Ifarada Tí Ó Jèrè Ìjagunmólú
“Ẹyin nilo ifarada, ki ó baa lè jẹ́ pe, lẹhin ti ẹ ti ṣe ifẹ-inu Ọlọrun tán, ki ẹ lè rí imuṣẹ ileri naa gba.”—HEBERU 10:36, NW.
1. Eeṣe ti ifarada fi ṣe koko fun olukuluku ti nṣiṣẹsin Jehofa Ọlọrun lonii?
GBOGBO ayé yii ni ó wà labẹ agbara ọlọrun ọlọtẹ kan. Oluṣakoso alaiṣeefojuri rẹ̀, Satani Eṣu, ndari gbogbo isapa rẹ̀ si titako Jehofa ati jíjà lodisi idalare ipo ọba alaṣẹ agbaye Jehofa nipasẹ Ijọba Mesaya naa. Eyi mu ki ó jẹ alaiṣee yẹrafun pe ẹnikẹni ti o ba ya araarẹ̀ sí mímọ́ fun Ọlọrun ti o sì wà ni iha ọdọ Rẹ̀ ninu ariyanjiyan ipo ọba alaṣẹ naa ni ayé yii yoo maa takò niṣo. (Johanu 15:18-20; 1 Johanu 5:19) Fun idi yii, ẹnikọọkan wa gbọdọ ṣe araarẹ̀ gírí lati farada a titi di igba ti ayé yii bá poora ninu iṣẹgun patapata ni Amagẹdọni. Lati wà lara awọn ajagunmólú Ọlọrun ti wọn bori ayé nipa igbagbọ ati iwatitọ wọn, awa gbọdọ tẹpẹlẹmọ ọn laiṣaarẹ titi de opin. (1 Johanu 5:4) Bawo ni awa ṣe le ṣe iyẹn?
2, 3. Bawo ni Jehofa Ọlọrun ati Jesu Kristi ṣe jẹ apẹẹrẹ ifarada giga julọ?
2 Fun ohun kan, a lè wá iṣiri lọdọ awọn apẹẹrẹ ifarada titayọ meji. Awọn wo niwọnyi? Ẹnikan ni Jesu Kristi, “akọbi gbogbo ẹda,” ẹni ti o ti fi otitọ foriti i ninu iṣẹ-isin Ọlọrun lati igba ti a ti mu un wa si ìyè ni akoko kan ti a ko mọ̀ ni igba ti o ti kọja. Ninu iforiti rẹ̀ ninu ṣiṣiṣẹsin Ọlọrun pẹlu iṣotitọ, Jesu di apẹẹrẹ fun gbogbo ẹda ọlọgbọnloye ti a mu wa si ìyè ni ọrun ati lori ilẹ-aye lẹhin-ọ-rẹhin. (Kolose 1:15, 16) Bi o ti wu ki o ri, apẹẹrẹ didara julọ ti ifarada ni Jehofa Ọlọrun, ẹni ti o ti farada iṣọtẹ lodisi ipo ọba alaṣẹ agbaye rẹ̀ ti yoo sì maa baa lọ lati ṣe bẹẹ titi di igba ti oun ba gbegbeesẹ lati yanju ariyanjiyan ipo ọba alaṣẹ naa fun igba ikẹhin.
3 Jehofa ti ni ifarada ni ọna awofiṣapẹẹrẹ ninu awọn ọran ti ó wemọ iyì ati imọlara mimuna tirẹ funraarẹ. Oun ti ká araarẹ̀ lọ́wọ́kò loju isunnibinu titobi o sì ti fa araarẹ̀ sẹhin kuro ninu gbigbegbeesẹ lodisi awọn wọnni ti wọn ti kẹgan rẹ̀—titikan Satani Eṣu funraarẹ. Awa kun fun imoore fun ifarada Ọlọrun ati fun aanu rẹ̀. Laisi iwọnyi, awa kì bá tí gbadun iwalaaye ti o kuru julọ paapaa. Nitootọ, Jehofa ti fi araarẹ̀ han yatọ rekọja gbogbo afiwe nipa ifarada rẹ̀.
4, 5. (a) Bawo ni apejuwe Pọọlu nipa amọkoko ṣe fi ifarada Ọlọrun ati aanu rẹ̀ han? (b) Bawo ni a ṣe fi aanu Ọlọrun han gẹgẹ bi eyi ti a kò ti ṣì lò?
