ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/11 ojú ìwé 8
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Àwọn Àjálù Tó Ń Ṣẹlẹ̀?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Àjálù—Kí Nìdí Tó Fi Pọ̀ Tó Bẹ́ẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
km 11/11 ojú ìwé 8

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Saturday Àkọ́kọ́ Lóṣù December

“Ó dá mi lójú pé ìwọ náà gbà pé gbogbo èèyàn ló nílò ọ̀rẹ́. Irú ìwà wo lo fẹ́ràn jù lọ lára ọ̀rẹ́ rẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí ìwé ìròyìn yìí sọ nípa ìdí tá a fi gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ yan àwọn ọ̀rẹ́ wa.” Mú Ilé Ìṣọ́ December 1 fún un, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò ohun tó wà ní ìsọ̀rí àkọ́kọ́ lójú ìwé 16. Ó kéré tán, kẹ́ ẹ ka ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀. Béèrè bóyá ó máa fẹ́ láti gba ìwé náà, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè tó kàn.

Ilé Ìṣọ́ December 1

“Kí lo rò pé ó fà á tí àwọn àjálù fi ń ṣẹlẹ̀ lemọ́lemọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí? [Jẹ́ kó fèsì.] Ó gbà àfiyèsí pé Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò kan tí àjálù á máa ṣẹlẹ̀ lemọ́lemọ́. [Ka Mátíù 24:7, 8.] Ìwé ìròyìn yìí dáhùn àwọn ìbéèrè yìí: Kí nìdí tí àjálù fi ń ṣẹlẹ̀ lemọ́lemọ́ lóde òní? Ṣé Ọlọ́run ló ń mú àjálù wá láti fìyà jẹ àwa èèyàn? Kí nìdí tó fi yẹ ká gbà pé Ọlọ́run máa tó fòpin sí gbogbo àjálù?”

Ji! October–December

“Gbogbo wa la fẹ́ kí ìgbésí ayé àwọn ọmọ wa ládùn kó lóyin. Àmọ́ ojúṣe wo làwọn òbí ní, kí wọ́n lè tọ́ àwọn ọmọ wọn ní àtọ́yanjú? [Jẹ́ kó fèsì.] Kí àwọn ọmọ lè máa ṣègbọràn, kí wọ́n sì ní ìwà ọmọlúwàbí, ó ṣe pàtàkì pé ká má ṣe jẹ́ kó sú wa láti máa tọ́ wọn sọ́nà. [Ka Diutarónómì 6:6, 7.] Ìwé ìròyìn yìí sọ bí títẹ̀lé àṣẹ tó ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ yìí ṣe máa ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti tọ́ àwọn ọmọ wọn láti ìgbà ìkókó títí tí wọ́n á fi dàgbà.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́