ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/99 ojú ìwé 7
  • Ǹjẹ́ A Mú Ọ Gbára Dì Láti Di Ẹni Tó Mọ̀ọ́kọ Mọ̀ọ́kà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ A Mú Ọ Gbára Dì Láti Di Ẹni Tó Mọ̀ọ́kọ Mọ̀ọ́kà?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
km 8/99 ojú ìwé 7

Ǹjẹ́ A Mú Ọ Gbára Dì Láti Di Ẹni Tó Mọ̀ọ́kọ Mọ̀ọ́kà?

1 Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń tẹ̀ ẹ́ mọ́ àwọn Kristẹni tòótọ́ lọ́kàn pé ó yẹ láti di ẹni “tí a mú gbára dì . . . fún iṣẹ́ rere gbogbo” nípasẹ̀ ìmọ̀ tó ń pèsè. (2 Tím. 3:17) Nípa báyìí, gbogbo ìránṣẹ́ Jèhófà la ń mú gbára dì dáadáa nípasẹ̀ àwọn ìpàdé. Àwọn àgbàlagbà tí kò lè kàwé tí wọn kò sì lè kọ̀wé ní èdè èyíkéyìí ti ń fi ìgbà gbogbo gbádùn àníyàn tí ètò àjọ Jèhófà ń ṣe nítorí wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, ìwé ìròyìn U.S. Catholic sọ nígbà kan pé “ẹ̀kọ́ àgbà tí Gbọ̀ngàn Ìjọba kọ̀ọ̀kan ń pèsè lóṣù kan ju èyí tí ọ̀pọ̀ jù lọ ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ń pèsè lọ́dún.”

2 Irú ẹ̀kọ́ àgbà bẹ́ẹ̀ máa ń ní ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà fún àwọn àgbàlagbà tí kò lè kàwé tí wọn kò sì lè kọ̀wé, ó sì tún máa ń ní ìtọ́ni kíkúnrẹ́rẹ́ láti inú Bíbélì tí a ṣètò láti gbin àwọn ìlànà ṣíṣekókó fún ìgbé ayé Kristẹni sí wọn nínú, èyí sì kan bó ṣe yẹ kí a máa tọ́jú àwọn ọmọ. Ṣùgbọ́n kí ló túmọ̀ sí láti mú gbára dì? Ìwé atúmọ̀ èdè kan túmọ̀ mú gbára dì pé ó jẹ́ ‘láti pèsè ohun tí ẹnì kan nílò fún un, fún ète kan tàbí fún iṣẹ́ kan.’

3 Lẹ́yìn tí Jí! December 8, 1978, sọ pé láàárín ọdún 1962 sí 1976, ní Nàìjíríà nìkan ṣoṣo, a kọ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti ọgọ́jọ ó dín mẹ́rin [15,156] èèyàn láti mọ̀ọ́kọ kí wọ́n sì mọ̀ọ́kà, ó wá fi kún un pé: ‘Púpọ̀ lára wọ́n wá láti àrọko—àwọn àgbẹ̀, ọdẹ, apẹja, àti àwọn ìyàwó ilé. Ìpinnu wọn láti ní ìmọ̀ Bíbélì kí wọ́n sì lè kọ́ àwọn ẹlòmíràn lẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ ló mú ìfẹ́ wọn sọjí láti kẹ́kọ̀ọ́.’ Ẹ wo ète wíwúnilórí tí wọ́n ní fún kíkẹ́kọ̀ọ́ láti mọ̀ọ́kọ kí wọ́n sì mọ̀ọ́kà! Irú ìpinnu yẹn kò ha ní dùn mọ́ Jèhófà nínú bí? Ohun ìṣiṣẹ́ wo la wá nílò fún ẹ̀kọ́ àgbà tó kẹ́sẹ járí nípasẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà wa?

4 Ohun Ìṣiṣẹ́ Ṣíṣekókó: Jèhófà sọ fún wòlíì Aísáyà pé: “Mú wàláà ńlá kan fún ara rẹ, kí o sì fi kálàmù ẹni kíkú [kọ̀wé] sára rẹ̀.” (Aísá. 8:1) Kò sí iyèméjì pé wòlíì náà gbára dì fún iṣẹ́ tí ń bẹ níwájú rẹ̀. Nítorí náà, nígbà tí ẹnì kan bá múra tán tó bá sì ti ya àkókò sọ́tọ̀, ó gbọ́dọ̀ ní àwọn ohun èlò tirẹ̀ fún kíkẹ́kọ̀ọ́: ìwé àkànlò, odindi ìwé àjákọ, nǹkan ìpàwérẹ́, àti pẹ́ńsù tàbí bírò fún àwọn iṣẹ́ kíláàsì. Ó dáa pé ká máa kó àwọn ohun èlò wọ̀nyí sínú àpò kan tí a yà sọ́tọ̀ ní pàtàkì fún ẹ̀kọ́ yìí.

5 Gan-an bí ìtìlẹyìn òbí ti ṣe pàtàkì fún ẹ̀kọ́ ìwé tó dáa nínú ọ̀ràn àwọn ọmọ, bẹ́ẹ̀ náà ni ìtìlẹyìn ìdílé ṣe pàtàkì tó nínú ọ̀ràn àwọn àgbàlagbà. Irú ìtìlẹyìn bẹ́ẹ̀ yóò kan níní ọ̀wọ̀ fún nǹkan èlò ilé ẹ̀kọ́ àgbàlagbà náà, ọkàn-ìfẹ́ nínú iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀, àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láti lè jẹ́ kí àgbàlagbà náà lè ṣe iṣẹ́ tí ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀ láṣeyọrí.

6 Ronú nípa ohun tí àgbẹ̀ kan yóò ṣe bó bá fẹ́ dá oko iṣu. Yóò kọ́kọ́ ṣán oko, á sì kọ ebè. Èyí túmọ̀ sí pé yóò ní ọkọ́ àti àdá. Yóò wá wá èbù iṣu tó dáa. Ǹjẹ́ àgbẹ̀ yẹn yóò ṣàṣeyọrí bí kò bá ní ohun ìṣiṣẹ́ ṣíṣekókó wọ̀nyẹn? Ó ṣeé ṣe kí nǹkan ṣòro fún un ní àwọn ọ̀nà kan, ṣùgbọ́n yóò túbọ̀ rọrùn fún àgbẹ̀ tó bá gbára dì láti fara dà á títí di ìgbà ìkórè. Gẹ́gẹ́ bó ṣe ń rí fún àgbẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe ń rí fún ẹnì kan tó ń kọ́ láti mọ̀ọ́kọ kó sì mọ̀ọ́kà—ó gbọ́dọ̀ ní àwọn ohun èlò ṣíṣekókó. Ẹ wo bí inú àgbẹ̀ kan ṣe máa ń dùn tó nígbà tó bá kórè dáadáa lẹ́yìn ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àṣekára! Bí o bá forúkọ sílẹ̀ ní kíláàsì mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà, ṣé o gbára dì láti di ẹni tó mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́