Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ July 13
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JULY 13
Orin 40
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
lv-YR orí 7 ìpínrọ̀ 10 sí 19 àti àpótí tó wà lójú ìwé 81
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Léfítíkù 21-24
No. 1: Léfítíkù 22:17-33
No. 2: Ǹjẹ́ Àwọn Tó Ń Ṣe Ohun Búburú Lè Yí Padà? (lr orí 25)
No. 3: Báwọn Kristẹni Tòótọ́ Ṣe Ń Ṣàánú Fáwọn Tálákà
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 224
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Máa Lo Bíbélì Lóde Ẹ̀rí. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 145. Ní ṣókí, ṣàṣefihàn bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa lo ìtumọ̀ Bíbélì tó lo orúkọ Ọlọ́run, Jèhófà.
10 min: Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Sọ àwọn ìrírí tàbí kó o fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn akéde nípa ohun tí wọ́n ti gbé ṣe ní ìpínlẹ̀ ìwàásù nígbà tí wọ́n sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́jọ́ tí ìjọ yà sọ́tọ̀ fún ìgbòkègbodò àkànṣe yìí.
10 min: “Ṣó O Lè Ṣe Púpọ̀ sí I Nínú Iṣẹ́ Ìwàásù?” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 17