Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ September 1
“Àwọn èèyàn máa ń ṣe ohun tí kò dáa nígbà míì torí pé àwọn onísìn ti tàn wọ́n jẹ kí wọ́n lè gba ohun tí kì í ṣe òótọ́ gbọ́. Kí lo rò pé ó mú kí wọ́n tàn wọ́n jẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Bíbélì ní ká máa ṣe. [Ka 1 Jòhánù 4:1.] Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ṣàyẹ̀wò ohun tá a gbà gbọ́, ká lè mọ̀ bóyá ó bá ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ mu.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 10 hàn án.
Ji! October–December
“Ṣó yẹ ká máa fi àwọn obìnrin joyè òjíṣẹ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa obìnrin kan. [Ka Róòmù 16:1.] Àmọ́, ẹsẹ Bíbélì míì sọ pé ó yẹ kí àwọn obìnrin máa dákẹ́ nínú ìjọ. Kí wá lèrò Bíbélì lórí kókó yìí? Àlàyé rẹ̀ wà nínú àpilẹ̀kọ yìí.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ ní ojú ìwé 16 hàn án.
Ilé Ìṣọ́ October 1
“Káàkiri àgbáyé, àwọn èèyàn tó ń ṣe onírúurú ẹ̀sìn máa ń gbàdúrà. Ǹjẹ́ o rò pé Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká máa gbàdúrà. [Ka Fílípì 4:6, 7.] Ìwé ìròyìn yìí jẹ́ ká mọ ìdáhùn Bíbélì sí àwọn ìbéèrè méje kan tí àwọn èèyàn sábà máa ń béèrè nípa àdúrà.”
Ji! October–December
“Ó ṣeé ṣe kí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wàásù fún ẹ rí. Ǹjẹ́ o ti ronú nípa ìdí tá a fi máa ń lọ láti ilé dé ilé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn kì í fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Mátíù 24:14.] A mọ̀ pé èrò tí kì í ṣe òótọ́ ni ọ̀pọ̀ ní nípa wa. Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé irú ẹni tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́.”