Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ December 12
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ DECEMBER 12
Orin 43 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 14 ìpínrọ̀ 1 sí 5, àti àpótí tó wà lójú ìwé 112 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Aísáyà 6-10 (10 min.)
No. 1: Aísáyà 6:1-13 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Àkọsílẹ̀ Nípa Ọlọ́rọ̀ àti Lásárù Kì Í Ṣe Ẹ̀rí Ìdálóró Ayérayé—td 16D (5 min.)
No. 3: Ìdí Tí Ìfẹ́ Kì Í Fi Í Kùnà Láé—1 Kọ́r. 13:8; 1 Jòh. 4:8) (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀.
15 min: Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run Ti Ọdún 2012. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ ni kó sọ àsọyé yìí. Jíròrò àwọn ohun tó bá ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ yín látinú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ti ọdún 2012. Ṣàlàyé ojúṣe olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn. Fún àwọn ará níṣìírí láti máa fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ tá a bá yàn fún wọn, kí wọ́n máa lóhùn sí Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, kí wọ́n sì máa fi àwọn àbá tí wọ́n bá rí gbà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ látinú ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run sílò.
15 min: “Gbogbo Ìgbà La Wà Lẹ́nu Iṣẹ́.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 2, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò ní ṣókí lẹ́nu akéde kan tó já fáfá gan-an lẹ́nu ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà. Ní kó ṣàlàyé bó ṣe máa ń múra sílẹ̀ ṣáájú, kó o sì ní kó sọ ìrírí kan tó gbádùn mọ́ni.
Orin 135 àti Àdúrà