Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Àwọn akéde tó ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá lóṣù February, ọdún 2009, jẹ́ ẹgbàá méjìdínláàádọ́jọ ó dín mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [295,966]. Èyí fi ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá, ọ̀ọ́dúnrún àti mẹ́tàlélógójì [13,343] ju àwọn akéde tó ròyìn lóṣù February, ọdún 2008 lọ. Ǹjẹ́ ká “máa bá a nìṣó bí ọkùnrin” nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.—1 Kọ́r. 16:13.