ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/99 ojú ìwé 5-6
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
km 8/99 ojú ìwé 5-6

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run

Àtúnyẹ̀wò láìṣí-ìwé-wò fún àkópọ̀ ẹ̀kọ́ tí a kárí nínú àwọn iṣẹ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run fún àwọn ọ̀sẹ̀ May 3 sí August 23, 1999. Lo abala tákàdá ọ̀tọ̀ láti fi kọ ìdáhùn sí púpọ̀ nínú àwọn ìbéèrè náà, bí ó bá ti lè ṣeé ṣe fún ọ tó, ní ìwọ̀n àkókò tí a yàn.

[Àkíyèsí: Lákòókò àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀, Bíbélì nìkan ni a lè lò láti dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí. Àwọn ìtọ́kasí tí ó tẹ̀ lé àwọn ìbéèrè wà fún ìwádìí fúnra rẹ. Nọ́ńbà ojú ìwé àti ìpínrọ̀ lè má fara hàn nínú gbogbo àwọn ìtọ́ka tí a ṣe sí Ilé Ìṣọ́.]

Dáhùn Òtítọ́ tàbí Èké sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:

1. Kò dìgbà tí àwọn òbí bá fí ìlànà Bíbélì báni dọ́rẹ̀ẹ́ ká tó sọ pé wọ́n fòye bá àwọn ọmọ wọn lò. [fy-YR ojú ìwé 108 ìpínrọ̀ 14]

2. Ìwé Jẹ́nẹ́sísì inú Bíbélì ń ru ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà àti ìrètí nínú “irú-ọmọ” ìbùkún tí a ṣèlérí náà sókè. (Jẹ́n. 3:15) [w83-YR 7/15 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 11]ọ́.

3. Ẹ́kísódù kò fi bẹ́ẹ̀ ní ìtumọ̀ gidi ní ọ̀rúndún ogún yìí. [w83-YR 10/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 3]

4. Kò ṣeé ṣe fún àwọn tí wọ́n wà ní ipò òṣì paraku láti fi owó ṣètọrẹ láti gbé ire Ìjọba lárugẹ. [w97-YR 9/15 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 8]

5. Sísan àsanfidípò yíyẹ fún àwọn òbí àti àwọn òbí àgbà jẹ́ apá kan ìjọsìn wa sí Jèhófà. (1 Tím. 5:4) [w97-YR 9/1 ojú ìwé 4 ìpínrọ̀ 1 àti 2]ọ́.

6. Pípa Sábáàtì mọ́ jẹ́ àmì kan láàárín Jèhófà àti gbogbo orílẹ̀-èdè ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo rs-E ojú ìwé 345 ìpínrọ̀ 3.]

7. Nígbà tí ọmọ kan bá dàgbà tó láti bẹ̀rẹ̀ sí í dápinnu ṣe, ó ń tẹ́wọ́ gba ẹrù iṣẹ́ púpọ̀ sí i fún àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀, ní pàtàkì nínú òfin àtọ̀runwá. (Róòmù 14:12) [fy-YR ojú ìwé 134 ìpínrọ̀ 17]ọ́.

8. Mósè kọ ìwé Léfítíkù ní ọdún 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa. [w84-YR 2/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 2]

9. Ọ̀rọ̀ Jésù tí a kọ sílẹ̀ nínú Lúùkù 21:20, 21 ní ìmúṣẹ ní ọdún 66 Sànmánì Tiwa nígbà tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù lábẹ́ àṣẹ Ọ̀gágun Titus kógun kúrò ní Jerúsálẹ́mù. [w97-YR 4/1 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 3 àti 4]

10. Ẹ̀kọ́ Epicurus léwu fún àwọn Kristẹni nítorí pé ó gbé e ka ojú ìwòye aláìgbàgbọ́ tó ní, èyí tí a ṣàpèjúwe rẹ̀ ní 1 Kọ́ríńtì 15:32. [w97-YR 11/1 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 4]

Dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí:

11. Ẹ̀kọ́ wo ni a rí kọ́ nínú ìkàléèwọ̀ jíjẹ ọ̀rá tí a kọ sínú ìwé Léfítíkù 3:17? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w84-YR 2/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 3.]

