Gbígbé Ìhìn Rere Kalẹ̀ Pẹ̀lú Ẹ̀mí Ìfojúsọ́nà-Fún-Rere
1 Gbogbo wa ní ń fẹ́ láti rí ìdùnnú kí a sì ṣàṣeyọrí nínú àwọn ohun tí a ń ṣe, pàápàá jù lọ, nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Kí ní ń mú irú ìtẹ́lọ́rùn bẹ́ẹ̀ wá fún wa? Ó ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lu níní ẹ̀mí ìrònú onífojúsọ́nà-fún-rere, bí ọwọ́ wa ti ń dí gan-an nínú iṣẹ́ aṣeni-láǹfààní ti ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. (Òwe 11:25) Ọ̀nà tí a gbà ń gbé ìhìn rere kalẹ̀ yẹ kí ó fi hàn pé a gba ohun tí a ń sọ gbọ́ ní tòótọ́. Bí a bá sọ̀rọ̀ láti inú ọkàn wá, nígbà náà, òótọ́ inú àti ìdánilójú ìgbàgbọ́ wa yóò hàn síta kedere. (Luk. 6:45) Nípa ṣíṣe ìfidánrawò ìgbékalẹ̀ wa, a óò túbọ̀ nígboyà sí i nígbà tí a bá ń bá àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ wa sọ̀rọ̀. Èyí yóò ṣàǹfààní ní pàtàkì nínú oṣù September, nígbà tí a óò lọ́wọ́ nínú ìgbétásì àkànṣe, nípa fífi ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye ní èdè Yorùbá lọni, fún ẹ̀dínwó ₦50. Àmọ́ ṣáá o, ìwe Walaaye Titilae ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, kò sí lára ẹ̀dínwó náà, ó ṣì wà ní iye tí a ń fi síta, ₦120. Àwọn ìdámọ̀ràn tí ó tẹ̀ lé e yìí lè ṣàǹfààní fún ọ nínu fífi ẹ̀mí ìfojúsọ́nà-fún-rere gbé ìhìn rere kalẹ̀.
2 Nígbà tí o bá ń fi ìwe “Walaaye Titilae” lọni, o lè sọ èyí nígbà ìbẹ̀wò rẹ àkọ́kọ́:
◼ “Bí a ti ń bá àwọn aládùúgbò wa sọ̀rọ̀, a ń rí i pé àwọn ìkìmọ́lẹ̀ inú ìgbésí ayé ojoojúmọ́ ń fa ìnira ńlá fún àwọn ìdílé lónìí. Ó ń ṣòro fún ọ̀pọ̀ láti gbé pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan. Ibo ni wọ́n ti lè rí ìrànlọ́wọ́? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bíbélì lè ṣèrànwọ́ gidi fún wa. [Ka Tímótì Kejì 3:16, 17.] Ìwé Mímọ́ pèsè àwọn ìlànà tí ó ṣàǹfààní, tí ó lè ran ìdílé lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí. Kíyè sí ohun tí a sọ ní ìpínrọ̀ 3, ní ojú ìwé 238, ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye.” Ka ìpínrọ̀ 3, kí o sì fi ìwé náà lọ̀ ọ́.
3 Nígbà tí o bá ń padà ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tí o bá jíròrò ìṣeségesège ètò ìdílé, o lè fẹ́ láti sọ èyí:
◼ “Nígbà ìbẹ̀wò mi àkọ́kọ́, a sọ̀rọ̀ nípa ọgbọ́n tí ń bẹ nínú títẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì, kí a baà lè ní ìgbésí ayé ìdílé aláyọ̀. Kí ni o rò pé ó jẹ́ kọ́kọ́rọ́ sí síso ìdílé pọ̀ ṣọ̀kan lónìí?” Jẹ́ kí ó fèsì. Ṣí i sí ìpínrọ̀ 27, ní ojú ìwé 247, kí o sì ka Kólósè 3:12-14. Ṣàlàyé síwájú sí i lórí bí ojúlówó ìfẹ́ ṣe lè so ìdílé pọ̀ ṣọ̀kan. Ṣàlàyé bí kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwe Walaaye Titilae ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé ṣe lè ṣèrànwọ́ nínú yíyanjú ìṣòro. Bí ó bá gbà bẹ́ẹ̀, ṣàṣefihàn bí a ṣe ń fi Walaaye Titilae kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
4 O lè gbìyànjú ìgbékalẹ̀ yìí nígbà tí o bá ń fi ìwe “Walaaye Titilae” lọni:
◼ “Bí mo ti ń bá àwọn ènìyàn àdúgbò yìí sọ̀rọ̀, mo kíyè sí i pé, ọ̀pọ̀ jù lọ ń yán hànhàn fún àdúgbò tí ó fọkàn ẹni balẹ̀ àti ayé alálàáfíà. Kí ni èrò rẹ nípa ìdí tí ènìyàn fi kùnà láti mú irú ipò bẹ́ẹ̀ wá? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Àwọn aṣáájú kan lè lọ́kàn rere, kí wọ́n sì ṣe àwọn ohun rere díẹ̀, ṣùgbọ́n, kíyè sí ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí Bíbélì fúnni.” Ka Orin Dáfídì 146:3, 4; kí o sì béèrè lẹ́yìn náà pé: “Ẹnikẹ́ni ha wà tí ó lè tẹ́ àìní ènìyàn lọ́rùn bí?” Ka ẹsẹ 5 àti 6. Fi àwòrán tí ó wà ní ojú ìwé 12 àti 13 ìwe Walaaye Titilae hàn án, kí o sì pe àfiyèsí sí àwọn àǹfààní ìṣàkóso Ọlọ́run. Fi ìwé náà lọ̀ ọ́ fún ọrẹ ₦50.
