Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní January: Mimu Ki Igbesi Ayé Idile Rẹ Jẹ Alayọ tàbí Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia,” fún ₦80. Ìjọ tí ó ní ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí, tí a tẹ̀ sórí bébà tí ń di pípọ́n ràkọ̀ràkọ̀ tàbí tí ń pàwọ̀ dà tàbí èyíkéyìí tí a tẹ̀ jáde ṣáájú 1982, lé fi wọ́n lọni ní ẹ̀dínwó ₦40. Irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀ ni a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ fi lọni. A kò gbọdọ̀ fi àwọn ìtẹ̀jáde tí a tẹ̀ sórí bébà tí kì í ṣá tàbí pàwọ̀ dà kún àwọn ìfilọni ẹlẹ́dìn-ínwó yìí. February: Efik, Gẹ̀ẹ́sì, àti Igbo—Yálà Mimu Ki Igbesi Ayé Idile Rẹ Jẹ Alayọ tàbí Revelation—Its Grand Climax At Hand! Àwọn èdè yòókù—Yálà Mimu Ki Igbesi Ayé Idile Rẹ Jẹ Alayọ tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. ÀKÍYÈSÍ: Àwọn ìjọ tí yóò nílò àwọn ìwé ìgbétásì tí a mẹ́nu kàn lókè yìí ní láti béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn, ti oṣù tí ń bọ̀.
◼ Àwọn ìjọ ní láti ṣe ètò rírọgbọ láti ṣe ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ọdún yìí ní Tuesday, April 2, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀. Ó dára pé kí ìjọ kọ̀ọ̀kan ṣe ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí tirẹ̀, ṣùgbọ́n èyí lè má fìgbà gbogbo ṣeé ṣe. Níbi tí ó ti jẹ́ pé àwọn ìjọ púpọ̀ ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà, bóyá ìjọ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lè gba gbọ̀ngàn míràn fún lílò ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn. Kò yẹ kí bíbẹ̀rẹ̀ Ìṣe Ìrántí náà pẹ́ jù débi tí kì yóò fi rọrùn fún àwọn olùfìfẹ́hàn tuntun láti pésẹ̀. Síwájú sí i, ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà kò gbọdọ̀ kún fọ́fọ́ jù débi pé kò ní sí àkókò ṣáájú àti lẹ́yìn ayẹyẹ náà láti kí àwọn àlejò, láti ṣètò ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí tí ń bá a lọ fún àwọn kan, tàbí láti gbádùn ìṣepàṣípààrọ̀ ìṣírí ní gbogbogbòò. Lẹ́yìn gbígbé gbogbo nǹkan yẹ̀ wò dáradára, àwọn alàgbà ní láti pinnu ètò tí yóò ran àwọn tí wọ́n pésẹ̀ síbi Ìṣe Ìrántí náà lọ́wọ́ jù lọ láti jàǹfààní kíkún rẹ́rẹ́ láti inú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
◼ A óò sọ ọ̀rọ̀ àsọyé ìtagbangba àkànṣe fún àkókò Ìṣe Ìrántí 1996 ní Sunday, April 21. Ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọyé náà yóò jẹ́, “Wíwà Láìlẹ́bi Láàárín Ìran Oníwà Wíwọ́ Kan.” A óò pèsè ìlapa èrò kan. Àwọn ìjọ tí yóò ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká, àpéjọ àyíká, tàbí ọjọ́ àpéjọ àkànṣe ní òpin ọ̀sẹ̀ yẹn, yóò sọ ọ̀rọ̀ àsọyé àkànṣe náà ní ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e. Ìjọ kankan kò gbọdọ̀ sọ àsọyé àkànṣe náà ṣáájú April 21.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti February, tí kò sì ní pẹ́ ju March 3 lọ, ọ̀rọ̀ àsọyé ìtagbangba tuntun fún àwọn alábòójútó àyíká yóò jẹ́, “Ìjọ Adúróṣinṣin Kan Lábẹ́ Ipò Ìdarí Kristi.” Àwọn alábòójútó àyíká tí ó ṣì ń fi àwòrán slide náà, “Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá Ń Yọ Ayọ̀ Ìṣẹ́gun Kárí Ayé,” hanni, yóò máa bá a lọ títí tí gbogbo ìjọ ní àyíká náà yóò fi gbọ́ ọ̀rọ̀ àsọyé aláwòrán slide náà. Bí ó ti wù kí ó rí, ní àwọn àyíká tí a kò ti ń fi àwòrán slide hàn, alábòójútó àyíká yóò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àsọyé tuntun náà, gẹ́gẹ́ bí a ti là á lẹ́sẹẹsẹ sókè.
◼ A óò mú Ilé-Ìṣọ́nà olóṣooṣù, tí yóò jáde nígbà kan náà, jáde ní èdè Isoko, bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìtẹ̀jáde January 1, 1996.
◼ Yearbook fún Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà—Gbogbo aṣáájú ọ̀nà déédéé àti àkànṣe, tí ó forúkọ sílẹ̀ ṣáájú tàbí ní July 1, 1995, lẹ́tọ̀ọ́ sí ẹ̀dà Yearbook kan lọ́fẹ̀ẹ́. A lè gba èyí nínú ẹrù tí a fi ránṣẹ́ sí ìjọ. A gbọ́dọ̀ kọ iye Yearbook ọ̀fẹ́ tí a fún àwọn aṣáájú ọ̀nà sórí fọ́ọ̀mù ìfowóránṣẹ́ S-20, kí a baà lè yọ owó ọ̀kọ̀ọ̀kan kúrò. Àwọn aṣáájú ọ̀nà lè gba àfikún Yearbook ní ẹ̀dínwó aṣáájú ọ̀nà. Àwọn wọ̀nyí jẹ́ fún ìlò nínú pápá. A gbọ́dọ̀ kọ èyí sí ibòmíràn lábẹ́ ẹ̀dínwó aṣáájú ọ̀nà, lórí fọ́ọ̀mù ìfowóránṣẹ́ S-20. Kọ “Yearbook fún ẹ̀dínwó aṣáájú ọ̀nà” síbẹ̀. A kò gbọdọ̀ jẹ́ kí àwọn wọ̀nyí dà rú pọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀dà tí a fún àwọn aṣáájú ọ̀nà lọ́fẹ̀ẹ́. A óò dínwó ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan tí ẹ tà fún àwọn aṣáájú ọ̀nà lẹ́dìn-ínwó.
◼ Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ fún Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà—Gbogbo aṣáájú ọ̀nà déédéé àti àkànṣe, tí ó forúkọ sílẹ̀ ṣáájú tàbí ní July 1, 1995, lẹ́tọ̀ọ́ sí ẹ̀dà kan lọ́fẹ̀ẹ́ fún ìlò ara ẹni. Fún ọ̀kọ̀ọ̀kan tí a fi fúnni, a óò yọ owó rẹ̀ kúrò nínú àkọsílẹ̀ ìṣirò owó ìwé yín. A kò fi àwọn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ kún àwọn ìṣètò wọ̀nyí. Pẹ̀lúpẹ̀lú, a ní láti kọ iye es96-YR tí a fún àwọn aṣáájú ọ̀nà lọ́fẹ̀ẹ́ sórí fọ́ọ̀mù ìfowóránṣẹ́ S-20, kí a baà lè yọ owó ọ̀kọ̀ọ̀kan kúrò.