Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ December 1
“Lákòókò tá a wà yìí, àwọn kan máa ń ṣe eré tó dá lórí ìtàn ìbí Jésù tó wà nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì yìí. [Ka Mátíù 2:1, 11.] Ǹjẹ́ o kíyè sí ìyàtọ̀ tó wà nínú ohun tí Bíbélì sọ pé ó ṣẹlẹ̀ àti ohun táwọn èèyàn máa ń gbé jáde nínú eré? [Jẹ́ kó fèsì.] Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an.” Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 31 hàn án.
Jí! January–March
“Kò sí bí ìṣòro ò ṣe ní máa wáyé nínú ìdílé. Ibo lo rò pé àwọn ìdílé ti lè rí ìmọ̀ràn tó ṣeé gbára lé tó sì bọ́gbọ́n mu. [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Sáàmù 32:8.] Ìwé Ìròyìn yìí sọ àwọn ìlànà Bíbélì pàtó kan tó jẹ́ pé tí àwọn ìdílé bá tẹ̀ lé e, á ràn wọ́n lọ́wọ́ gan-an.”
Ilé Ìṣọ́ January 1
“Èrò tó yàtọ̀ síra ni àwọn ìsìn ní tó bá dọ̀rọ̀ mímu ọtí líle. Ojú wo lo rò pé Ọlọ́run fi ń wo ẹni tó bá ń mu ọtí líle? [Jẹ́ kó fèsì.] Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbà kan wà tí Jésù sọ omi di ọtí wáìnì, síbẹ̀ jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì tún sọ. [Ka Òwe 23:20a.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí.”
Jí! January–March
“Ǹjẹ́ o gbà pé oríṣiríṣi ìṣòro ló ń bá àwọn ìdílé fínra lóde òní? [Jẹ́ kó fèsì.] Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọ̀ pé ìmọ̀ràn tó bọ́gbọ́n mu wà nínú Bíbélì. Àpẹẹrẹ kan rèé. [Ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó wà nínú ìwé ìròyìn náà.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bí àwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè ran àwọn ìdílé lọ́wọ́ kí wọ́n lè kojú oríṣiríṣi ìṣòro tó lè wáyé.”