Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ July 6
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JULY 6
Orin 109
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
lv-YR orí 7 ìpínrọ̀ 1 sí 9, àtàwọn àpótí tó wà lójú ìwé 76 àti 78
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Léfítíkù 17-20
No. 1: Léfítíkù 19:1-18
No. 2: Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìwà Burúkú (td-YR 31B)
No. 3: Má Ṣe Di Olè! (lr orí 24)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 13
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ méjì tàbí mẹ́ta. Kí ló fún wọn níṣìírí láti sapá kọ́wọ́ wọn lè tẹ iṣẹ́ àtàtà yìí? (1 Tím. 3:1-9) Ìṣírí àti ìrànlọ́wọ́ wo ni wọ́n rí gbà? Àwọn ìbùkún wo ni wọ́n sì ti rí?
10 min: Ríran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Láti Fi Ìjọba Ọlọ́run sí Ipò Kìíní. Àsọyé tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lábẹ́ ìsọ̀rí tó wà lójú ìwé 281.
Orin 43