12. Èé ṣe tí Jèhófà fi fàyè gba Sátánì Èṣù láti máa wà nìṣó? (Ẹ́kís. 9:15, 16) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w92-YR 3/15 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 14.]

13. Nígbà tí mẹ́ńbà kan nínú ìdílé bá ń ṣàìsàn líle koko, ọ̀nà wo ni ìdílé gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ tọ̀ láti lè gbé àwọn ohun àkọ́múṣe kalẹ̀? (Òwe 15:22) [fy-YR ojú ìwé 122 ìpínrọ̀ 14]

14. Ní ọ̀nà wo ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì fi jẹ́ “ìjọba àwọn àlùfáà”? (Ẹ́kís. 19:6) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w95-YR 7/1 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 8.]

15. Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín ojú tó “mú ọ̀nà kan” àti èyí tó “burú”? (Mát. 6:22, 23) [w97-YR 10/1 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 5]

16. Báwo ni a ṣe lè sọ pé Dáfídì rìn “pẹ̀lú ìwà títọ́ ọkàn-àyà àti pẹ̀lú ìdúróṣinṣin” nígbà tó ṣe ọ̀pọ̀ àṣìṣe? (1 Ọba 9:4) [w97-YR 5/1 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 2]

17. Àwọn àǹfààní òde òní wo ni ṣíṣe tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ‘bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́’ ṣàpẹẹrẹ rẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àgọ́ ìjọsìn? (Ẹ́kís. 39:32) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; w95-YR 12/15 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 9.]

18. Kí ni òkodoro òtítọ́ náà pé Jèhófà fi ara rẹ̀ hàn ní “èmi yóò jásí ohun tí èmi yóò jásí” túmọ̀ sí? (Ẹ́kís. 3:14) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w95-YR 3/1 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 6.]ẹ̀.

19. Ẹ̀kọ́ wo ni ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó kan Nádábù àti Ábíhù tí a kọ sínú Léfítíkù 10:1, 2 kọ́ wa? [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w84-YR 2/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 4.]

20. Lábẹ́ Òfin Mósè, èé ṣe tí bíbímọ fi ń sọ obìnrin kan di “aláìmọ́”? (Léf. 12:2, 5) [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w84-YR 2/15 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 6.]

21. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ìwòsàn oníṣẹ́ ìyanu fún ìdánìkanwà, òbí anìkàntọ́mọ kan lè fara dà á pẹ̀lú okun tí _________________________ ń pèsè, èyí tí a ń rí nípasẹ̀ títẹpẹlẹ mọ́ _________________________. (1 Tím. 5:5) [fy-YR ojú ìwé 111 ìpínrọ̀ 21]

22. Ohun ìbànújẹ́ tó ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé ẹnì kan lè jẹ́ nítorí _________________________ tàbí nítorí _________________________ ti àwa fúnra wa. [w97-YR 5/15 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 7]

23. Ìwé Ẹ́kísódù fi Jèhófà hàn gẹ́gẹ́ bí _________________________ àti _________________________ àti _________________________ títóbi. [w83-YR 10/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 10 sí 12.]

