Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù August: A lè lo èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ìwé méjìlélọ́gbọ̀n tó tẹ̀ lé e yìí: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, àti Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? Àwọn ìwé pẹlẹbẹ Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, Our Problems—Who Will Help Us Solve Them?, àti Will There Ever Be a World Without War? ni a lè fi lọni nígbà tó bá yẹ. September: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. October: Gbogbo èdè—Àsansílẹ̀ owó fún Ilé Ìṣọ́ àti Jí! November: Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? tàbí Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun.
◼ Níbi gbogbo, ní onírúurú àkókò nínú ọdún, àwọn ọlidé ayé máa ń wà tí a máa ń tìtorí ẹ̀ fún àwọn ọmọ ní ìsinmi ní ilé ìwé, tí a sì máa ń fún àwọn òṣìṣẹ́ ní ìsinmi níbi iṣẹ́. Àǹfààní títayọ lọ́lá nìyí fún ìjọ láti nípìn-ín tí ó pọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Kí àwọn alàgbà wéwèé ṣáájú fún àkókò wọ̀nyí kí wọ́n sì sọ fún ìjọ ṣáájú nípa àwọn ètò tí wọ́n ń ṣe fún ìjẹ́rìí àjẹ́pọ̀ ní àwọn àkókò ọlidé.
◼ A ń kó àwọn fọ́ọ̀mù tí ó tó láti lò ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2000 ránṣẹ́ sí ìjọ kọ̀ọ̀kan. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fọgbọ́n lo àwọn fọ́ọ̀mù wọ̀nyí. Ète tí a torí rẹ̀ ṣe wọ́n nìkan ni kí ẹ lò wọ́n fún.
◼ Ìjọ kọ̀ọ̀kan yóò rí fọ́ọ̀mù Literature Inventory (S-18) mẹ́ta gbà. Kí akọ̀wé ìjọ rí ìránṣẹ́ tí ń bójú tó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù August kí wọ́n sì dá ọjọ́ tí wọn yóò ṣe ìṣírò ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó wà nínú ìjọ ní ìparí oṣù náà. Wọ́n gbọ́dọ̀ ka iye àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó wà lọ́wọ́ ní ti gidi kí wọ́n sì kọ àròpọ̀ rẹ̀ sórí fọ́ọ̀mù Literature Inventory. Àròpọ̀ iye ìwé ìròyìn tí ó wà lọ́wọ́ ni a lè mọ̀ láti ọ̀dọ̀ ìránṣẹ́ tí ń bójú tó ìwé ìròyìn. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi ẹ̀dà tí ó jẹ́ ojúlówó ránṣẹ́ sí Society, ó pẹ́ tán ní September 6. Ẹ tọ́jú ẹ̀dà kejì sínú fáìlì yín. Ẹ lè lo ẹ̀dà kẹta gẹ́gẹ́ bí èyí tí ẹ óò kọ́kọ́ kọ nǹkan sí. Kí akọ̀wé bójú tó ìṣírò náà, kí alábòójútó olùṣalága sì ṣàyẹ̀wò fọ́ọ̀mù tí a ti kọ ọ̀rọ̀ kún náà. Akọ̀wé àti alábòójútó olùṣalága ni kó fọwọ́ sí fọ́ọ̀mù náà.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti August 18, 1999, sí August 31, 1999, Society yóò máa ṣe ìṣírò ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó wà lọ́wọ́ ní Bẹ́tẹ́lì Igieduma. Nítorí ìṣírò tí a fẹ́ ṣe yìí, a kò ní ṣiṣẹ́ lórí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ìjọ béèrè pé kí a fi ránṣẹ́. Bákan náà, a óò ti ilé ìgbàwé pa láti August 18 sí August 20, 1999, kò sì sí ẹni tí yóò lè gba ìwé ní àkókò yìí.
◼ Kásẹ́ẹ̀tì Fídíò Tuntun Tí Ó Wà:
Noah—He Walked With God —Gẹ̀ẹ́sì
Akéde: ₦800; aṣáájú ọ̀nà: ₦640.