Ojú Ìwòye Bíbélì
Kí Ni Ọjọ́ Ìdájọ́?
Bíbélì sọ pé Ọlọ́run “ti dá ọjọ́ kan nínú èyí tí ó pète láti ṣèdájọ́ ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” (Ìṣe 17:31) Ọ̀pọ̀ èèyàn ni inú wọn kì í dùn tí wọ́n bá gbọ́ pé a máa dá àwọn lẹ́jọ́. Ṣé bó ṣe máa ń rí lára tìẹ náà nìyẹn?
TỌ́RỌ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, inú rẹ máa dùn láti mọ̀ pé ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa ló mú kó ṣètò Ọjọ́ Ìdájọ́ láti fi mú ìbùkún àgbàyanu wá fún ìran èèyàn, títí kan àwọn tó ti kú. (Mátíù 20:28; Jòhánù 3:16) Kí nìdí tá a fi nílò Ọjọ́ Ìdájọ́? Kí ló máa ṣẹlẹ̀ ní “ọjọ́” yẹn?
Kí Nìdí Tá A Fi Nílò Ọjọ́ Ìdájọ́?
Nígbà tí Ọlọ́run dá èèyàn sí ayé, kì í ṣe pé ó fẹ́ fi dán àwọn èèyàn wò láti mọ̀ bóyá wọ́n á kúnjú ìwọ̀n láti gbé níbòmíì. Ó dá èèyàn láti máa gbé ayé títí láé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni tọkọtaya àkọ́kọ́, wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. Nípa báyìí, wọ́n pàdánù àǹfààní tí wọ́n ní láti wà láàyè títí láé, wọ́n sì fa ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú sórí gbogbo àtọmọdọ́mọ wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 2:15-17; Róòmù 5:12.
Ẹgbẹ̀rún ọdún ni Ọjọ́ Ìdájọ́ máa jẹ́, láàárín àkókò yẹn, ìran èèyàn máa láǹfààní láti gba ohun tí Ádámù àti Éfà ti sọ nù pa dà.a Kíyè sí pé ìwé Ìṣe 17:31, tá a fa ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ yọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí sọ pé Ọjọ́ Ìdájọ́ máa nípa lórí àwọn tó wà ní “ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” Àwọn tó bá rí ìdájọ́ rere gbà máa gbé lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n sì máa gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun pẹ̀lú ara pípe. (Ìṣípayá 21:3, 4) Èyí fi hàn pé Ọjọ́ Ìdájọ́ máa jẹ́ kó ṣeé ṣe láti mú ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún aráyé àti ayé yìí ṣẹ.
Kristi Jésù ni Onídàájọ́ tí Ọlọ́run yàn. Bíbélì sọ pé Jésù máa “ṣèdájọ́ àwọn alààyè àti òkú.” (2 Tímótì 4:1) Àwọn wo ni “àwọn alààyè” tí Jésù máa ṣèdájọ́ wọn? Báwo sì ni àwọn òkú ṣe máa pa dà wà láàyè lórí “ilẹ̀ ayé tí a ń gbé”?
Jésù Máa Ṣèdájọ́ “Àwọn Alààyè”
Ní báyìí, a ti ń sún mọ́ ìparí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀, ìgbà yẹn sì ni Ọlọ́run máa pa gbogbo àwùjọ ẹ̀dá èèyàn oníwà ìbàjẹ́ run, á sì tipa báyìí mú àwọn ẹni burúkú kúrò. Àwọn tó bá la ìparun ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí já ni “àwọn alààyè” tí Jésù máa ṣèdájọ́ wọn.—Ìṣípayá 7:9-14; 19:11-16.
Láàárín ẹgbẹ̀rún [1,000] ọdún tí ìdájọ́ yẹn máa gbà, Kristi Jésù àtàwọn ọkùnrin àti obìnrin tí iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tí wọ́n jíǹde sí ọ̀run máa ṣàkóso lé ayé lorí. Wọ́n máa jẹ́ ọba àti àlùfáà, wọ́n á sì jẹ́ káwọn olóòótọ́ èèyàn rí àǹfààní ẹbọ ìràpadà Jésù gbà, èyí tó máa mú wọn dé ìjẹ́pípé ti ara àti ti èrò orí.—Ìṣípayá 5:10; 14:1-4; 20:4-6.
Ní Ọjọ́ Ìdájọ́, Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ò ní lè nípa èyíkéyìí lórí ohun táwa èèyàn bá ń ṣe. (Ìṣípayá 20:1-3) Àmọ́ ṣá o, lẹ́yìn Ọjọ́ Ìdájọ́, Ọlọ́run máa gba Sátánì láyè láti dán àwọn èèyàn tó bá wà láàyè wò bóyá wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin. Àwọn tó bá ń bá a nìṣó láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run nígbà náà máa yege ìdánwò tí Ádámù àti Éfà ti kùnà. Wọ́n máa gba ìdájọ́ tó máa jẹ́ kí wọ́n láǹfààní láti gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè tí a mú pa dà bọ̀ sípò lórí ilẹ̀ ayé. Gbogbo àwọn tó bá yàn láti ṣọ̀tẹ̀ lòdì sí Ọlọ́run máa pa run títí láé, bíi ti Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀.—Ìṣípayá 20:7-9.
