ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/96 ojú ìwé 4
  • Fi Òye Inú Wàásù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fi Òye Inú Wàásù
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìmọ̀ Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ń Dáhùn Ọ̀pọ̀ Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni Láti Wàásù
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Dámọ̀ràn fún Lílò Lóde Ẹ̀rí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Pèsè Ìtọ́sọ́nà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 1/96 ojú ìwé 4

Fi Òye Inú Wàásù

1 Láti ní òye inú ń béèrè pé kí a lóye àwọn nǹkan kan nípa àwọn tí a ń wàásù fún. Èé ṣe? Nítorí àṣeyọrí wa nínú dídé inú ọkàn àwọn ènìyàn sinmi lórí ìtóótunpegedé wa láti gbé ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà kalẹ̀ ní ọ̀nà tí yóò fà wọ́n mọ́ra. Ní oṣù January, a óò fi onírúurú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí ìjọ ṣì lè ní lọ́wọ́ lọni. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwọn akéde yóò lo ìwé náà, “Jẹ́ Kí Ijọba Rẹ Dé.” Àwọn àbá tí ó tẹ̀ lé e yìí lè ṣàǹfààní.

2 Bí o bá yàn láti fi ìwé náà, “Jẹ́ Kí Ijọba Rẹ Dé,” lọni, o lè tọ́ka sí àwòrán tí ó wà ní ojú ìwé 4 àti 5, kí o sì sọ pé:

◼ “Àwòrán yìí jẹ́ àwòrán ohun tí Bibeli kọ́ni nípa ète Ọlọrun fún orí ilẹ̀ ayé. Kí ni ìwọ rò pé yóò ná ìwọ àti ìdílé rẹ láti gbé nínú paradise kan lórí ilẹ̀ ayé? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bibeli fi hàn pé ipò oníparadise yìí yóò ṣẹlẹ̀ láìpẹ́, lábẹ́ Ìjọba Ọlọrun. [Ka Orin Dafidi 37:10, 11.] Ìwé yìí lè fi ohun tí o ní láti ṣe láti jàǹfààní nínú ohun tí Ọlọrun yóò ṣe hàn ọ́. N óò fẹ́ láti fi ẹ̀dà yìí sílẹ̀ fún ọ.” Fi ìwé náà lọ̀ ọ́ ní iye tí a ń fi síta, kí o sì ṣètò láti padà wá fún ìjíròrò síwájú sí i.

3 A lè lo ọ̀nà ìgbàyọsíni yíyàtọ̀ láti fi ìwé náà, “Jẹ́ Kí Ijọba Rẹ Dé,” lọni, nípa lílo ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ó wà ní ojú ìwé 12, ìpínrọ̀ 5, nínú ìwé “Reasoning”:

◼ “Bí mo tí ń bá àwọn aládùúgbò mi sọ̀rọ̀, mo kíyè sí i pé ọ̀pọ̀ ń yán hànhàn láti gbé lábẹ́ ìjọba kan tí ó lè yanjú àwọn ìṣòro ńlá tí ó dojú kọ wá lónìí ní ti gidi—ìwà ọ̀daràn àti iye owó gíga tí ìgbọ́bùkátà ń náni (tàbí ohunkohun tí ó wà lọ́kàn ọ̀pọ̀ ènìyàn ní lọ́ọ́lọ́ọ́). Ìyẹn yóò wuni, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Irú ìjọba kan bẹ́ẹ̀ ha wà lónìí bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ní ti gidi, ọ̀pọ̀ ènìyàn ti gbàdúrà fún irú ìjọba kan bẹ́ẹ̀. Ó dájú pé ìwọ pẹ̀lú ti gbàdúrà fún un, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ènìyàn kò kà á sí ìjọba kan.” Ka Danieli 2:44, kí o sì fẹ̀rí bí Ìjọba náà ṣe jẹ́ gidi hàn. Ṣí ìwé “Jẹ́ Kí Ijọba Rẹ Dé” sí àpótí tí ó wà ní ojú ìwé 25, kí o sì tẹnu mọ́ àwọn ohun tí Ìjọba Ọlọrun yóò ṣàṣeparí rẹ̀. Ṣètò láti padà wá fún ìjíròrò síwájú sí i, kí o sì fi ìwé náà lọ̀ ọ́ ní iye tí a ń fi síta.

4 Bí o bá ń lo ìwé náà, “Yiyan Ọna Igbesi Ayé Ti O Dara Julọ,” o lè bẹ̀rẹ̀ nípa wíwí pé:

◼ “Ìdàrúdàpọ̀ àti àìdánilójú ń bẹ nípa ọ̀nà tí ó dára jù lọ láti gbé ìgbésí ayé wa. Ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó jẹ́ olóòótọ́-inú yóò fẹ́ láti rí ọ̀nà ìgbésí ayé tí ń mú àlàáfíà àti ìtẹ́lọ́rùn wá nísinsìnyí, tí ó sì fi gbígbádùn ọjọ́ ọ̀la tí ó fọkàn ẹni balẹ̀ dáni lójú. Ṣùgbọ́n, ọ̀nà láti gbé ìgbésí ayé láìkábàámọ̀ ha wà bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ìrètí dídájú fún ọjọ́ ọ̀la sísunwọ̀n kan yóò jẹ́ kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀.” Ka 1 Peteru 3:13, kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀. Ṣàlàyé pé fífi àwọn ìlànà Bibeli sílò nísinsìnyí yóò mú ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀ wá. Gbé àwọn kókó inú ìpínrọ̀ 34 àti 35 nínú orí 11 ìwé Yiyan Ọna Igbesi Ayé Ti O Dara Julọ yẹ̀ wò, kí o sì fi ìwé náà lọ̀ ọ́ ní iye tí a ń fi síta.

5 O lè ru ọkàn-ìfẹ́ èwe kan sókè pẹ̀lú ìgbékalẹ̀ kúkúrú kan ní lílo ìwé náà, “Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ,” nípa sísọ pé:

◼ “Òǹkọ̀wé kan sọ pé: ‘Èyí tí ó pọ̀ jù lára àwọn ènìyàn ń lo àwọn ọdún àkọ́kọ́ wọn láti mú òṣì àti àre wá sórí ara wọn ní ìgbẹ̀yìn ayé wọn.’ Ìwọ kò fẹ́ kí ìyẹn ṣẹlẹ̀ sí ọ, àbí o fẹ́ bẹ́ẹ̀? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ọlọrun pẹ̀lú kò fẹ́ kí ìyẹ́n ṣẹlẹ̀. Ìwé yìí, Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ, yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yẹra fún àwọn ọ̀fìn tí ọ̀pọ̀ èwe ń kó sí.” Fi ìwé náà lọ̀ ọ́ ní iye tí a ń fi síta, kí o sì ṣètò láti padà wá.

6 Òye inú yóò mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti fòye mọ àìní àwọn ènìyàn tí a ń bá pàdé, àti ohun tí wọ́n lọ́kàn ìfẹ́ sí. Owe 16:23 (NW), fi èyí dá wa lójú, ní wí wí pé: “Ọkàn-àyà ọlọgbọ́n mú kí ẹnu rẹ̀ fi òye inú hàn, ó sì fi agbára ìyíniléròpadà kún ètè rẹ̀.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́