ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/96 ojú ìwé 8
  • Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Pèsè Ìtọ́sọ́nà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Pèsè Ìtọ́sọ́nà
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fífi Ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun Lọni
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Dámọ̀ràn fún Lílò Lóde Ẹ̀rí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Ìmọ̀ Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ń Dáhùn Ọ̀pọ̀ Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Fi Òye Inú Wàásù
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 12/96 ojú ìwé 8

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Pèsè Ìtọ́sọ́nà

1 A ń gbé nínú ayé kan tí ó kún fún ọ̀pọ̀ ìṣòro àti ojútùú tí kò tó nǹkan. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ń sùn lébi. Iye tí ń pọ̀ sí i ń di ajoògùnyó. Ìdílé púpọ̀ sí i ń tú ká. Ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan àti ìwà ipá inú ìdílé ń jẹ yọ nínú ìròyìn lemọ́lemọ́. A ń sọ afẹ́fẹ́ tí a ń mí símú àti omi tí a ń mu di májèlé díẹ̀díẹ̀. Lẹ́sẹ̀ kan náà, púpọ̀ sí i nínú wa ni a ń hùwà ọ̀daràn sí.

2 Àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wà lókè yìí kàn wá gbọ̀ngbọ̀n lónìí ju bí wọ́n ṣe kàn wá ní àwọn ọdún bíi mélòó kan sẹ́yìn pàápàá. Ó yẹ kí àwọn ènìyàn mọ̀ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń fúnni nítọ̀ọ́ni, ó sì ń pèsè ojútùú sí gbogbo ìṣòro tí ń pọ́n wọn lójú. A óò sakun láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ ní December nípa fífi Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun lọ̀ wọ́n. Ṣùgbọ́n, wíwulẹ̀ fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀ fún ẹnì kan kò túmọ̀ sí pé ẹni náà yóò tẹ́wọ́ gba ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. A gbọ́dọ̀ ṣe ìpadàbẹ̀wò pẹ̀lú góńgó bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́kàn. Ó dájú pé a óò rí ìrànlọ́wọ́ gbà bí a bá sapá gidigidi. (Mat. 28:19, 20) Àwọn ìgbékalẹ̀ mélòó kan tí a dábàá nìyí:

3 Bí o bá bá àgbàlagbà kan pàdé, o lè gbìyànjú ọ̀nà ìyọsíni yìí:

◼ “Ǹjẹ́ mo lè béèrè ohun kan: Báwo ni àwọn ènìyàn ní àdúgbò ṣe ń ba ara wọn lò, nígbà tí ẹ wà ní kékeré? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Nǹkan ti yàtọ̀ pátápátá nísinsìnyí, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Kí ni ẹ rò pé ó fa ìyípadà náà? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ní ti gidi, a ń rí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ kan nínú Bíbélì. [Ka Tímótì Kejì 3:1-5.] Yàtọ̀ sí pé Bíbélì ṣàpèjúwe bí ayé ti wà gan-an lónìí lọ́nà pípé pérépéré, ó tún ṣèlérí ayé kan tí ó dára jù ní ọjọ́ iwájú tí kò jìnnà. Nítorí èyí, a ń rọ gbogbo ènìyàn láti ka Bíbélì. Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun tí mo ń kà mú kì Bíbélì túbọ̀ yé mi dáradára.” Fi Bíbélì náà lọ̀ ọ́ ní iye tí a ń fi síta.

4 Nígbà tí o bá ṣèpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àgbàlagbà tí o fún ní Bíbélì, o lè sọ pé:

◼ “Nígbà tí a sọ̀rọ̀ kẹ́yìn, a fohùn ṣọ̀kan pé, ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà, àwùjọ òde òní ti yí padà di búburú ní ìfiwéra pẹ̀lú bí ayé ti rí ní nǹkan bí ọdún mélòó kan sẹ́yìn. Ṣùgbọ́n, èmi yóò fẹ́ láti fi hàn yín pé Bíbélì gbé ìfojúsọ́nà fún ayé kan tí ó dára jù kalẹ̀ fún ọjọ́ ọ̀la. [Ka Ìṣípayá 21:3, 4.] Mímọ̀ pé èyí jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yẹ kí ó fún wa níṣìírí láti yẹ àwọn ohun mìíràn tí Bíbélì ní láti sọ wò. [Ka Ìṣe 8:30, 31.] Ó ṣeé ṣe kí ẹ bá àwọn ohun tí ẹ kò lóye pàdé, nígbà tí ẹ bá ń ka Bíbélì. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò láyọ̀ láti ràn yín lọ́wọ́, kí ẹ baà lè lóye àwọn ohun tí ẹ ń kà nínú Bíbélì dáradára sí i.” Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ̀ ọ́ lọ́fẹ̀ẹ́.