4 Apọsiteli Pọọlu tọka si ifarada ati aanu Ọlọrun nigba ti o wi pe: “Amọkoko ko ha ni aṣẹ lori amọ̀ lati ṣe ninu ìṣù kan naa ohun èèlò kan fun ìlò ọlọla, ohun èèlò miiran fun ìlò àìlọ́lá? Nisinsinyi, bi Ọlọrun, bi o tilẹ ni ifẹ inu lati fi ibinu rẹ̀ han ati lati sọ agbara rẹ̀ di mímọ̀, ba fi ọpọlọpọ ipamọra fi aye gba awọn koto ibinu ti a mú yẹ fun iparun, ki oun ba lè sọ ọrọ̀ ogo rẹ̀ di mímọ̀ lara awọn koto aanu, ti oun ti pese ṣaaju fun ogo, eyiini ni, awa, ẹni ti oun ti pè kii ṣe laaarin awọn Juu nikan ṣugbọn laaarin awọn orilẹ-ede pẹlu, iyẹn nkọ?”—Roomu 9:21-24, NW.
5 Gẹgẹ bi awọn ọrọ wọnyi ti fihan, laaarin akoko ifarada rẹ̀ yii, Jehofa nbaa lọ pẹlu ete ologo rẹ̀ ó sì nfi aanu rẹ̀ han lori awọn koto eniyan kan bayii. Oun pese awọn koto wọnyi fun ogo ainipẹkun o sì tipa bayii ṣẹgunbori awọn ete buburu oluṣatako nla rẹ̀, Satani Eṣu, ati gbogbo awọn alabaakẹgbẹ Satani. Kii ṣe gbogbo iran araye ni a rí pe ó jẹ koto ibinu, ti o yẹ fun iparun. Eyi yin ifarada onisuuru ti Ọlọrun Olodumare. Aanu rẹ̀ kò ni jasi asan. Yoo yọrisi (1) idile ijọba ologo ninu awọn ọrun labẹ Ọmọkunrin aayo-olufẹ ti Jehofa, Jesu Kristi, ati (2) iran awọn ẹda eniyan pípé ti a mu pada sori paradise ilẹ-aye kan, ti gbogbo wọn jẹ ajogun iye ainipẹkun.
Fifarada A Titi De Opin
6. (a) Eeṣe ti awọn Kristẹni kò fi le yẹra fun idanwo ifarada? (b) Ki ni ọrọ Giriiki naa fun “ifarada” saba maa nduro fun?
6 Pẹlu iru ireti agbayanu kan bẹẹ ni iwaju, awọn ọrọ afunnilokun ti Jesu gbọdọ maa dun gbọnmọ-gbọnmọ ni eti wa lemọlemọ, tii ṣe: “Ẹni ti o ba foriti i titi de opin, oun naa ni a o gbala.” (Matiu 24:13) O ṣe pataki lati bẹrẹ daradara ni ipa ọna jijẹ Kristẹni ọmọ-ẹhin. Ṣugbọn ohun ti ó ṣe pataki nigbẹhin-gbẹhin ni bi a ti farada a, bi a ti dé opin ipa ọna naa daradara tó. Apọsiteli Pọọlu tẹnumọ eyi nigba ti o wi pe: “Ẹyin nilo ifarada, ki o baa lè jẹ pe, lẹhin ti ẹ ti ṣe ifẹ inu Ọlọrun tan, ki ẹ lè ri imuṣẹ ileri naa gbà.” (Heberu 10:36, NW) Ọrọ Giriiki naa ti a tumọsi “ifarada” nihin-in ni hy·po·mo·neʹ. Eyi niye igba nduro fun ifarada onigboya, aduroṣinṣin, tabi onisuuru ti kii sọ ireti nù loju awọn iṣoro, inunibini, adanwo, ati idẹwo. Bi a ba nireti lati jere igbala nikẹhin, a gbọdọ yọnda fun idanwo ifarada gẹgẹ bi apakan imurasilẹ ti o pọndandan fun igbala yẹn.
