Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run.
1. Kí la lè rí kọ́ nínú ìkàléèwọ̀ tó wà nínú ìwé Ẹ́kísódù 23:19? [w06-YR 4/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 1 sí 5]
2. Kí ni Úrímù àti Túmímù, báwo ni wọ́n sì ṣe ń lò wọ́n ní Ísírẹ́lì ìgbàanì? (Ẹ́kís. 28:30) [w06-YR 1/15 ojú ìwé 18; w01-YR 9/1 ojú ìwé 27]
3. Báwo ni Jèhófà ṣe bá Mósè sọ̀rọ̀ ní “ojúkojú”? (Ẹ́kís. 33:11, 20) [w04-YR 3/15 ojú ìwé 27]
4. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa bí wọ́n ṣe fi tinútinú yọ̀ǹda àwọn ohun ìní wọn, tí wọ́n sì lo ìmọ̀ àti òye wọn láti ṣètìlẹ́yìn fún kíkọ́ àgọ́ ìjọsìn? (Ẹ́kís. 35:5, 10) [w99-YR 11/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 1 àti 2]
5. Kí ni àtabojú tó wà nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run nípa tẹ̀mí tí ìwé Ẹ́kísódù 40:28 mẹ́nu bà dúró fún? [w00-YR 1/15 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 7 àti 8]
6. Apá wo lára ìrúbọ tí Jésù ṣe ló tọ́ka sí “ọrẹ ẹbọ sísun”? (Léf. 1:13) [w04-YR 5/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 3]
7. Kí ni jíjẹ́ tí “gbogbo ọ̀rá jẹ́ ti Jèhófà” gbìn sí wa lọ́kàn? (Léf. 3:16, 17) [w04-YR 5/15 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 2]
8. Kí ni ìjẹ́pàtàkì dída ẹ̀jẹ̀ sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ àti fífi í sára onírúurú nǹkan? [w04-YR 5/15 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 5]
9. Kí ni Léfítíkù 12:8 jẹ́ ká mọ̀ nípa bí wọ́n ṣe tọ́ Jésù dàgbà, ẹ̀kọ́ wo sì nìyẹn kọ́ wa? [w98-YR 12/15 ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 5]
10. Kí ni oríṣiríṣi ẹran tí wọ́n fi ń rúbọ lọ́jọ́ ètùtù ọdọọdún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣàpẹẹrẹ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù? (Léf. 16:11-16) [w98-YR 2/15 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 2]