Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni Láti Wàásù
Onírúurú àbá nípa ọ̀nà tá a lè gbà lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni ló wà nínú àkìbọnú yìí. Tó o bá fẹ́ túbọ̀ já fáfá, sọ ọ́ lọ́rọ̀ ara ẹ, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ sọ bá ipò àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu kó o sì rí i pé o mọ àwọn kókó tó ṣeé fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò nínú ìwé náà. O sì lè lo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2005, ojú ìwé 8.
Àdúrà
◼ “Ṣó ò kì í ṣe kàyéfì nípa ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń dáhùn àdúrà? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka 1 Jòhánù 5:14, 15 àti ojú ìwé 170 sí 172, ìpínrọ̀ 16 sí 18.] Orí yìí tún ṣàlàyé ìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà sí Ọlọ́run àti ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe kó bàa lè máa gbọ́ àdúrà wa.”
Àjálù/Ìjìyà
◼ “Nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ṣe kàyéfì bóyá Ọlọ́run kan tiẹ̀ wà tó ń gba tàwọn èèyàn rò tàbí tó tiẹ̀ rí ìyà tó ń jẹ wọ́n. Ṣé ìwọ náà ti rò ó bẹ́ẹ̀ rí? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka 1 Pétérù 5:7 àti ojú ìwé 11, ìpínrọ̀ 11.] Ìwé yìí ṣàlàyé bí Ọlọ́run á ṣe fòpin sí gbogbo ohun tó ń fa ìjìyà ẹ̀dá pátápátá porogodo.” Fi àwọn ìbéèrè tó wà níbẹ̀rẹ̀ ojú ìwé 106 hàn án.
Amágẹ́dọ́nì
◼ “Nígbà táwọn èèyàn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà ‘Amágẹ́dọ́nì,’ ibi ìpakúpa rẹpẹtẹ lọkàn wọn máa ń lọ. Ǹjẹ́ kò ní yà ọ́ lẹ́nu láti mọ̀ pé ohun tó yẹ kéèyàn tiẹ̀ máa wọ̀nà fún ni Amágẹ́dọ́nì? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka Ìṣípayá 16:14, 16.] Kíyè sí àlàyé yìí tó dá lórí bí ayé ṣe máa rí lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì.” Ṣí ìwé náà sí ojú ìwé 82 sí 84 kó o sì ka ìpínrọ̀ 21.
Bíbélì
◼ “Àwọn èèyàn sábà máa ń pe Bíbélì ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ǹjẹ́ kò yà ọ́ lẹ́nu láti rí bí ìwé táwọn ọkùnrin kan kọ ṣe di ìwé tá a lè máa pè ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka 2 Pétérù 1:21 àti ojú ìwé 19 sí 20, ìpínrọ̀ 5.] Ìdáhùn Bíbélì sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí wà nínú ìwé yìí.” Fi àwọn ìbéèrè tó wà lójú ìwé 6 hàn án.
◼ “Láyé tá a wà yìí, àwọn èèyàn tètè máa ń mọ ohun tó ń lọ ju tàtijọ́ lọ. Ṣùgbọ́n ibo lo rò pé a ti lè rí ìmọ̀ràn gidi tó lè jẹ́ kí ìgbésí wa láyọ̀ ká sì rí bátiṣé? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka 2 Tímótì 3:16, 17 àti ojú ìwé 23, ìpínrọ̀ 12.] Ìwé yìí ṣàlàyé bá a ṣe lè gbé ìgbésí ayé wa lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́, ká sì ṣe ara wa láǹfààní.” Fi àtẹ àti àwòrán tó wà lójú ìwé 122 sí 123 hàn án.
Ìdílé
◼ “Gbogbo wa ló máa ń wù pé ká ní ilé aláyọ̀. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì sọ nǹkan kan tí gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé lè ṣe kí ayọ̀ bàa lè wà nínú ilé, nǹkan ọ̀hún sì ni pé kí wọ́n máa fara wé bí Ọlọ́run ṣe ń lo ìfẹ́.” Ka Éfésù 5:1, 2 àti ojú ìwé 135, ìpínrọ̀ 4.
Ikú/Àjíǹde
◼ “Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣe kàyéfì nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú. Ṣó o rò pé ó ṣeé ṣe fún wa láti mọ̀? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka Oníwàásù 9:5 àti ojú ìwé 58 sí 59, ìpínrọ̀ 5 sí 6.] Ìwé yìí tún ṣàlàyé ohun tí ìlérí àjíǹde tí Ọlọ́run ṣe nínú Bíbélì, máa túmọ̀ sí fáwọn tó ti kú.” Fi àwòrán tó wà lójú ìwé 75 hàn án.
◼ “Bí èèyàn wa kan bá kú, ṣe ló máa ń ṣe wá bíi ká tún rí onítọ̀hún. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Ọ̀pọ̀ làwọn tí ìlérí àjíǹde tó wà nínú Bíbélì ti tù nínú. [Ka Jòhánù 5:28, 29 àti ojú ìwé 71 sí 72, ìpínrọ̀ 16 sí 17.] Orí yìí tún dáhùn àwọn ìbéèrè yẹn.” Fi àwọn ìbéèrè tó wà níbẹ̀rẹ̀ ojú ìwé 66 hàn án.
