ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • fg ẹ̀kọ́ 5 àwọn ìbéèrè 1-5
  • Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn Tó Fi Dá Ayé Yìí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn Tó Fi Dá Ayé Yìí?
  • Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn fún Ilẹ̀ Ayé?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Kí Ni Ète Ọlọrun fún Ilẹ̀ Ayé?
    Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
  • Ibo Ni Párádísè Tí Bíbélì Sọ Máa Wà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • “Àá Pàdé ní Párádísè!”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
Àwọn Míì
Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
fg ẹ̀kọ́ 5 àwọn ìbéèrè 1-5

Ẹ̀KỌ́ 5

Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn Tó Fi Dá Ayé Yìí?

1. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá ayé yìí?

Ádámù àti Éfà nínú ọgbà Édẹ́nì àti nígbà Ọlọ́run lé wọn jáde nínú ọgbà náà

Jèhófà dá ayé yìí fún àwa èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Ilé wa ni. Ọlọ́run kò dá Ádámù àti Éfà sí ọ̀run, kò sì fẹ́ kí wọ́n bímọ síbẹ̀, nítorí ó ti dá àwọn áńgẹ́lì tẹ́lẹ̀ pé kí wọ́n máa gbé ní ọ̀run. (Jóòbù 38:​4, 7) Kàkà bẹ́ẹ̀, inú Párádísè kan tí à ń pè ní ọgbà Édẹ́nì ni Ọlọ́run fi ọkùnrin àkọ́kọ́ sí pé kó máa gbé. (Jẹ́nẹ́sísì 2:15-17) Jèhófà fún òun àti àtọmọdọ́mọ rẹ̀ láǹfààní láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé.​—Ka Sáàmù 37:29; 115:16.

Ní ìbẹ̀rẹ̀, ọgbà Édẹ́nì nìkan ló jẹ́ Párádísè. Ọlọ́run fẹ́ kí tọkọtaya àkọ́kọ́ náà bímọ, kí àwọn ọmọ wọn sì kún ayé. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, wọ́n á máa gbé ní gbogbo ayé, wọ́n á sì sọ ayé di Párádísè. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ayé yìí kò ní pa run láé. Ibẹ̀ ni àwa èèyàn á máa gbé títí láé.​—Ka Sáàmù 104:5.

Wo Fídíò náà Kí Ni Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Dá Ayé?

2. Kí nìdí tí ayé kò fi jẹ́ Párádísè báyìí?

Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, torí náà Jèhófà lé wọn jáde kúrò nínú ọgbà náà. Bí wọ́n ṣe pàdánù Párádísè nìyẹn, kò sí èèyàn kankan tó sì lè dá a pa dà. Bíbélì sọ pé: “A ti fi ayé lé ẹni burúkú lọ́wọ́.”​—Jóòbù 9:24.​—Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:23, 24.

Àwọn èèyàn ń kọ́lé nígbà tí ayé pa dà di Párádísè

Ṣé Jèhófà kò wá ní ṣe ohun tó ní lọ́kàn níbẹ̀rẹ̀ fún àwa èèyàn mọ́ ni? Rárá o! Òun ni agbára rẹ̀ ga jù lọ. Kò lè ṣe àṣetì. (Àìsáyà 45:18) Ó máa rí i dájú pé àwa èèyàn pa dà gbé nínú Párádísè.​—Ka Sáàmù 37:11, 34.

3. Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa dá Párádísè pa dà?

Ayé máa pa dà di Párádísè nígbà tí Jésù bá ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba tí Ọlọ́run fi jẹ. Nínú ogun kan tó ń jẹ́ Amágẹ́dọ́nì, Jésù àtàwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run máa pa gbogbo àwọn ọ̀tá Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà Jésù á ju Sátánì sí ẹ̀wọ̀n ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún. Ogun yìí ò ní pa àwọn èèyàn Ọlọ́run, torí pé Jésù máa tọ́ wọn sọ́nà á sì dáàbò bò wọ́n. Wọ́n máa wà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.​—Ka Ìfihàn 20:​1-3; 21:3, 4.

4. Ìgbà wo ni ìyà máa dópin?

Ìgbà wo ni Ọlọ́run máa mú ìwà ibi kúrò láyé? Jésù fún wa ní “àmì” kan tó máa jẹ́ ká mọ̀ pé òpin ti sún mọ́lé. Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé báyìí ń fi ẹ̀mí àwọn èèyàn sínú ewu, ó sì ń fi hàn pé “ìparí ètò àwọn nǹkan,” ìyẹn òpin ayé la wà báyìí.​—Ka Mátíù 24:3, 7-14, 21, 22.

Nígbà ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún tí Jésù máa fi ṣàkóso aráyé látọ̀run, ó máa fòpin sí ìyà. (Àìsáyà 9:6, 7; 11:9) Yàtọ̀ sí pé Jésù máa ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba, ó tún máa jẹ́ Àlùfáà Àgbà, á sì mú ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run kúrò. Lọ́nà yìí, Ọlọ́run máa lo Jésù láti mú àìsàn, ọjọ́ ogbó àti ikú kúrò pátápátá.​—Ka Àìsáyà 25:8; 33:24.

5. Àwọn wo ló máa gbé nínú Párádísè tó ń bọ̀?

Àwọn èèyàn ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba

Ní àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, wàá rí àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tí wọ́n sì fẹ́ mọ ohun tí wọ́n á ṣe kí inú Ọlọ́run lè dùn sí wọn

Àwọn èèyàn tó ṣègbọràn sí Ọlọ́run máa gbé nínú Párádísè. (1 Jòhánù 2:17) Jésù rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n wá àwọn ọlọ́kàn tútù, kí wọ́n sì kọ́ wọn ní ohun tí wọ́n máa ṣe láti rí ojú rere Ọlọ́run. Lóde òní, Jèhófà ń kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn jọ kí wọ́n lè gbé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé tó ń bọ̀. (Sefanáyà 2:3) Ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn èèyàn ń kọ́ bí wọ́n ṣe lè jẹ́ ọkọ àti bàbá rere, wọ́n sì ń kọ́ bí wọ́n á ṣe jẹ́ ìyàwó àti ìyá tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́. Àwọn ọmọ àtàwọn òbí máa ń jọ́sìn pa pọ̀, wọ́n sì ń kọ́ bí wọ́n á ṣe jàǹfààní látinú ìròyìn ayọ̀.​—Ka Míkà 4:1-4.

Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i, ka orí 3 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́