Fífi Ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun Lọni
1 Ìgbà gbogbo ni ìwé náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun máa ń mú wa láyọ̀. Àwọn aláìlábòsí ọkàn mọrírì ìwé náà, ó sì ti ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́wọ́ láti mú ìdúró wọn lọ́dọ̀ Jèhófà kí wọ́n sì ṣe batisí. Ó fi òtítọ́ hàn lọ́nà rere. A pète ìwé náà láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti tètè ní ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́. Ní December a óò ní àǹfààní lẹ́ẹ̀kan sí i láti fi ìwé yìí lọni ní ìpínlẹ̀ wa. Bákan náà, a gbọ́dọ̀ ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tí ó fi ọkàn ìfẹ́ hàn. Kí ni a lè sọ láti ru ọkàn ìfẹ́ sókè kí a sì fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún ìpadàbẹ̀wò?
2 Ìgbékalẹ̀ kan nìyí tí ó lè fa ẹni tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Ọlọ́run ti dín kù mọ́ra:
◼ “Ọ̀pọ̀ ènìyàn dàgbà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nísinsìnyí wọ́n rí i pé ìgbàgbọ́ wọn kò rí bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Kí ni o rò pé ó fa ìyẹn? [Jẹ́ kí ó dáhùn.] Ìgbàgbọ́ wa nínú Ọlọ́run ni a ń fún lókun nípa ríronú nípa àwọn ohun àgbàyanu tí ó wà ní àgbáálá ayé. [Ka Orin Dáfídì 19:1.] Ẹni náà tí àwọn òfin rẹ̀ ń darí àwọn àgbájọpọ̀ ìṣẹ̀dá ojú ọ̀run yìí ti pèsè ìdarísọ́nà tí ó ṣeyebíye fún wa pẹ̀lú. [Ka Orin Dáfídì 19:7-9.] Ẹsẹ wọ̀nyí tẹnu mọ́ bí ó ti ṣe pàtàkì tó láti kọ́ gbogbo ohun tí a bá lè kọ́ nípa Ọlọ́run àti àwọn ète rẹ̀. [Pe àfiyèsí sí àwòrán tí ó wà ní ojú ewé 4 àti 5, kí o sì ka ọ̀rọ̀ tí a kọ sára àwòrán náà.] Bí ìwọ bá fẹ́ láti jàǹfààní láti inú àkànṣe ìmọ̀ yí, inú mi yóò dùn láti fi ìwé yìí sílẹ̀ pẹ̀lú rẹ fún ọrẹ ₦55.”
3 Bí o bá bá ẹnì kan tí kò ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run sọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n tí ó fi ọkàn ìfẹ́ díẹ̀ hàn, ìwọ lè bẹ̀rẹ̀ nípa ṣíṣí ìwé náà sí àwòrán tí ó wà ní ojú ewé 4 àti 5, kí o sì sọ pé:
◼ “Nígbà tí mo wá síbi níjọ̀ọ́sí, a wo àwòrán fífani mọ́ra ti àwọn àyíká ẹlẹ́wà yí. Ọ̀rọ̀ tí a kọ sára àwòrán náà béèrè pé, ‘Kí ni o gbọ́dọ̀ ṣe láti gbádùn wọn?’ Báwo ni ìwọ yóò ṣe dáhùn ìyẹn? [Jẹ́ kí ó dáhùn.] Lọ́nà tí ó ṣe kedere, Bíbélì fi ọ̀kan nínú àwọn ohun pàtàkì tí a ń béèrè hàn. [Ka Jòhánù 17:3.] Ìmọ̀ ṣe pàtàkì sí ìgbàgbọ́ wa nínú Ọlọ́run. Ọ̀nà títayọ tí a lè gbà kọ́ ohun tí ó yẹ kí a mọ̀ jẹ́ nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé.” Ṣí orí 1 kí o sì tọ́ka sí àwọn ohun afúnniníṣìírí mélòó kan tí a gbé yẹ̀ wò nínú ìpínrọ̀ 1 sí 5. Ṣàlàyé bí a ṣe ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, sì sọ fún un pé ìwọ yóò fẹ́ láti pa dà wá fún ìjíròrò síwájú sí i.
4 Bí o bá ní ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí ń bani nínú jẹ́ nínú ìròyìn àìpẹ́ yìí lọ́kàn, o lè sọ pé:
◼ “Ó ṣeé ṣe kí o ti gbọ́ nípa [mẹ́nu kan ìṣẹ̀lẹ̀ náà]. Ìwọ ha ti ṣe kàyéfì rí nípa bóyá Ọlọ́run, ní ti gidi, ń bìkítà nípa àìsí ìdájọ́ òdodo àti ìjìyà tí a ń rí ní àyíká wa tàbí tí àwa fúnra wa pàápàá ń nírìírí rẹ̀? [Jẹ́ kí ó dáhùn.] Bíbélì mú un dá wa lójú pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa àti pé òun yóò ràn wá lọ́wọ́ láti la àwọn àkókò wàhálà já.” Kà lára àwọn ẹsẹ inú Orin Dáfídì 72:12-17. Ṣí ìwé Ìmọ̀ sí ojú ewé 70, kí o sì fi hàn pé ó dáhùn ìbéèrè kan tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn ti béèrè pé, Èé ṣe tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà? Lẹ́yìn náà, máa bá a nìṣó nípa sísọ pé, “Ìwọ yóò rí i pé ìdáhùn Bíbélì sí ìbéèrè yẹn jẹ́ èyí tí ń tuni nínú gidigidi. Èmi yóò fẹ́ láti fi ìwé yìí sílẹ̀ pẹ̀lú rẹ fún ọrẹ ₦55, kí o lè kà nípa rẹ̀ fúnra rẹ.”