Ilé Gbígbé
◼ “Láwọn ibi púpọ̀, ṣe ló túbọ̀ ń nira sí i láti rí ibùgbé tó bójú mu tí ò sì wọ́nwó. Ṣó o rò pé ọjọ́ ọjọ́ kan ń bọ̀ tí gbogbo èèyàn á nílé tó dáa lórí? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka Aísáyà 65:21, 22 àti ojú ìwé 34, ìpínrọ̀ 20.] Ìwé yìí ṣàlàyé bí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe yìí á ṣe nímùúṣẹ.”
Ìsìn
◼ “Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé àwọn ìsìn ayé ló ń fa ìṣòro ẹ̀dá dípò kó bá wọn yanjú àwọn ìṣòro náà. Ṣó o rò pé ibi tó dáa ni ìsìn ń sin àwọn èèyàn lọ [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Mátíù 7:13, 14 àti ojú ìwé 145 sí 146, ìpínrọ̀ 5.] Orí yìí ṣàgbéyẹ̀wò kókó mẹ́fà tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti dá ìjọsìn tí Ọlọ́run fọwọ́ sí mọ̀ yàtọ̀.” Fi ibi tá a tò wọ́n sí hàn án lójú ìwé 147.
Ìyè Àìnípẹ̀kun
◼ “Ó ń wu ọ̀pọ̀ èèyàn pé kí wọ́n nílera àtẹ̀mí gígùn. Ṣùgbọ́n ká ló lè ṣeé ṣe, ṣé wàá fẹ́ wà láàyè títí láé? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka Ìṣípayá 21:3, 4 àti ojú ìwé 54, ìpínrọ̀ 17.] Ìwé yìí jíròrò bá a ṣe lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun, ó sì tún jẹ́ ká mọ bí ayé ṣe máa rí nígbà tí ìlérí Ọlọ́run bá ṣẹ.”
Jèhófà Ọlọ́run
◼ “Ọ̀pọ̀ àwọn tó gba Ọlọ́run gbọ́ á fẹ́ láti túbọ̀ sún mọ́ ọn. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Bíbélì rọ̀ wá pé ká sún mọ́ Ọlọ́run? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka Jákọ́bù 4:8a àti ojú ìwé 16, ìpínrọ̀ 20.] Ṣe la dìídì ṣe ìwé yìí láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ̀ sí i nípa Ọlọ́run látinú Bíbélì tiwọn fúnra wọn.” Fi àwọn ìbéèrè tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí 8 hàn án.
◼ “Ọ̀pọ̀ ló ń gbàdúrà pé kí orúkọ Ọlọ́run di èyí tá a yà sí mímọ́ tàbí tá a bọ̀wọ̀ fún. Ǹjẹ́ o tiẹ̀ mọ orúkọ ọ̀hún? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka Sáàmù 83:18 àti ojú ìwé 195, ìpínrọ̀ 2 sí 3.] Ìwé yìí ṣàlàyé ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an nípa Jèhófà Ọlọ́run àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé.”
Jésù Kristi
◼ “Káàkiri ayé làwọn èèyàn ti gbọ́ nípa Jésù Kristi. Àwọn kan pè é ní ọ̀kan lára àwọn àkàndá èèyàn. Àwọn míì sì ń jọ́sìn rẹ̀ bí Ọlọ́run Olódùmarè. Ṣó o rò pé ohun tá a bá gbà gbọ́ nípa Jésù Kristi ṣe pàtàkì?” Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka Jòhánù 17:3 àti ojú ìwé 37 sí 38, ìpínrọ̀ 3. Ní kó ka àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ àkòrí yẹn.
Ogun/Àlàáfíà
◼ “Gbogbo ayé ló ń fẹ́ àlàáfíà. Àbí ṣe lo rò pé àlá tí ò lè ṣẹ ni ríretí táráyé ń retí àlàáfíà? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka Sáàmù 46:8, 9.] Ìwé yìí jíròrò ọ̀nà tí Ọlọ́run máa gbà ṣe ohun tó fẹ́ ṣe, táá sì dá àlàáfíà padà sáyé.” Fi àwòrán tó wà lójú ìwé 35 hàn án kó o sì jíròrò ojú ìwé 34 sí 36, ìpínrọ̀ 17 sí 21.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
Àwọn Ọ̀nà Tó O Lè Gbà Mẹ́nu Ba Ìṣètò Tó Wà fún Fífi Ọrẹ Ṣètìlẹyìn
“Bó o bá fẹ́ láti ṣètìlẹyìn tó mọ níwọ̀n fún iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé lónìí, màá fẹ́ láti gbà á.”
“Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò díye lé àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa, síbẹ̀ a máa ń gba ọrẹ tó mọ níwọ̀n fún ìtìlẹyìn iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé.”
“Ó lè máa yà ọ́ lẹ́nu bá a ṣe ń ṣe é tí iṣẹ́ yìí fi ń tẹ̀ síwájú. Ìdí ni pé ọrẹ àtinúwá la fi ń ti iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé náà lẹ́yìn. Bó o bá fẹ́ láti ṣètìlẹyìn tó mọ níwọ̀n fún iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé lónìí, màá fẹ́ láti gbà á.”