlétò láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà. Ká rí i dájú pé à ń gbàdúrà nígbà gbogbo. Ká máa rántí pé kò sí ògiri ọgbà ẹ̀wọ̀n tàbí àhámọ́ èyíkéyìí tó lè dènà àdúrà wa sí Jèhófà, Baba wa onífẹ̀ẹ́, tàbí tó lè da ìṣọ̀kan ẹgbẹ́ ará wa rú.
21 Ẹ jẹ́ ká máa fara dà á láìbọ́hùn, ká má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun paná ìtara wa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tí Jésù Kristi gbé lé wa lọ́wọ́. Lẹ́yìn tó jíǹde, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Torí náà, ẹ lọ, kí ẹ máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn pé kí wọ́n máa pa gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mát. 28:19, 20) Ẹ jẹ́ káwa náà ní ìfaradà bíi ti Jésù. Ìgbà gbogbo ni ká máa rántí ìbùkún ìyè àìnípẹ̀kun tá a máa rí gbà nínú Ìjọba Ọlọ́run. (Héb. 12:2) Torí pé ọmọlẹ́yìn Kristi tó ti ṣèrìbọmi ni wá, inú wa dùn pé a wà lára àwọn tó ń mú àsọtẹ́lẹ̀ Jésù nípa “ìparí ètò àwọn nǹkan” yìí ṣẹ. Ó ní: “A ó sì wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé.” (Mát. 24:3, 14) Tá a bá ṣiṣẹ́ yìí tọkàntọkàn lásìkò tá a wà yìí, a máa láǹfààní ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun òdodo Jèhófà!