ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/99 ojú ìwé 8
  • Nawọ́ Ìkésíni sí Gbogbo Àwọn Tí Òùngbẹ Ń Gbẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Nawọ́ Ìkésíni sí Gbogbo Àwọn Tí Òùngbẹ Ń Gbẹ
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Dámọ̀ràn fún Lílò Lóde Ẹ̀rí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Fífi Ìjẹ́kánjúkánjú Sọ Ìhìn Rere Náà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Àwọn Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Tí A Dábàá fún Lílò Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Pápá
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Gbára Lé Jèhófà Láti Mú Kí Àwọn Nǹkan Dàgbà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
km 8/99 ojú ìwé 8

Nawọ́ Ìkésíni sí Gbogbo Àwọn Tí Òùngbẹ Ń Gbẹ

1 Gẹ́gẹ́ bí wòlíì Ámósì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ìdílé aráyé lónìí ‘ni òùngbẹ tí kì í ṣe fún omi, bí kò ṣe fún gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà ń gbẹ.’ (Ámósì 8:11) Láti ran àwọn èèyàn tí òùngbẹ nípa tẹ̀mí ń gbẹ yìí lọ́wọ́, a ń sọ fún wọn nípa àwọn ìpèsè tí Ọlọ́run ti ṣe láti gba àwọn èèyàn onígbọràn lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, tí orí tó kẹ́yìn nínú ìwé Ìṣípayá ṣàpèjúwe pé ó jẹ́ “odò omi ìyè kan.” A ní àǹfààní láti nawọ́ ìkésíni sí gbogbo àwọn tí òùngbẹ ń gbẹ fún òdodo láti “gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.” (Ìṣí. 22:1, 17) Báwo la ṣe lè ṣe èyí ní oṣù August? Nípa fífi onírúurú ìwé pẹlẹbẹ lọ àwọn tó bá fi ojúlówó ìfẹ́ hàn. O lè gbìyànjú àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí:

2 Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń ṣàníyàn nípa ọ̀ràn ìlera, o lè rí i pé ìgbékalẹ̀ yìí gbéṣẹ́ nípa lílo ìwé pẹlẹbẹ náà, “Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?”:

◼ “Ọ̀pọ̀ ń ṣàníyàn nípa owó ìgbàwòsàn tó gbámúṣé tí ń lọ sókè. Bóyá ìwọ náà ti ronú nípa ọ̀ràn yìí rí. [Jẹ́ kó fèsì.] Ohun kan ha wà tó lè mú kí ìṣòro yìí kásẹ̀ nílẹ̀ pátápátá bí? [Jẹ́ kó fèsì.] Ohun àgbàyanu kan táa lè fojú sọ́nà fún rèé.” Ka Ìṣípayá 22:1, 2. Lẹ́yìn náà, ṣí ìwé pẹlẹbẹ náà sí àwòrán tó wà ní ojú ewé 24, kí o sì lo ìpínrọ̀ 11 láti ṣàlàyé rẹ̀. Parí ọ̀rọ̀ rẹ nípa sísọ pé: “Ìtẹ̀jáde yìí jíròrò ìgbésẹ̀ tí o ní láti gbé tí yóò mú kí o lè máa fi ìgbọ́kànlé wo iwájú láti gbé nínú àgbàyanu ayé tuntun ti Ọlọ́run.” Fi ìwé pẹlẹbẹ náà lọ̀ ọ́ ní ₦15. Ṣètò láti padà lọ.

3 Nígbà tí o bá ń lọ padà bẹ̀ ẹ́ wò, o lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò rẹ nípa sísọ pé:

◼ “Nígbà tí mo wá síbí kẹ́yìn, a sọ̀rọ̀ nípa ohun kan tó lè mú kí àwọn ìṣòro ìlera kásẹ̀ nílẹ̀ pátápátá. Ǹjẹ́ o ronú pé àkókò yóò dé nígbà tí kò ní sẹ́ni tí yóò máa ṣàìsàn? [Jẹ́ kó fèsì.] Kíyè sí gbólóhùn tí ń gbàfiyèsí yìí.” Ka Aísáyà 33:24. Lẹ́yìn náà, ṣí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè sí Ẹ̀kọ́ 5, jíròrò ìpínrọ̀ 5 àti 6, béèrè àwọn ìbéèrè tó bá a mu tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ náà kí o sì ka díẹ̀ nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a yàn. Mẹ́nu kàn án pé mímú àìsàn àti ikú kúrò jẹ́ ara ìmúṣẹ ète tí Ọlọ́run ní ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ fún ilẹ̀ ayé. Ṣètò láti padà lọ láti jíròrò ìpínrọ̀ 1 sí 4 àti 7 nínú ẹ̀kọ́ kan náà.

