Gbọ́rọ̀ Kalẹ̀ Lọ́nà Tó Máa Bá Onírúurú Ipò Mu
Bí a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn látọkànwá, a ó fojú sílẹ̀ láti mọ ìṣòro tí wọ́n ní ká bàa lè kọ́ wọn nípa bí Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣe yanjú àwọn ìṣòro wọn. (Fílí. 2:4) Báwọn akéde kan ṣe máa ń gbé ọ̀rọ̀ wọn kalẹ̀ tó sábà máa ń bá ipò onílé mu ni pé wọ́n máa ń jẹ́ kí onílé sọ èrò rẹ̀ lórí àwọn àwòrán bí Párádísè yóò ṣe rí tó wà nínú àwọn ìwé wa, bí irú àwọn tá a tò sí apá ọ̀tún ìwé yìí. Láti ṣe èyí, o lè lo ọ̀kan lára àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e yìí:
◼ “Ǹjẹ́ o rò pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tí gbogbo èèyàn á máa gbádùn bíi tàwọn tó wà nínú àwòrán yìí?”
◼ “Kò sí ẹni tí kò wù káwọn ọmọ ẹ̀ gbádùn ayé wọn bíi tàwọn tó wà nínú àwòrán yìí. Kí lo rò pé ó lè mú kí èyí ṣeé ṣe?”
◼ “Nígbà tí ìfẹ́ Ọlọ́run bá di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé bíi ti ọ̀run, bí ilé ayé wa ṣe máa rí rèé. Nínú àwòrán yìí, ǹjẹ́ o rí ohun tó yàtọ̀ sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé wa lónìí?”
◼ “Ṣé wàá fẹ́ gbé nínú irú ibi tó wà nínú àwòrán yìí? [Jẹ́ kó fèsì.] Ǹjẹ́ o rò pé èyí lè ṣẹlẹ̀ lójú ẹ̀mí wa?”
Fara balẹ̀ gbọ́ ìdáhùn rẹ̀, kó o wá bi í ní ìbéèrè kan tàbí méjì sí i láti fi mọ èrò ọkàn rẹ̀. Tí àwọn kan bá wá fèsì pé ní tàwọn o, àwọn ò fẹ́ láti gbé nínú irú ibi tó wà nínú àwòrán yẹn tàbí tí wọ́n bá sọ pé àlá tí ò lè ṣẹ ni, má ṣe yára kà wọ́n sẹ́ni tí ò níkan-án ṣe. Ńṣe ni kó o fọgbọ́n wádìí ohun tó fà á tí wọ́n fi sọ bẹ́ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí ìdáhùn wọn fi hàn pé àwọn ìṣòro tó dà bíi pé kò lójútùú tí ọmọ aráyé ń ní ló ti bà wọ́n lọ́kàn jẹ́ tó bẹ́ẹ̀.—Ìsík. 9:4.
Bó o bá ti mọ ohun tó ń jẹ onílé lọ́kàn, gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà tó máa bá ipò rẹ̀ mu. Sọ̀rọ̀ nípa ohun tó bá àníyàn ọkàn rẹ̀ mu jù lọ nínú ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tàbí méjì tó sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn. (Wo àwọn àbá tó wà lápá ọ̀tún ìwé yìí.) Jẹ́ kó fojú ara rẹ̀ rí ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ. Bó bá fìfẹ́ hàn, fún un ní ìwé náà kó o sì ṣètò láti padà wá. Nígbà tó o bá padà bẹ̀ ẹ́ wò, ṣàlàyé síwájú sí í nípa ohun tẹ́ ẹ jọ sọ níṣàájú.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
Díẹ̀ Lára Àwọn Ibi Tí A Ti Lè Rí Àwòrán Bí Párádísè Yóò Ṣe Rí
Ìwé Olùkọ́ Ńlá: ojú ìwé 251 sí 254
Ìwé Ìmọ̀: ojú ìwé 4 àti 5, 188 àti 189
Ìwé pẹlẹbẹ Béèrè: ojú ìwé 11 àti 13
Ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run: ojú ìwé 92 àti 93
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
Àwọn Ìṣòro Táwon Èèyàn Ń Ṣàníyàn Nípa Rẹ̀
Àìsàn àti àbùkù ara
Àìsí ìwà ọmọlúwàbí láwùjọ
Àìtó oúnjẹ àti àìjẹunrekánú
Bíba ilé ayé jẹ́
Ẹ̀tanú àti ìwà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́
Híhùwà ìkà sí àwọn ẹranko
Òwe12:10
Ìdààmú ọkàn
Ìjọba tí kò lè bójú tó àwọn aráàlú bó ṣe yẹ
Ikú àti ọ̀fọ̀
Ipò òṣì àti ìninilára
Ìṣòro àìrílégbé àti àìríná-àìrílò
Ìwà ìbàjẹ́ àti ìwà ìrẹ́jẹ
Ìwà ọ̀daràn àti ìwà ipá
Ogun àti ìpániláyà