7. Itanjẹ wo ni a gbọdọ yẹra fun, apẹẹrẹ ta ni yoo sì ran wa lọwọ lati ni ifarada?
7 A kò gbọdọ tan araawa jẹ nipa ero ìtẹ́ra-ẹni lọ́rùn naa pe a le bori idanwo naa ni kiakia. Nitori ki ariyanjiyan ipo ọba alaṣẹ agbaye ati iwatitọ eniyan baa le di eyi ti a fi ipinnu ikẹhin fun lésì, Jehofa kò dá araarẹ̀ sí. Oun ti farada awọn nǹkan ti ko gbadunmọni bi o tilẹ jẹ pe oun iba ti pa wọn run loju ẹsẹ. Jesu Kristi pẹlu jẹ́ apẹẹrẹ ifarada. (1 Peteru 2:21; fiwe Roomu 15:3-5.) Pẹlu awọn apẹẹrẹ titayọ wọnyi niwaju wa, dajudaju awa pẹlu muratan lati farada a titi de opin.—Heberu 12:2, 3.
Ẹ̀rí Ìtóótun Kan Ti A Nilo
8. Animọ wo ti gbogbo wa nilo ni apọsiteli Pọọlu ṣapejuwe?
8 Kò sí iranṣẹ Ọlọrun, ani lati awọn akoko ijimiji julọ paapaa, ti a tii dásí kuro lọwọ aini naa lati fẹ̀rí iwatitọ rẹ̀ han nipa nini ifarada. Awọn eniyan titayọ ninu itan Bibeli ti wọn duro ni oloootọ titi dé iku ti wọn sì tootun fun iye ainipẹkun ninu awọn ọrun nilati fi ẹ̀rí iduroṣinṣin wọn han. Fun apẹẹrẹ, Farisi tẹlẹri naa, Sọọlu ara Tasu, sọ fun awọn ara Kọrinti pe: “Emi kò rẹhin ni ohunkohun si awọn apọsiteli gigagiga naa, bi emi ko tilẹ jamọ nǹkankan. Nitootọ a ti ṣe iṣẹ ami apọsiteli laaarin yin ninu suuru gbogbo, ninu iṣẹ ami, ati iṣẹ iyanu, ati iṣẹ agbara.” (2 Kọrinti 12:11, 12) Laika awọn ẹrù inira iṣẹ naa sí, Pọọlu ka iṣẹ-ojiṣẹ rẹ̀ si iyebiye lọna giga gan-an debi pe ó farada ohun pupọ o sì fi igbona ọkan gbiyanju lati maṣe mu ẹgan eyikeyii wa sori rẹ̀.—2 Kọrinti 6:3, 4, 9.
9. (a) Bawo ni awọn aṣẹku ẹni ami ororo ṣe fi ifarada han, pẹlu iyọrisi wo sì ni? (b) Ki ni o ṣiṣẹ gẹgẹ bi iṣiri fun wa lati maa baa lọ pẹlu iṣotitọ ninu iṣẹ-isin atọrunwa?
9 Ni eyi ti o tubọ jẹ akoko ode oni, awọn Kristẹni ẹni ami ororo ti wọn nṣiṣẹsin Ọlọrun ṣaaju ogun agbaye kìn-ín-ní mọ pe 1914 yoo sami si opin Akoko Awọn Keferi, ọpọlọpọ ninu wọn sì reti lati gba ere ti ọrun wọn ni ọdun manigbagbe yẹn. Ṣugbọn eyi kò ṣẹlẹ. Gẹgẹ bi awọn otitọ ti fihan nisinsinyi, a ti fi ọpọ awọn ọdun mẹwaa-mẹwaa kun un fun wọn. Laaarin akoko ipa ọna igbesi-aye wọn ti ori ilẹ-aye ti a fàgùn siwaju lọna ti a kò reti tẹlẹ yii, wọn niriiri ìyọ́mọ́ lati ọwọ Jehofa Ọlọrun. (Sekaraya 13:9; Malaki 3:2, 3) Ifarada ti nbaa lọ wá ṣiṣẹ fun ìsunwọ̀n sii wọn. Gẹgẹ bi iranṣẹ Jehofa, wọn yọ̀ lati di awọn ti a yàn gẹgẹ bi awọn eniyan ti njẹ orukọ rẹ̀. (Aisaya 43:10-12; Iṣe 15:14) Lonii, lẹhin ti a ti mu wọn la ogun agbaye meji ati ọgọọrọ awọn iforigbari keekeeke kọja, ó dun mọ wọn lati rí iranlọwọ ninu titan ihinrere naa kalẹ nipasẹ ogunlọgọ nla ti awọn agutan miiran ti npọ sii, ti iye wọn ju aadọta ọkẹ mẹrin lọ nisinsinyi. Paradise tẹmi ti wọn ngbadun ti tànkálẹ̀ yika gbogbo ilẹ-aye, ani titi de awọn erekuṣu okun jijinna julọ. Ìlòsí olojurere yii, eyi ti a nmọriri lọpọlọpọ sii bi iwalaaye wa ti ngun sii tó ti ṣeranwọ gẹgẹ bi ohun kan ti nfunni niṣiiri lati maa baa lọ pẹlu iṣotitọ ninu iṣẹ-isin atọrunwa titi di igba ti ifẹ ati ete Jehofa ba di eyi ti a muṣẹ ni kikun.
