Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò lóṣù June: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Bí onílé bá ti ní ìwé yìí, ẹ lè fún un ní ìwé olójú ìwé 192 èyíkéyìí tá a tẹ̀ sórí bébà tó pọ́n ràkọ̀ràkọ̀ tàbí ìwé èyíkéyìí tá a tẹ̀ ṣáájú ọdún 1992. July àti August: Ẹ lè lo èyíkéyìí lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tẹ́ ẹ ní lọ́wọ́, irú bí: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Ẹ Máa Ṣọ́nà!, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? àti “Sawo o! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” September: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, ká sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tá a bá fìwé lọni. Jẹ́ kí onílé mọ bó ṣe lè jàǹfààní látinú ìwé náà nípa fífi bá a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án ní ṣókí.
◼ Níwọ̀n bí oṣù August ti ní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún, ó máa dáa gan-an láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.
◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tuntun Tó Wà:
Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn (Onílẹ́tà Gàdàgbà) —Gẹ̀ẹ́sì
Watch Tower Publications Index ti ọdún 2007 —Gẹ̀ẹ́sì
◼ Àwọn Àwo DVD Tuntun Tó Wà:
Jehovah’s Witnesses Stand Firm Against Nazi Assault —Lórí àwo DVD
Warning Examples for Our Day àti Respect Jehovah’s Authority—Lórí àwo DVD