Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ August 3
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ AUGUST 3
Orin 198
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Númérì 4-6
No. 1: Númérì 4:1-16
No. 2: Bí A Ṣe Lè Mọ Ẹni Tó Yẹ Kí Á Ṣègbọràn Sí (lr orí 28)
No. 3: Ìjọba Ọlọ́run Nìkan Ló Lè Yanjú Ìṣòro Aráyé (td-YR 31E)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 166
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde méjì tàbí mẹ́ta tí wọ́n ti sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i tàbí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tí a kì í ṣe déédéé. Àwọn nǹkan wo ni wọ́n kọ́kọ́ ṣàníyàn nípa ẹ̀, báwo ni wọ́n sì ṣe borí àwọn àníyàn náà? Báwo ni Jèhófà ṣe bù sí ìsapá wọn? Sọ pé kí wọ́n sọ ìrírí kan tàbí méjì tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tàbí kí wọ́n ṣàṣefihàn bó ṣe ṣẹlẹ̀ gan-an ní ṣókí.
10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Ní Ìgbọ́kànlé Pé Jèhófà Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Láti Di Olùkọ́ Tó Múná Dóko. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 56, ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 57, ìpínrọ̀ 2.
Orin 171