24. Ní pàtàkì, bí a ṣe ń hùwà ní _________________________ọ̀kọ̀ ni ó ń fi irú ẹni tí a jẹ́ hàn, kì í ṣe bí a ṣe ń hùwà ní _________________________. [w97-YR 10/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 4]

25. Bí àwọn àjọ̀dún ìkórè bá ní ìsopọ̀ pẹ̀lú _________________________ọ̀rìṣà tàbí _________________________, ojúlówó Kristẹni lè yẹra fún mímú inú bí Jèhófà nípa kíkọ _________________________ pẹ̀lú irú ìjọsìn bẹ́ẹ̀ tí a ti sọ dẹ̀gbin. [w97-YR 9/15 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 6]

Mú ìdáhùn tó tọ̀nà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tó tẹ̀ lé e yìí:

26. Ìsìnrú “irínwó ọdún” àwọn irú-ọmọ Ábúráhámù bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Íṣímáẹ́lì ń fi Ísákì rẹ́rìn-ín ní (1943; 1919; 1913) ṣááju Sànmánì Tiwa, ó sì dópin pẹ̀lú ìdásílẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní oko ẹrú Íjíbítì ní (1543; 1519; 1513) ṣááju Sànmánì Tiwa. (Jẹ́n. 15:13) [w83-YR 7/15 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 14 àti 15]

27. Yálà ìdílé kan kẹ́sẹ járí nínú kíkojú àmódi líle koko tàbí kò kẹ́sẹ járí, sinmi lórí (ìfọ̀kànbalẹ̀ nípa owó níná; ìṣarasíhùwà; ètò ìbánigbófò) tí àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ ní. (Òwe 17:22) [fy-YR ojú ìwé 120 ìpínrọ̀ 10]

28. Ẹni tí ó sọ nínú ọkàn rẹ̀ pé “Jèhófà kò sí” ni a pè ní “òpònú” nítorí pé ẹni yẹn jẹ́ (aláìní ìwà rere; ẹni tí kò kàwé; aláìlágbára láti ronú). (Sm. 14:1) [w97-YR 10/1 ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 8]

29. Ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tí Ádámù àti Éfà pàdánù nígbà tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ ni (ìjẹ́pípé wọn; ipò ìbátan wọn pẹ̀lú Ọlọ́run; ọgbà tó jẹ́ ilé wọn), èyí tó jẹ́ àṣírí ayọ̀ wọn. [w97-YR 10/15 ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 2]

30. Léraléra, ìwé (Jẹ́nẹ́sísì; Ẹ́kísódù; Léfítíkù) sọ ohun tí a béèrè láti jẹ́ mímọ́. [w84-YR 2/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 1]

So àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó tẹ̀ lé e yìí mọ́ àwọn gbólóhùn tí a tò lẹ́sẹẹsẹ sí ìsàlẹ̀ yìí:

Ẹ́kís. 5:2; Ẹ́kís. 21:29; Òwe 1:8; Gál. 5:20; Ják. 1:14, 15

31. Ẹnikẹ́ni tó bá sọ pé ohun jẹ́ Kristẹni tó sì ń hu ìwà ipá onírufùfù ìbínú léraléra, láìronú pìwà dà, tó tún ń ṣe àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ̀ léṣe ni a lè yọ lẹ́gbẹ́. [fy-YR ojú ìwé 150 ìpínrọ̀ 23]

32. Bí a ṣe ń hùwà ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú bí a ṣe ń ronú. [fy-YR ojú ìwé 148 ìpínrọ̀ 18]

33. Jèhófà Ọlọ́run tẹ́ gbogbo àwọn tó fi àyà gbàǹgbà kọ̀ láti mọyì ipò jíjẹ́ Ọlọ́run rẹ̀ lógo.Ẹ́kís. 5:2] [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w92-YR 12/15 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 18.]

34. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì yan olórí ẹrù iṣẹ́ ti fífún àwọn ọmọ ní ìtọ́ni fún bàbá, ìyá pẹ̀lú ní ipa pàtàkì láti kó. [fy-YR ojú ìwé 133 ìpínrọ̀ 12]

35. Òfin kò fàyè gba àìbìkítà gẹ́gẹ́ bí ìdí fún fífi àánú hàn síni nígbà tí a bá pa ẹni kan. [Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w95-YR 11/15 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 5.]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́