Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní July àti August: Ẹ lè lo èyíkéyìí lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tẹ́ ẹ ní lọ́wọ́: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá,” Ẹ Máa Ṣọ́nà!, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? —Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun--Ṣé O Ti Rí I?, àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun. September: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, ká sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tá a bá fún ẹnì kan ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Jẹ́ kó mọ bó ṣe lè jàǹfààní látinú ìwé náà nípa fífi bá a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án ní ṣókí. October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la máa lò. Ẹ fún ẹni tó bá fìfẹ́ hàn ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́? Bó bá ti ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà, kẹ́ ẹ sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
◼ Níwọ̀n bí oṣù August ti ní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún, ó máa dáa gan-an láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.
◼ Àwọn Àwo CD Tuntun Tó Wà:
Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn—Lórí àwo CD —Gẹ̀ẹ́sì
Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé—Lórí àwo CD —Gẹ̀ẹ́sì
Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!—Lórí àwo CD —Faransé