5 Bí o bá pa dà wá láti máa bá ìjíròrò rẹ nìṣó lórí ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà, o lè sọ pé:
◼ “Nígbà tí mo wá síbí kẹ́yìn, a sọ̀rọ̀ nípa [ohun yòó wù tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà jẹ́]. Ìbéèrè jẹ yọ ní ti ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà púpọ̀ bẹ́ẹ̀ nínú ayé. Orí ìparí èrò wo ni o dé? [Jẹ́ kí ó dáhùn.] Ó fúnni níṣìírí láti mọ̀ pé kì í ṣe Ọlọ́run ni ó fa irú àwọn ipò tí ń kó wàhálà báni bẹ́ẹ̀.” Ṣí ìwé Ìmọ̀ sí ojú ewé 71 àti 72, kí o sì jíròrò díẹ̀ nínú àwọn èrò inú Ìwé Mímọ́ tí a kárí nínú ìpínrọ̀ 3 sí 5. Sọ fún un pé ìwọ yóò fẹ́ láti pa dà wá láti ṣàlàyé ìdí tí ó fi lè dá wa lójú pé àyè tí Ọlọ́run fi gba ìjìyà yóò dópin láìpẹ́.
6 Bí o bá bá òbí kan pàdé, o lè darí àfiyèsí sórí ìdílé:
◼ “Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn òbí gbà pé ìṣòro púpọ̀ ní ń bẹ nínú gbígbìyànjú láti gbé ìgbésí ayé ìdílé aláyọ̀. Kí ni o kíyè sí pé ó jẹ́ ìdènà tí ó tóbi jù? [Jẹ́ kí ó dáhùn.] Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wa ń ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe, ṣùgbọ́n a sábà máa ń mọrírì àrànṣe tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ kí ọwọ́ wa tẹ àwọn àbájáde tí ó sàn jù. Bíbélì fúnni ní ìmọ̀ràn tí ó ta yọ. [Kà lára àwọn ẹsẹ inú Kólósè 3:12, 18-21.] Bíbélì ní púpọ̀ sí i láti sọ lórí kókó yìí, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàlàyé rẹ̀ ní orí 15 nínú ìwé yìí, tí a pe àkọlé rẹ̀ ní ‘Gbígbé Ìdílé Kan Tí Ó Bọlá fún Ọlọ́run Ró.’ Ó ṣàyẹ̀wò ìmọ̀ràn tí a fúnni nínú Bíbélì tí ó ń fi hàn bí a ṣe lè mú másùnmáwo lọ́kọláya kúrò àti bí a ṣe lè kojú àwọn ìṣòro tí ń dojú kọ àwọn ọmọ wa. Ó dá mi lójú pé ìwọ yóò gbádùn kíkà á.”
7 Bí o bá ń pa dà láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ òbí kan tí ó ń ṣàníyàn nípa àwọn ìṣòro ìdílé, o lè sọ èyí:
◼ “Mo mọ̀ pé ìwọ, gẹ́gẹ́ bí òbí, ń fẹ́ ohun tí ó dára jù lọ fún àwọn ọmọ rẹ. Níwọ̀n bí kò ti ṣeé ṣe láti dáàbò bò wọ́n kúrò lọ́wọ́ ohun gbogbo tí ó burú, o ní láti kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè kojú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé. Ọ̀nà wo ni o rò pé a lè gbà ṣe ìyẹn? [Jẹ́ kí ó dáhùn.] Ọ̀kan nínú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ tí òbí lè pèsè ni ìdánilẹ́kọ̀ọ́.” Ṣí ìwé Ìmọ̀ sí ojú ewé 145 àti 146, kí o sì pe àfiyèsí sí ìmọ̀ràn Bíbélì tí ó gbéṣẹ́, kí o tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì rẹ̀ àti bí títẹ̀lé e ṣe lè jẹ́ ìbùkún. Sọ fún un pé ìwọ yóò fẹ́ láti pa dà wá láti fi bí a ṣe lè lo ìwé yìí láti kọ́ púpọ̀ sí i nípa bí a ṣe lè ní ìgbésí ayé ìdílé aláyọ̀ hàn án.
8 Dájúdájú, ìwé yìí jẹ́ ìpèsè àgbàyanu láti ọ̀dọ̀ Jèhófà láti mú kí iṣẹ́ ìkónijọ náà ‘yára kánkán’ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yí. (Aísá. 60:22) Bí a bá lò ó lọ́nà tí ó gbéṣẹ́, a lè fúnni ní ìmọ̀ tí ó lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti jèrè ìyè àìnípẹ̀kun.