Jóòbù
21 Jóòbù fèsì pé:
2 “Ẹ fara balẹ̀ fetí sí ọ̀rọ̀ mi;
Kí èyí jẹ́ ohun tí ẹ fi máa tù mí nínú.
3 Ẹ gba tèmi rò tí mo bá ń sọ̀rọ̀;
Tí mo bá sọ̀rọ̀ tán, ẹ lè wá fi mí ṣe yẹ̀yẹ́.+
4 Ṣé èèyàn kan ni mò ń ṣàròyé fún ni?
Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé mo* máa lè ní sùúrù?
5 Ẹ wò mí, kí ẹnu sì yà yín;
Ẹ fi ọwọ́ bo ẹnu yín.
6 Tí mo bá ń rò ó, ọkàn mi kì í balẹ̀,
Gbogbo ara mi sì ń gbọ̀n rìrì.
8 Gbogbo ìgbà ni àwọn ọmọ wọn ń wà lọ́dọ̀ wọn,
Wọ́n sì ń rí àtọmọdọ́mọ wọn.
9 Ààbò wà lórí ilé wọn, wọn ò bẹ̀rù rárá,+
Ọlọ́run ò sì fi ọ̀pá rẹ̀ jẹ wọ́n níyà.
10 Akọ màlúù wọn ń gùn, kì í sì í tàsé;
Abo màlúù wọn ń bímọ, oyún ò sì bà jẹ́ lára wọn.
11 Àwọn ọmọkùnrin wọn ń sáré jáde bí agbo ẹran,
Àwọn ọmọ wọn sì ń ta pọ́n-ún pọ́n-ún.
14 Àmọ́ wọ́n sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ pé, ‘Fi wá sílẹ̀!
Kò wù wá pé ká mọ àwọn ọ̀nà rẹ.+
15 Ta ni Olódùmarè, tí a fi máa sìn ín?+
Èrè wo la máa rí tí a bá mọ̀ ọ́n?’+
16 Àmọ́ mo mọ̀ pé agbára wọn kọ́ ló mú wọn láásìkí.+
Èrò* àwọn ẹni burúkú jìnnà sí mi.+
17 Ìgbà mélòó là ń fẹ́ fìtílà àwọn ẹni burúkú pa?+
Ìgbà mélòó ni àjálù ń dé bá wọn?
Ìgbà mélòó ni Ọlọ́run ń fi ìbínú pa wọ́n run?
18 Ṣé wọ́n dà bíi pòròpórò rí níwájú atẹ́gùn
Àti bí ìyàngbò* tí ìjì gbé lọ?
19 Ọlọ́run máa fi ìyà èèyàn pa mọ́ de àwọn ọmọ rẹ̀;
Àmọ́ kí Ọlọ́run san án lẹ́san, kó bàa lè mọ̀ ọ́n.+
20 Kó fi ojú ara rẹ̀ rí ìparun rẹ̀,
Kí òun fúnra rẹ̀ sì mu nínú ìbínú Olódùmarè.+
21 Torí kí ló ṣe ń ronú ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ilé rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀,
22 Ṣé ẹnì kankan lè kọ́ Ọlọ́run ní ohunkóhun,*+
Nígbà tó jẹ́ pé Òun ló ń dá ẹjọ́ àwọn ẹni gíga jù pàápàá?+
24 Nígbà tí ọ̀rá kún itan rẹ̀,
Tí egungun rẹ̀ sì le.*
25 Àmọ́ ẹlòmíì kú nínú ìbànújẹ́,*
Láì gbádùn ohun rere kankan rí.
28 Torí ẹ sọ pé, ‘Ibo ni ilé ẹni tó gbajúmọ̀ wà,
Ibo sì ni àgọ́ tí ẹni burúkú gbé wà?’+
29 Ṣebí ẹ ti béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn arìnrìn-àjò?
Ṣebí ẹ̀ ń fara balẹ̀ wo àwọn ohun tí wọ́n rí,*
30 Pé à ń dá ẹni ibi sí ní ọjọ́ àjálù,
A sì ń gbà á sílẹ̀ ní ọjọ́ ìbínú?
31 Ta ló máa kò ó lójú nípa ọ̀nà rẹ̀,
Ta ló sì máa san án lẹ́san ohun tó ṣe?
32 Tí wọ́n bá gbé e lọ sí itẹ́ òkú,
Wọ́n máa ṣọ́ ibojì rẹ̀.
33 Iyẹ̀pẹ̀ tó ṣù pọ̀ ní àfonífojì máa dùn mọ́ ọn lẹ́nu,+
Bí àìmọye tó ṣáájú rẹ̀.
34 Kí ló dé tí ẹ wá ń fún mi ní ìtùnú tí kò nítumọ̀?+
Ẹ̀tàn ni gbogbo ìdáhùn yín!”