10. Ki o maa baa sí iṣaarẹ eyikeyii fun wa, ki ni a nilo deedee?
10 Niwọn bi ere wa ti sinmi lori iduroṣinṣin wa, a nilo ọrọ iyanju lori ọran ṣiṣekoko yii lemọlemọ. (1 Kọrinti 15:58; Kolose 1:23) Ki ìsọni di alailera kankan ma baa wà laaarin awọn eniyan Jehofa, a gbọdọ maa fun wa niṣiiri deedee lati rọ̀ mọ́ otitọ ati anfaani ṣiṣeyebiye ti titan otitọ kálẹ̀, gan-an gẹgẹ bi a ti ṣe fun awọn ijọ ti a ṣẹṣẹ dá silẹ ni ọgọrun-un ọdun kìn-ín-ní nipasẹ awọn ipadabẹwo lati ọdọ Pọọlu ati Banaba. (Iṣe 14:21, 22) Ẹ jẹ ki o jẹ ìgbèrò ati ipinnu gbọnyingbọnyin wa pe gẹgẹ bi apọsiteli Johanu ti sọ ọ, otitọ yoo duro ninu wa, “yoo sì maa ba wa gbe titi.”—2 Johanu 2.
Diduro Pẹlu Ifarada Aláìyẹ̀
11. Ki ni ó dabii ọna Ọlọrun pẹlu awọn iranṣẹ rẹ̀, bawo si ni a ṣe ṣakawe eyi ninu ọran ti Josẹfu?
11 Ó ngba akoko ki idanwo ti ó bá wa to le pari. (Jakobu 1:2-4) Duro ná! Duro ná! Duro ná! ni o dabii ohun ti ó jẹ́ ọna Ọlọrun pẹlu awọn iranṣẹ rẹ̀ igba laelae nigba ti a dán wọn wò niti ipinnu wọn lati maa baa lọ ninu igbagbọ. Ṣugbọn iduro naa, nikẹhin, saba maa njasi ọ̀kan ti o ni ẹ̀san rere fun awọn iranṣẹ oluṣotitọ wọnni. Fun apẹẹrẹ, Josẹfu nilati duro fun ọdun 13 gẹgẹ bi ẹrú ati ẹlẹwọn kan, ṣugbọn ìrírí naa yọ́ animọ iwa rẹ̀ mọ́.—Saamu 105:17-19.
12, 13. (a) Bawo ni Aburahamu ṣe jẹ apẹẹrẹ ifarada oloootọ? (b) Ni ọna wo ni igbagbọ ati ifarada Aburahamu gba duro gẹgẹ bi awokọṣe fun wa?
