Ẹ̀kọ́ 5
Kí Ni Ète Ọlọrun fún Ilẹ̀ Ayé?
Èé ṣe tí Jehofa fi dá ilẹ̀ ayé? (1, 2)
Èé ṣe tí ilẹ̀ ayé kò fi jẹ́ paradise nísinsìnyí? (3)
Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn búburú? (4)
Ní ọjọ́ iwájú, kí ni Jesu yóò ṣe fún àwọn aláìsàn? àwọn arúgbó? àwọn òkú? (5, 6)
Láti nípìn-ín nínú àwọn ìbùkún ọjọ́ iwájú, kí ni o ní láti ṣe? (7)
1. Jehofa dá ilẹ̀ ayé yìí kí àwọn ènìyàn lè gbádùn gbígbé lórí rẹ̀ títí láé. Ó fẹ́ kí àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ olódodo àti aláyọ̀ máa gbé orí ilẹ̀ ayé títí gbére. (Orin Dafidi 115:16; Isaiah 45:18) A kì yóò pa ilẹ̀ ayé run láé; yóò wà títí láé.—Orin Dafidi 104:5; Oniwasu 1:4.
2. Kí Ọlọrun tó dá ènìyàn, Ó yan apá kékeré kan lórí ilẹ̀ ayé, ó sì sọ ọ́ di paradise ẹlẹ́wà kan. Ó pè é ní ọgbà Edeni. Níhìn-ín ni ó fi ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, Adamu àti Efa, sí. Ọlọrun pète pé kí wọ́n bí àwọn ọmọ, kí wọ́n sì kún gbogbo ilẹ̀ ayé. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọn ì bá ti sọ gbogbo ilẹ̀ ayé pátá di paradise kan.—Genesisi 1:28; 2:8, 15.
3. Adamu àti Efa dẹ́ṣẹ̀ nípa mímọ̀ọ́nmọ̀ rú òfin Ọlọrun. Nítorí náà, Jehofa lé wọn jáde kúrò nínú ọgbà Edeni. Wọ́n pàdánù Paradise. (Genesisi 3:1-6, 23) Ṣùgbọ́n Jehofa kò tí ì gbàgbé ète rẹ̀ fún ilẹ̀ ayé yìí. Òún ṣèlérí láti sọ ọ́ di paradise kan, níbi tí ẹ̀dá ènìyàn yóò máa gbé títí láé. Báwo ni òun yóò ṣe ṣe èyí?—Orin Dafidi 37:29.
4. Kí ayé yìí tó lè di paradise kan, a gbọ́dọ̀ mú àwọn ènìyàn búburú kúrò. (Orin Dafidi 37:38) Èyí yóò ṣẹlẹ̀ ní Armagedoni, tí í ṣe ogun Ọlọrun láti fi òpin sí ìwà ibi. Tẹ̀ lé e, a óò fi Satani sẹ́wọ̀n 1,000 ọdún. Èyí túmọ̀ sí pé, kì yóò sí ẹni búburú kankan tí yóò ṣẹ́ kù láti ba ilẹ̀ ayé jẹ́. Àwọn ènìyàn Ọlọrun nìkan ni yóò là á já.—Ìṣípayá 16:14, 16; 20:1-3.
5. Lẹ́yìn náà, Jesu Kristi yóò ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba lórí ilẹ̀ ayé yìí, fún 1,000 ọdún. (Ìṣípayá 20:6) Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, òun yóò mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò nínú èrò inú àti ara wa. A óò di ẹ̀dá ènìyàn pípé, gan-an gẹ́gẹ́ bí Adamu àti Efa ti jẹ́ kí wọ́n tó dẹ́ṣẹ̀. Nígbà náà, kì yóò sí àìsàn, ọjọ́ ogbó, àti ikú mọ́. Àwọn ènìyàn tí ń ṣàìsàn yóò sàn, àwọn arúgbó yóò sì padà di ọ̀dọ́.—Jobu 33:25; Isaiah 33:24; Ìṣípayá 21:3, 4.
6. Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Jesu, àwọn olóòótọ́ ẹ̀dá ènìyàn yóò ṣiṣẹ́ láti sọ gbogbo ilẹ̀ ayé pátá di paradise kan. (Luku 23:43) Pẹ̀lúpẹ̀lù, a óò jí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn òkú dìde sí ìyè lórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣe 24:15) Bí wọ́n bá ṣe ohun tí Ọlọrun béèrè lọ́wọ́ wọn, wọn yóò máa gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn yóò pa run títí láé.—Johannu 5:28, 29; Ìṣípayá 20:11-15.
7. Nípa báyìí, ète Ọlọrun ní ìbẹ̀rẹ̀, fún ilẹ̀ ayé, yóò yọrí sí rere. Ìwọ yóò ha fẹ́ láti nípìn-ín nínú àwọn ìbùkún ọjọ́ iwájú wọ̀nyí bí? Bí o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, o ní láti máa bá a nìṣó láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jehofa, kí o sì ṣe àwọn ohun tí òún béèrè. Lílọ sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, tí ó wà ládùúgbò rẹ, yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.—Isaiah 11:9; Heberu 10:24, 25.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Wọ́n pàdánù Paradise
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Lẹ́yìn Armagedoni, a óò sọ ilẹ̀ ayé di paradise kan