5 Bí ẹ bá jíròrò nípa ìṣàkóso Ọlọ́run nígbà àkọ́kọ́, o lè gbìyànjú àbá yìí nígbà ìpadàbẹ̀wò:
◼ “Nígbà tí mo kàn sí ọ ní ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn, a jíròrò ìkùnà ènìyàn láti mú àlàáfíà tòótọ́ wá sórí ilẹ̀ ayé. O lè rántí pé a rí ìdí tí Bíbélì fúnni fún irú ìkùnà bẹ́ẹ̀. [Tún ka Orin Dáfídì 146:3 lẹ́ẹ̀kan sí i.] O ha kíyè sí ìdí tí Ọlọ́run fi gbà wá níyànjú láti má ṣe gbé ìrètí wa karí ẹ̀dá ènìyàn bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ó ṣeé ṣe kí o gbà pé, ìrètí èyíkéyìí fún ojútùú pípẹ́ títí ní láti ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Ìdí tí a fi lè ní ìgbọ́kànlé yìí ni a sọ nínú Orin Dáfídì 146:10. [Kà á.] Bí a bá fẹ́ jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, kí ni a ní láti ṣe?” Ṣí ìwe Walaaye Titilae sí ojú ìwé 15, ka ìpínrọ̀ 19, kí o sì pe àfiyèsí sí Jòhánù 17:3. Gbà láti ṣàṣefihàn bí àràádọ́ta ènìyàn ti jèrè ìmọ̀ tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun, nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí ó bá gbà, fi ìwé Ìmọ̀ lọ̀ ọ́, kí o sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́.
6 Nínú ṣíṣiṣẹ́ láti ìsọ̀ dé ìsọ̀ àti nínú ọjà, o lè lo ìgbékalẹ̀ ṣókí yìí, ní lílo ìwe “Walaaye Titilae”:
◼ “Lónìí, a ń ṣiṣẹ́ sin àwọn oníṣòwò àdúgbò yìí lọ́nà àkànṣe. Gbogbo wa ní ń ṣàníyàn nípa ìwà ọ̀daràn àti ìwà ipá tí ń peléke sí i ní agbègbè wa. O ha rò pé ẹnikẹ́ni ní ojútùú gidi sí ìṣòro náà bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ọlọ́run ní ojútùú sí i.” Ṣí ìwe Walaaye Titilae sí ojú ìwé 157; ka Òwe 2:22, tí ó wà ní ojú ewé náà, kí o sì ṣàlàyé rẹ̀. Fi àkòrí orí 19 hàn án, kí o sì fi ìwé náà lọ̀ ọ́.
7 Nígbà tí o bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ oníṣòwò kan tí o fi ìwe “Walaaye Titilae” síta fún, o lè sọ èyí:
◼ “Nígbà ìbẹ̀wò mi tí ó kẹ́yìn, mo mẹ́nu kàn án pé, Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni ó ní ojútùú pípẹ́ títí sí ìwà ọ̀daràn àti ìwà ipá. Ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, a lè ní ìgbọ́kànlé pé ilẹ̀ ayé alálàáfíà yóò wà ní tòótọ́. Kíyè sí yíyàn tí a gbé ka iwájú olúkúlùkù wa.” Ka ìpínrọ̀ 4, ní ojú ìwé 159, títí kan Orin Dáfídì 37:35-38, nínú ìwe Walaaye Titilae. Ṣàlàyé àwòran ojú ìwé 161, kí o sì ka àkọlé àwòrán, tí ó wà lókè. Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ lọ̀ ọ́, tí ẹ óò máa ṣe ní ìsọ̀ wọn tàbí ní ilé wọn.
8 Àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn tí a lè fi lọni nígbà ìgbétásì àkànṣe náà ni Ayọ̀—Bi A Ṣe Lè Rí I, Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ, Igbesi Aye Yii Ha Ni Gbogbo Ohun Ti O Wà Bi?, àti Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. Ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti ronú àwọn ìgbékalẹ̀ tí kò nira, nígbà tí o bá ń fi àwọn ìtẹ̀jáde wọ̀nyí lọni. Gẹ́gẹ́ bí “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run,” a ní ìdí púpọ̀ láti fojú sọ́nà fún rere, nígbà tí a bá ń gbé ìhìn rere kalẹ̀. (1 Kọr. 3:9) Níní irú ẹ̀mí ìrònú yìí yóò yọrí sí ìbùkún jìngbìnnì láti ọ̀dọ Jèhófà.