12 Aburahamu ti di ẹni ọdun 75 ṣaaju ki Ọlọrun to pe e jade kuro ni Uri ti awọn ara Kalidia lati lọ si Ilẹ Ileri. Oun tó nǹkan bi ẹni ọdun 125 nigba ti o gba ẹ̀rí ijotiitọ ileri Ọlọrun ti a fi ibura ṣe—eyi ti o ṣẹlẹ ni kété lẹhin ti Aburahamu ṣaṣefihan okun igbagbọ rẹ̀ nipa lilọ dé ori fifi Isaaki, ọmọkunrin rẹ̀ aayo-olufẹ rubọ, ni didawọ duro kiki nigba ti angẹli Jehofa ká a lọ́wọ́kò ti ó si dena irubọ naa. (Jẹnẹsisi 22:1-18) Aadọta ọdun jẹ akoko gigun kan fun Aburahamu lati duro gẹgẹ bi àtìpó ni ilẹ ajeji kan, ṣugbọn oun duro fun aadọta ọdun miiran sibẹ titi di igba ti oun kú ni ẹni ọdun 175. Ni gbogbo akoko yẹn, Aburahamu jẹ ẹlẹrii oluṣotitọ ati wolii Jehofa Ọlọrun.—Saamu 105:9-15.
13 Igbagbọ ati ifarada Aburahamu ni a gbekalẹ gẹgẹ bi awoṣe fun gbogbo awọn iranṣẹ Ọlọrun ti wọn fẹ gba awọn ibukun naa ti a ṣeleri nipsẹ Jesu Kristi, Iru-ọmọ Aburahamu. (Heberu 11:8-10, 17-19) Nipa rẹ̀, a kà ni Heberu 6:11-15 pe: “Awa sì fẹ ki olukuluku yin ki o maa fi iru aisinmi kannaa han, fun ẹ̀kún ireti titi de opin: ki ẹ maṣe di onilọọra, ṣugbọn alafarawe awọn ti wọn ti ipa igbagbọ ati suuru jogun awọn ileri. Nitori nigba ti Ọlọrun ṣe ileri fun Aburahamu, bi kò ti rí ẹni ti o pọju oun lati fi bura, o fi araarẹ̀ bura, wi pe, nitootọ ní bibukun emi yoo bukun fun ọ, ati ni bibisii emi yoo mu ọ bí sii. Bẹẹ naa sì ni, lẹhin igba ti o fi suuru duro, o rí ileri naa gbà.”
14. Eeṣe ti awa ko fi nilati ronu pe idanwo ifarada jẹ alailopin ati pe ẹ̀san rere ni ọwọ kò lè tó?
14 Ni bayii awọn aṣẹku ẹni ami ororo ti ri ọdun 77 pe ó kọja lọ lati igba opin Akoko Awọn Keferi ni 1914, nigba ti diẹ ninu wọn reti iṣelogo ti ijọ Kristẹni tootọ si ọrun. Bi yoo ti pẹ sii tó fun awọn aṣẹku naa lati duro ni awa kò mọ. O ha yẹ ki awa mikan nigba naa ki a sì ronu pe iduro naa jẹ alailopin ati pe ere naa jẹ àlá ti kò le ṣẹ bi? Bẹẹkọ! Iyẹn ki yoo dá ipo ọba alaṣẹ Ọlọrun lare lae tabi ki o bọla fun orukọ rẹ̀. Oun ni a ki yoo dalare niwaju aye nigba ti o ba nfi ìjagunmólú ati èrè iye ainipẹkun ti o tibẹ yọ fun wa. Laifi gigun akoko naa pè, awọn aṣẹku, papọ pẹlu awọn oluṣotitọ alabaakẹgbẹ wọn ẹni bii agutan, pinnu lati duro fun Jehofa lati gbegbeesẹ ni akoko tirẹ funraarẹ. Ni fifi iru iforiti awofiṣapẹẹrẹ bẹẹ han, wọn tẹle ipa ọna Aburahamu.—Roomu 8:23-25.
15. (a) Ki ni àkọlé wa, ati la awọn iriri wo kọja ni Ọlọrun ti gbé wa ró pẹlu ayọ iṣẹgun? (b) Iṣileti Pọọlu wo ni ó ṣe wẹ́kú sibẹ fun ọjọ wa?