4 Bí àwọn èèyàn bá ń ronú nípa ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ tó sọ nípa ẹni tó kú láìtọ́jọ́, o lè gbìyànjú ìgbékalẹ̀ yìí nípa lílo ìwé pẹlẹbẹ náà, “Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú”:

◼ “Ó ṣeé ṣe kí o ti gbọ́ nípa [mẹ́nu ba ìròyìn náà]. Nígbà tí ìjàǹbá bá ké ìwàláàyè àwọn èèyàn kúrú, ọ̀pọ̀ máa ń ṣe kàyéfì nípa ọ̀rọ̀ tó yẹ ká fi tu àwọn ìdílé àwọn tó kú nínú. Kí lo rò nípa rẹ̀?” Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ṣí ìwé pẹlẹbẹ náà sí ojú ìwé 30 kí o sì fi àwòrán tí a fi ṣàpèjúwe bí àjíǹde yóò ṣe rí han ẹni náà. Máa bọ́rọ̀ nìṣó nípa sísọ pé: “Ó máa ń ya ọ̀pọ̀ lẹ́nu láti gbọ́ pé àtolóòótọ́ àtaláìṣòótọ́ èèyàn ni a óò mú padà bọ̀ sí ìyè nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. [Ka Ìṣe 24:15 kí o sì ṣàlàyé rẹ̀.] Ìwé pẹlẹbẹ yìí jíròrò ọ̀pọ̀ ìsọfúnni mìíràn tó ń gbádùn mọ́ni nípa ète Ọlọ́run fún ọjọ́ ọ̀la. Bí o bá fẹ́ láti mọ púpọ̀ sí i nípa rẹ̀, ₦15 péré ni ẹ̀dà kan ìwé pẹlẹbẹ yìí yóò ná ọ.” Ṣètò láti padà lọ, kíyè sí ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan fẹ́ ní pàtó àti ohun tí wọ́n ń ṣàníyàn nípa rẹ̀.

5 Nígbà tí o bá tún padà lọ, mú kí ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ bá onílé mu. Bóyá o lè sọ pé:

◼ “Nígbà táa sọ̀rọ̀ kẹ́yìn, mo mọrírì gbólóhùn kan tóo sọ nípa ète Ọlọ́run fún ilẹ̀ ayé. [Mẹ́nu kan gbólóhùn náà.] Mo ṣàwárí àwọn ìsọfúnni tí mo ronú pé yóò gbádùn mọ́ ọ.” Ṣí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè sí Ẹ̀kọ́ 5. Ka ọ̀pọ̀ ìpínrọ̀ nínú ẹ̀kọ́ náà bí ó bá ti rí i pé onílé nífẹ̀ẹ́ sí i tó kí o sì jíròrò wọn. Lẹ́yìn tí o bá ti yan àkókò kan láti padà lọ láti máa bá ẹ̀kọ́ náà nìṣó, fún onílé ní ìwé ìléwọ́ tó sọ àwọn àkókò tí ìjọ ń ṣèpàdé. Ṣàlàyé fún un nípa Ìpàdé fún Gbogbo Ènìyàn, kí o sì ké sí i láti wá síbẹ̀.

6 Bí o bá ń fẹ́ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó rọrùn tó sọ̀rọ̀ nípa ìwé àṣàrò kúkúrú, o lè sọ pé:

◼ “Màá fẹ́ kí o ní ìwé àṣàrò kúkúrú yìí tí àkòrí rẹ̀ ń jẹ́, Ireti Wo ni Ó Wà fun Awọn Ololufẹ Tí Wọn Ti Kú?” Mú un lé onílé lọ́wọ́ kí o sì sọ pé kí ó máa fojú bá a lọ bí o ṣe ń ka ìpínrọ̀ kìíní. Jẹ́ kó fèsì sí ìbéèrè tí gbólóhùn tó kẹ́yìn béèrè. Ka ìpínrọ̀ kejì, kí o sì wá ṣí ìwé pẹlẹbẹ Ki Ni Ète Igbesi-Aye? sí àwòrán tó wà ní ojú ewé 31. Máa bọ́rọ̀ nìṣó nípa sísọ pé: “Ìtẹ̀jáde yìí sọ ọ̀pọ̀ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àjíǹde àti àwọn ìlérí àgbàyanu tí Bíbélì ṣe fún ọjọ́ ọ̀la. ₦15 péré ni ẹ̀dà yìí yóò ná ọ.” Ṣètò fún ìpadàbẹ̀wò.

7 Bí a bá ń ké sí àwọn èèyàn lọ́nà tó fà wọ́n mọ́ra, ó lè mú kí wọ́n wá sídìí omi ìyè tí Jèhófà ń mú kí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó nísinsìnyí. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a sọ fún gbogbo ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ pé, “Máa bọ̀!”—Ìṣí. 22:17.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́