5 Bí o bá ní ìjíròrò pẹ̀lú ọ̀dọ́ kan, o lè sọ pé:

◼ “N óò fẹ́ láti bí ọ ní ìbéèrè kan: Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́ kan, o ha rò pé o ní ìdí láti ní ìfojúsọ́nà fún rere nípa ọjọ́ ọ̀la bí? Lójú tìrẹ, báwo ni ọjọ́ ọ̀la ti rí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] A dúpẹ́ pé ìdí rere wà láti ní ìfojúsọ́nà fún rere nípa ọjọ́ ọ̀la. [Ka Pétérù Kejì 3:13.] Ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kì í ṣe ti ènìyàn, ó dáhùn àwọn ìbéèrè tí ó jẹ́ pé Ọlọ́run nìkan ni ó lè dáhùn rẹ̀. Gbàrà tí a bá ti gbà gbọ́ pé òtítọ́ ni ohun tí Bíbélì sọ, a óò wá ní ìrètí tí ó dájú nípa ọjọ́ ọ̀la. Bí o bá fẹ́, inú mi yóò dùn láti fi ẹ̀dà Bíbélì yìí sílẹ̀ fún ọ fún ọrẹ ₦120.”

6 Nígbà tí o bá padà bẹ ọ̀dọ́ tí ó gba Bíbélì lọ́wọ́ rẹ wò, o lè bẹ̀rẹ̀ nípa wíwí pé:

◼ “Mo mọrírì sísọ tí o sọ fún mi nípa bí o ti bìkítà tó nípa ọjọ́ ọ̀la. Rántí pé mo fi ẹsẹ Bíbélì kan hàn ọ́, tí ó ṣèlérí ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀, tí ó fọkàn ẹni balẹ̀, fún wa. Òmíràn nìyí. [Ka Ìṣípayá 21:3, 4.] Bíbélì fúnra rẹ̀ pèsè ẹ̀rí ìdánilójú pé òun jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kì í ṣe ti ènìyàn. Kíyè sí ohun tí ó sọ nínú Tímótì Kejì 3:16. [Kà á.] Bí o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, inú mi yóò dùn láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ lọ́fẹ̀ẹ́.”

7 Ẹni tí kò mọ ibi tí yòó yíjú sí fún ìtọ́sọ́nà láti kojú ìṣòro ìgbésí ayé lè dáhùn padà sí ọ̀nà ìyọsíni yìí:

◼ “A ń gbé ní àkókò tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ènìyàn ni ó dojú kọ ìṣòro ńlá. Ọ̀pọ̀ ń yíjú sí onírúurú agbaninímọ̀ràn fún ìtọ́sọ́nà. Níbo ni o rò pé a ti lè rí ìmọ̀ràn yíyè kooro, tí yóò múná dóko? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bíbélì sọ òtítọ́ ṣíṣe kókó kan tí ó yẹ kí gbogbo wa lóye. Jẹ́ kí a wo ohun tí Ìṣípayá 1:3 sọ. [Kà á.] Ọ̀pọ̀ jù lọ ìṣòro tí ń pọ́n aráyé lójú jẹ́ àbájáde tààràtà títẹ̀ tí àwọn ènìyàn kò tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bíbélì yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lóye bí gbogbo ìṣòro wa yóò ṣe dópin lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ìwọ yóò ha fẹ́ láti kà á bí?” Lẹ́yìn náà, fi Bíbélì lọ̀ ọ́ ní iye tí a ń fi síta.

8 Bí o bá sọ̀rọ̀ nípa àìní ènìyàn fún ìtọ́sọ́nà nígbà ìkésíni rẹ àkọ́kọ́, o lè máa bá ìjíròrò rẹ lọ nígbà ìpadàbẹ̀wò nípa wíwí pé:

◼ “Nígbà tí a kọ́kọ́ pàdé, a fohùn ṣọ̀kan pé a nílò ìtọ́sọ́nà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí a óò bá ṣàṣeyọrí nínú kíkojú ìṣòro ìgbésí ayé. Nítorí náà, mímọ̀ pé Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń mú ìbùkún wá. A ń bù kún wa nítorí pé a ń rí ìtọ́sọ́nà fún ìgbésẹ̀ wa ojoojúmọ́, tí a kò lè rí níbòmíràn. Ṣùgbọ́n, má ṣe gbàgbé pé, ẹrù iṣẹ́ kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti fífi ohun tí ó sọ sọ́kàn já lé wa léjìká. Mo láyọ̀ láti fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ̀ ọ́ lọ́fẹ̀ẹ́, mo sì ti ṣe tán láti fi bí a ti ń ṣe é hàn ọ́ ní báyìí.”

9 Jèhófà yóò bù kún ìsapá wa, bí a ti ń ran tọmọdé tàgbà lọ́wọ́ láti mọrírì ìjẹ́pàtàkì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ìtọ́sọ́nà rẹ̀ nínú ìgbésí ayé wa.—Orin Da. 119:105.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́