15 Ọrọ akọle naa, nigba naa, ṣì jẹ ifarada aláìyẹsẹ̀ ninu ṣiṣe ifẹ inu Ọlọrun. (Roomu 2:6, 7) Ni igba ti o ti kọja o ti tì wá lẹhin la awọn ipọnloju mimuna já, eyi ti o ni awọn ifisẹwọn ati àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ninu, oun sì ti fi ayọ iṣẹgun mú wa kọja pẹlu ogo fun orukọ ati ete rẹ̀.a Lakooko ti o ṣì kù sibẹ fun ipari idanwo wa, Jehofa yoo maa baa lọ lati ṣe bakan naa. Ọrọ iyanju Pọọlu ṣì ṣe wẹ́kú sibẹ fun ọjọ wa pe: “Nitori ẹyin nilo suuru ati ifarada oniduuroṣinṣin, ki ẹ baa le ṣe ifẹ inu Ọlọrun ki ẹ sì ṣaṣepari rẹ̀ ni kikun, ki ẹ sì tipa bayii gbà ki ẹ si gbé e lọ ki ẹ sì gbadun ohun ti a ṣeleri naa dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”—Heberu 10:36, The Amplified Bible; Roomu 8:37.
16. Eeṣe ti a kò fi gbọdọ wo iyasimimọ wa si Jehofa ni ọna ti ó wulẹ ni ààlà tabi pẹlu awọn aidaniloju?
16 Niwọn igba ti Jehofa ti ní iṣẹ fun wọn lati ṣe laaarin aye buburu yii, nigba naa, ni titẹle apẹẹrẹ Jesu, a fẹ lati lọwọ ninu iṣẹ yẹn titi yoo fi pari. (Johanu 17:4) Iyasimimọ wa fun Jehofa kii ṣe lori adehun naa pe awa yoo ṣiṣẹsin in fun kiki akoko kukuru kan ati lẹhin naa Amagẹdọni yoo de. Iyasimimọ wa jẹ titilae. Iṣẹ Ọlọrun fun wa ki yoo dopin pẹlu ogun Amagẹdọni. Bi o ti wu ki o ri, o wulẹ jẹ kiki lẹhin ti a ba ti ṣaṣepari iṣẹ ti a nilati ṣe naa ṣaaju Amagẹdọni ni a tó le ri awọn ohun titobilọla ti yoo wá lẹhin ogun ńlá yẹn. Lẹhin naa, ni afikun si anfaani alayọ ti bibaa lọ lati ṣe iṣẹ rẹ̀, a o san ẹ̀san rere fun wa pẹlu awọn ibukun ti oun ṣeleri ti a ti nwọna fun tipẹ.—Roomu 8:32.
Ifẹ Fun Ọlọrun Ran Wa Lọwọ Lati Ni Ifarada
17, 18. (a) Ni awọn akoko masunmawo, ki ni yoo ran wa lọwọ lati lo ifarada pẹlu ojurere Ọlọrun? (b) Ki ni yoo ran wa lọwọ lati jere ìjagunmólú naa, ki sì ni a kò sọ nipa akoko ti ó ṣẹ́kù?
17 Boya, nigba ti awọn akoko ba kun fun masunmawo, a le beere pe: ‘Bawo ni awa ṣe lè ni ifarada siwaju sii?’ Ki ni idahun naa? Nipa ninifẹẹ Ọlọrun pẹlu gbogbo ọkan-aya, ero-inu, ọkàn ati okun wa. “Ifẹ a maa mu suuru, a sì maa ṣeun; ifẹ kii ṣe ilara; ifẹ kii sọrọ igberaga, kii fẹ̀, a maa farada ohun gbogbo, a maa gba ohun gbogbo gbọ́, a maa reti ohun gbogbo, a maa fàyàrán ohun gbogbo. Ifẹ kii yẹ̀ lae.” (1 Kọrinti 13:4, 7, 8) Ayafi bi a ba farada a nitori ifẹ fun Ọlọrun, ifarada wa ko ni niyelori. Ṣugbọn bi a ba foriti i labẹ awọn ẹrù inira nitori ifọkansin wa fun Jehofa, nigba naa ifarada wa ní iyọrisi ti mimu ki ifẹ wa fun un jinlẹ sii. Ifẹ fun Ọlọrun, Baba rẹ̀, ran Jesu lọwọ lati farada a. (Johanu 14:30, 31; Heberu 12:2) Bi agbara isunniṣe wa tootọ ba jẹ ifẹ fun Ọlọrun, Baba wa, ki ni ó wà nibẹ ti awa ko ni le farada?