Bí Jésù Ṣe Máa Ṣèdájọ́ ‘Àwọn Òkú’
Bíbélì sọ pé àwọn òkú “yóò dìde” ní Ọjọ́ Ìdájọ́. (Mátíù 12:41) Jésù sọ pé, “wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yóò sì jáde wá, àwọn tí wọ́n ṣe ohun rere sí àjíǹde ìyè, àwọn tí wọ́n sọ ohun búburú dàṣà sí àjíǹde ìdájọ́.” (Jòhánù 5:28, 29) Kì í ṣe ẹ̀mí tó fi ara àwọn tó ti kú sílẹ̀ ni Bíbélì yìí ń sọ o. Àwọn òkú kò mọ ohunkóhun rárá, ẹ̀mí wọn ò sì lọ síbì kankan lẹ́yìn tí wọ́n ti kú. (Oníwàásù 9:5; Jòhánù 11:11-14, 23, 24) Jésù máa jí gbogbo àwọn tó ń sùn nínú oorun ikú dìde wá sí ìyè lórí ilẹ̀ ayé.
Ṣé ohun táwọn tó jíǹde bá ṣe kí wọ́n tó kú la máa fi ṣèdájọ́ wọn? Rárá o. Bíbélì sọ pé, “ẹni tí ó bá ti kú ni a ti dá sílẹ̀ pátápátá kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” (Róòmù 6:7) Torí náà, bíi tàwọn tó máa la ìparun ètò àwọn nǹkan yìí já, Jésù máa ṣèdájọ́ àwọn tó bá jíǹde sí ìwàláàyè lórí ilẹ̀ áyé “ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ wọn” ní Ọjọ́ Ìdájọ́. (Ìṣípayá 20:12, 13) Ohun tí wọ́n bá ṣe láàárín àkókò yẹn la máa fi ṣèdájọ́ wọn, ìyẹn ló máa jẹ́ kí àjíǹde wọn jẹ́ àjíǹde sí ìyè àìnípẹ̀kun tàbí àjíǹde sí ìparun. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn máa jẹ́ tí ọ̀pọ̀ àwọn tó máa jíǹde sí ìyè máa mọ Jèhófà Ọlọ́run àti ohun tó fẹ́ kí wọ́n ṣe kí wọ́n lè máa wà láàyè nìṣó. Wọ́n á láǹfààní láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, wọ́n á sì jogún ìyè àìnípẹ̀kun ní ayé.
Má Bẹ̀rù
Yàtọ̀ sí pé Ọlọ́run máa fún àwọn èèyàn ní ìtọ́ni ní Ọjọ́ Ìdájọ́, àwọn tó wà láàyè á tún láǹfààní láti máa fàwọn ohun tí wọ́n ń kọ́ ṣèwà hù, wọ́n á sì lè jèrè àwọn ìbùkún tó máa mú wá. Fojú inú wo bí ayọ̀ rẹ á ti pọ̀ tó nígbà tó o bá pa dà rí àwọn èèyàn rẹ tí wọ́n jíǹde, tẹ́ ẹ sì wá jọ ń dàgbà di ẹni pípé!
Ọlọ́run máa gba Sátánì láyè láti dán ìdúróṣinṣin àwọn èèyàn wò lẹ́yìn Ọjọ́ Ìdájọ́. Àmọ́ kò yẹ ká máa bẹ̀rù tàbí ká máa ṣàníyàn. Nígbà tí Ọjọ́ Ìdájọ́ bá fi máa parí, gbogbo àwọn tó wà láàyè á ti wà ní ìmúratán láti kojú àdánwò ìkẹyìn yìí. Ọjọ́ Ìdájọ́ á wá tipa bẹ́ẹ̀ wà lára ìmúṣẹ àwọn ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe, ìyẹn mímú tó fẹ́ mú ipa tí ìṣọ̀tẹ̀ tó wáyé ní ọgbà Édẹ́nì ti ní lórí aráyé kúrò.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “ọjọ́” lè túmọ̀ sí sáà àkókò tí gígùn wọn yàtọ̀ síra. Bí àpẹẹrẹ, wo Jẹ́nẹ́sísì 2:4.
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Kí ni Ọjọ́ Ìdájọ́?—Ìṣe 17:31.
● Àwọn wo la máa ṣèdájọ́ wọn?—2 Tímótì 4:1.
● Báwo ni Ọjọ́ Ìdájọ́ ṣe máa gùn tó?—Ìṣípayá 20:4-6.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]
Fojú inú wo bí ayọ̀ rẹ á ti pọ̀ tó nígbà tó o bá pa dà rí àwọn èèyàn rẹ tí wọ́n jíǹde
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Nígbà ìṣàkóso Kristi, àwọn tó ti kú máa jíǹde sínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé