Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Sátidé Àkọ́kọ́ Lóṣù December
“Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń rántí Jésù lásìkò tá a wà yìí. Nǹkan pàtàkì wo lo rò pé Jésù ṣe fáráyé? [Jẹ́ kó fèsì.] Wo àkọlé tó wà lójú ìwé 16 yìí.” Fún onílé náà ní Ilé Ìṣọ́ December 1, kí ẹ sì jọ jíròrò ohun tó wà lábẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìsọ̀rí náà àti ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀, ó kéré tán. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè míì.
Ilé Ìṣọ́ December 1
“Lásìkò tá a wà yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣayẹyẹ Kérésìmesì. Èwo nínú àwọn ohun tó wà lójú ìwé yìí lo kà sí pàtàkì jù lásìkò Kérésìmesì? [Fi àwọn ohun tá a tò sí ojú ìwé 3 hàn án, kó o sì jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ṣí àpilẹ̀kọ tó bá ohun tí onílé bá tọ́ka sí mu, kó o sì ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a gbé àpilẹ̀kọ náà kà.] Ìwé ìròyìn yìí sọ oríṣiríṣi ọ̀nà tá a lè máa gbà rántí Jésù jálẹ̀ ọdún, tí kò ní jẹ́ lásìkò Kérésì nìkan.”
Ji! October–December
“Àwa èèyàn ń fẹ́ kí ayé yìí dáa jù báyìí lọ, àmọ́ kí ni ìwọ ń fẹ́ kó dáa? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tó fa wàhála tó bá gbogbo èèyàn. [Ka Róòmù 5:12.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ìdí tá a fi lè fọkàn tán Ọlọ́run pé ó máa tó fòpin sí ebi, ogun, àìsàn àti ikú.”