18 Ifẹ aláìyẹsẹ̀ wa fun Jehofa Ọlọrun ni o ti mu ki o ṣeeṣe fun wa lati wà ni ajagunmólú lori aye laaarin akoko idanwo ti o lekoko julọ yii. Jehofa, nipasẹ Jesu Kristi, yoo sì maa baa lọ lati fun wa ni iranlọwọ ti a nilo bi o ti wu ki a yọnda eto igbekalẹ awọn nǹkan ogbologboo yii lati wa tó. (1 Peteru 5:10) Nitootọ, a ko sọ asọtẹlẹ kankan niti bi akoko ti ó kù ti pọ tó, kii sì ṣe pe awa nda ọjọ pàtó eyikeyii. A fi iyẹn silẹ fun Olupa akoko mọ Titobi julọ naa, Jehofa Ọlọrun.—Saamu 31:15.
19, 20. (a) Oju wo ni a gbọdọ fi wo ọjọ kọọkan ti nkọja ti a farada? (b) Iwa omugọ wo ni a fẹ lati yẹra fun, eesitiṣe?
19 Bi o ti wu ki o ri, iran eniyan ti a sọtẹlẹ pe yoo ṣẹlẹrii “opin eto igbekalẹ awọn nǹkan” ti yoo sì niriiri rẹ̀ ni o ti dagba gan-an nisinsinyi. (Matiu 24:3, 32-35) Nitori naa ẹ maṣe jẹ ki a gbagbe lae pe ọjọ kọọkan ti nkọja ti a farada fi ọjọ kan dinku fun Satani ati awọn ẹmi eṣu rẹ̀ lati sọ agbaye di eléèérí pẹlu wíwà wọn gan-an o sì fi ọjọ kan sunmọ igba ti Jehofa ki yoo farada wíwà “koto ibinu ti a mu yẹ fun iparun” mọ́. (Roomu 9:22, NW) Laipẹ, nigba ti ipamọra Jehofa ba wá si opin, oun yoo tu ibinu rẹ̀ sori awọn ọkunrin ati obinrin alaiwa-bi-Ọlọrun. Nipa bayii, oun yoo fi aitẹwọgba rẹ̀ atọrunwa han fun ipa ọna igbesẹ wọn, ani bi o tilẹ jẹ pe oun yọnda wọn lati maa baa lọ fun gbogbo sáà akoko yii.
20 Yoo jẹ alaimọgbọndani julọ fun wa lati dawọ awọn isapa onifẹẹ wa lati jere ẹbun ologo yẹn ti a nawọ rẹ̀ jade si wa nipasẹ Jesu Kristi duro. Kaka bẹẹ, a pinnu lati maa baa lọ pẹlu iṣotitọ gẹgẹ bi Ẹlẹ́rìí fun Jehofa ni akoko ṣiṣe pataki julọ yii nigba ti Jehofa fẹrẹẹ ṣetan lati dá araarẹ lare gẹgẹ bi Ọba alaṣẹ Agbaye.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fun apẹẹrẹ, Christine Elizabeth King kọwe pe: “Lodisi awọn Ẹlẹ́rìí nikan ni ijọba [Nazi] kò ṣaṣeyọri, nitori pe bi o tilẹ jẹ pe wọn ti pa ẹgbẹẹgbẹrun, iṣẹ naa nbaa lọ ati ni May 1945 igbokegbodo awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣì nbaalọ sibẹ, nigba ti Eto-ajumọni Orilẹ-ede ko sí. Iye awọn Ẹlẹ́rìí ti pọ sii ko sì sí awọn ti wọn juwọsilẹ. Awujọ naa ti jere awọn ajẹriiku wọn sì ti ja ija ogun kan sii ninu ogun Jehofa Ọlọrun.”—The Nazi State and the New Religions: Five Case Studies in Non-Conformity, oju-iwe 193.
Bawo Ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun Pada?
◻ Eeṣe ti awa kò fi le yẹra fun jijẹ ki a dan ifarada wa wo?
◻ Itanjẹ wo ni awa fẹ lati yẹra fun?
◻ Lati yẹra fun ṣisaarẹ wa eyikeyii, ki ni a nilo?
◻ Ki ni àkọlé wa?
◻ Ni akoko masunmawo, ki ni yoo ran wa lọwọ lati farada a?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Awọn eniyan Ọlọrun, bii awọn Ẹlẹ́rìí wọnyi ni Port of Spain, Trinidad, ti nmuratan nigba gbogbo lati duro de Jehofa