Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .
Ibo Ni Párádísè Tí Bíbélì Sọ Máa Wà?
▪ Ọkùnrin kan tó ń kú lọ fi ìgboyà sọ ìgbàgbọ́ tó ní nínú Jésù, Jésù sì ṣèlérí fún un pé: “Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.” (Lúùkù 23:43) Ibo ni ọkùnrin yìí máa wà? Ṣé ọ̀run ni Párádísè náà máa wà ni tàbí orí ilẹ̀ ayé àbí ibòmíì níbi tí àwọn èèyàn ti ń retí ìdájọ́?
Inú Párádísè ni àwọn òbí wa àkọ́kọ́ gbé nígbà kan rí. Bíbélì sọ fún wa pé: “Jèhófà Ọlọ́run gbin ọgbà kan ní Édẹ́nì, síhà ìlà-oòrùn, ibẹ̀ ni ó sì fi ọkùnrin tí ó ti ṣẹ̀dá sí. Jèhófà Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti mú ọkùnrin náà, ó sì mú un tẹ̀ dó sínú ọgbà Édẹ́nì láti máa ro ó àti láti máa bójú tó o.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:8, 15) Nígbà tí wọ́n túmọ̀ àwọn ẹsẹ yìí sí èdè Gíríìkì, “ọgbà” ni wọ́n pè ní pa·raʹdei·sos, inú rẹ̀ sí ni ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà “paradise” tó túmọ̀ sí Párádísè ti wá.
Bí ó ti di dandan pé kí tọkọtaya kan mú ibùgbé rẹ̀ gbòòrò sí i nígbà tí àwọn ọmọ bá ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni a retí pé kí àwọn òbí wa àkọ́kọ́ mú Párádísè gbòòrò kọjá inú ọgbà Édẹ́nì nígbà tí àwọn ọmọ wọn bá ń pọ̀ sí i. Ọlọ́run sọ fún wọn pé: “Ẹ . . . kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:28.
Ohun tí Ẹlẹ́dàá wa ní lọ́kàn fún ẹ̀dá èèyàn ni pé, kí wọ́n máa gbé inú Párádísè orí ilẹ̀ ayé kí wọ́n sì bímọ síbẹ̀. Wọ́n á máa gbé títí láé nínú ọgbà ilẹ̀ ayé, níbi tí wọn kò ti nílò itẹ́ òkú. Ilẹ̀ ayé ni Ọlọ́run ní lọ́kàn pé kó jẹ́ ilé tí aráyé á máa gbé títí láé. Abájọ tí àwọn ohun tí Ọlọ́run dá sí ayé fi máa ń múnú wa dùn gan-an! Ọlọ́run dá wa láti máa gbé nínú ayé ẹlẹ́wà.
Ṣé ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn ti yí pa dà ni? Rárá o. Jèhófà fi dá wa lójú pé: “Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde yóò já sí. Kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tí mo ní inú dídùn sí.” (Aísáyà 55:11) Lẹ́yìn ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ọdún tí Ọlọ́run ti dá èèyàn, Bíbélì sọ nípa “Aṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé àti Olùṣẹ̀dá rẹ̀” pé, “kò wulẹ̀ dá a lásán” àmọ́ ó “ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀.” (Aísáyà 45:18) Ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn kò tíì yí pa dà. Ayé yìí ṣì máa di Párádísè.
Ó dùn mọ́ni láti mọ̀ pé, ọ̀pọ̀ ẹsẹ Bíbélì tó sọ nípa Párádísè ló máa ń ṣàlàyé ìwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé. Bí àpẹẹrẹ, àsọtẹ́lẹ̀ kan nínú ìwé Aísáyà sọ pé: “Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn.” (Aísáyà 65:21) Ibo ni wọ́n ń kọ́lé sí, ibo sì ni wọ́n máa ń gbin àjàrà sí? Ibo ni wọ́n ti ń jẹ èso? Orí ilẹ̀ ayé ni. Ìwé Òwe 2:21 ṣàlàyé rẹ̀ kedere pé: “Àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé.”
Jésù náà sọ̀rọ̀ nípa Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Lóòótọ́, ó tún ṣèlérí pé Párádísè ti ọ̀run máa wà, àmọ́ àwọn èèyàn díẹ̀ tá a yàn ló wà fún. (Lúùkù 12:32) Lẹ́yìn tí àwọn wọ̀nyí bá ti kú, Ọlọ́run á jí wọn dìde sí Párádísè ti ọ̀run, wọ́n á sì dara pọ̀ mọ́ Kristi láti máa ṣàkóso lé Párádísè ilẹ̀ ayé lórí. (Ìṣípayá 5:10; 14:1-3) Àwọn alájùmọ̀ ṣàkóso pẹ̀lú Jésù lọ́run yìí á rí i dájú pé àwọn ṣàkóso Párádísè ilẹ̀ ayé lọ́nà tó tọ́, wọ́n á sì bójú tó o lọ́nà tó máa bá ìlànà Ọlọ́run mu.
Jésù mọ̀ pé, èyí ni ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn nípa ilẹ̀ ayé. Ó ṣe tán, ọ̀run ló wà pẹ̀lú Baba rẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run dá àwọn nǹkan sínú ọgbà Édẹ́nì. Gbogbo àwọn tó bá ń lo ìgbàgbọ́ lóde òní ló máa láǹfààní láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ iwájú. (Jòhánù 3:16) Jésù ṣèlérí fún irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ pé: “Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.”—Lúùkù 23:43.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]
© FORGET Patrick/SAGAPHOTO.COM/Alamy