Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní November: Kí Ló Wà Nínú Bíbélì? Láfikún sí èyí tàbí gẹ́gẹ́ bí àfidípò, ẹ tún lè lo ìwé olójú ewé 32 èyíkéyìí tá a tò sínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù August 2011. December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Bí àwọn ọmọdé bá wà nínú ilé náà, kẹ́ ẹ lo ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà tàbí Ìwé Ìtàn Bíbélì. January: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tẹ́ ẹ bá fún ẹnì kan ní ìwé náà. February: Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé àti Sún Mọ́ Jèhófà.
◼ Bí ẹnì kan bá fẹ́ fi ọrẹ ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì ní tààràtà, “Watch Tower” ni kó sọ pé kí wọ́n san owó náà fún, kí ó kọ Watch àti Tower lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ni o.