Sọ̀rọ̀ Láìṣojo
1 Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ní àwọn àgbègbè kan, àwọn akéde ń rí i pé ó túbọ̀ ń nira láti bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ nínú ilé wọn. Ọ̀pọ̀ ròyìn pé, a kì í bá èyí tí ó ju àádọ́ta nínú ọgọ́rùn ún àwọn ènìyàn ní àwọn ìpínlẹ̀ wọn nílé, nígbà tí a bá ṣe ìkésíni láti ilé dé ilé. Nítorí èyí, ọ̀pọ̀ nínú àkókò tí a ń lò ni kì í méso jáde.
2 Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, a máa ń rí ọ̀pọ̀ ènìyàn nílé ní Sunday, èyí tí ọ̀pọ̀ kà sí ọjọ́ ìsinmi. Àṣà ti yí padà. Ó wọ́pọ̀ lónìí pé kí àwọn ènìyàn lọ sẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn, bójú tó àwọn àìní ìdílé, irú bíi lílọ rajà, tàbí kí wọ́n lọ́wọ́ nínú eré ìnàjú, èyí tí ń mú kí wọ́n filé sílẹ̀ pẹ̀lú. Àní ní ọjọ́ Sunday pàápàá, kíkàn sí àwọn ènìyàn láti ilé dé ilé ti di ìṣòro ìgbà gbogbo.
3 Nígbà tí àwọn ènìyàn kò bá sí nílé, ó túmọ̀ sí pé wọ́n wà níbòmíràn. Níwọ̀n bí góńgó wa ti jẹ́ láti bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, èé ṣe tí a kò fi bá àwọn tí a ń bá pàdé—ní òpópónà, ní ọjà, tàbí níbi iṣẹ́ sọ̀rọ̀. Ó jẹ́ àṣà Paulu láti tọ “awọn wọnnì tí ó ṣẹlẹ̀ pé wọ́n wà ní àrọ́wọ́tó” lọ, láti jẹ́rìí fún wọn. (Ìṣe 17:17) Èyí jẹ́ ọ̀nà ìjẹ́rìí kan tí ó méso jáde nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ó sì jẹ́ ọ̀nà ìjẹ́rìí kan tí ń méso jáde lọ́jọ́ wa.
4 Nígbà tí a bá ń lọ láti ilé dé ilé, a sábà máa ń rí àwọn ènìyàn tí ń rìn lọ ní gbẹ̀fẹ́ tàbí bóyá tí wọ́n ń tẹsẹ̀ dúró de ẹnì kan. Ní ọjọ́ tí ojú ọjọ́ bá dára, wọ́n lè máa fọ aṣọ wọn tàbí ṣiṣẹ́ lórí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọn. Ohun tí a nílò láti bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ lè má ju ẹ̀rín músẹ́ bí aládùúgbò àti ìkíni bí ọ̀rẹ́ lọ. Bí wọ́n bá ń gbé nítòsí, a tilẹ̀ lè mẹ́nu kàn án pé, ó ṣeé ṣe pé díẹ̀ ni a fi tàsé wọn nílé, inú wa sì dùn pé a ní àǹfààní yìí láti bá wọn sọ̀rọ̀ nísinsìnyí. Ọ̀pọ̀ ti gbádùn ìrírí tí ń mérè wá, nípa lílo ìdánúṣe láti túbọ̀ fi ìgboyà hàn.
5 Àìṣojo Ń Mú Ìyọrísí Rere Jáde: Arákùnrin kan ròyìn pé òún máa ń tọ àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ní ìdúró, tí ń dúró de ọkọ̀, tí ń rìn lọ ní gbẹ̀fẹ́, tàbí tí ó jókòó sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọn lọ. Pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ ọlọ́yàyà àti ohùn jíjí pépé, ó máa ń ṣe bí aládùúgbò, ẹni bí ọ̀rẹ́, tí ó wulẹ̀ ń ṣèbẹ̀wò. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, kì í ṣe pé ó ti ṣeé ṣe fún un láti fi ọ̀pọ̀ ìwé síta nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún ti ṣeé ṣe fún un láti bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli.
6 Arákùnrin mìíràn àti ìyàwó rẹ̀ wà nínú iṣẹ́ ilé dé ilé nígbà tí wọ́n ṣalábàápàdé obìnrin kan tí ó fa àpò ńlá tí ó lọ fi rajà lọ́wọ́. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀, ní gbígbóríyìn fún un fún jíjẹ́ aláápọn ní bíbójú tó àìní ìdílé rẹ̀. Wọ́n béèrè pé: “Ṣùgbọ́n, ta ni ó lè tẹ́ àìní aráyé lọ́rùn?” Èyí ru ọkàn-ìfẹ́ obìnrin náà sókè. Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ráńpẹ́ yọrí sí kíké sí wọn wá sínú ilé rẹ̀, níbi tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli.
7 Nítorí náà, nígbà míràn tí o bá tún ń jẹ́rìí láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà, ì bá à ṣe ní Sunday tàbí ní ọjọ́ mìíràn láàárín ọ̀sẹ̀, tí o sì rí i pé àwọn ènìyàn kò sí nílé, èé ṣe tí o kò túbọ̀ máyà le, kí o sì bá àwọn ènìyàn tí o bá pàdé sọ̀rọ̀—ní òpópónà tàbí níbòmíràn? (1 Tessa. 2:2) Ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí ó túbọ̀ méso jáde, ìwọ yóò sì gbádùn ayọ̀ púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ.