Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Láàárín ọdún iṣẹ́ ìsìn 2007 sí 2008, àwọn akéde ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́fà [1,206] ní Nàìjíríà ló dáhùn ìpè sí Makedóníà, ìyẹn ni lílọ wàásù láwọn ìpínlẹ̀ tá a kì í sábà ṣiṣẹ́. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn akéde yìí ló ní àwọn ìrírí tó gbádùn mọ́ni lóde ẹ̀rí, èyí tó fi hàn pé a ṣì nílò àwọn òṣìṣẹ́ púpọ̀ sí i. Ọ̀kan lára àwọn arákùnrin náà sọ pé: “Lọ́jọ́ tá a lò níbẹ̀ kẹ́yìn, lẹ́yìn tá a parí ìpàdé, ọkùnrin kan tó jẹ́ ará abúlé yẹn béèrè pé ìgbà wo la tún máa pa dà wá wàásù níbẹ̀. A sọ fún un pe a ò tíì lè sọ pé ìgbà báyìí ló máa jẹ́. Ó wá sọ pé, ‘Tí obìnrin kan bá bímọ tuntun, ńṣe ló yẹ kó máa tọ́jú ọmọ jòjòló yẹn títí dìgbà tó máa fi tójú bọ́. Ẹ̀ ti bímọ tuntun báyìí o . . . àmọ́ ẹ wá fẹ́ fi í sílẹ̀. Ta láá máa wá tọ́jú ọmọ jòjòló náà tá á fi tójú bọ́? Ẹ jọ̀ọ́, ẹ wá nǹkan ṣe nípa wa o.’” Ṣé o lè dáhùn sí ìpè yìí lọ́dún yìí?—Ìṣe 16:9.