ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 10
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Léfítíkù

      • Iná bọ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà, ó sì pa Nádábù àti Ábíhù (1-7)

      • Ìlànà tí àwọn àlùfáà yóò máa tẹ̀ lé nípa jíjẹ àti mímu (8-20)

Léfítíkù 10:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 6:23; 1Kr 24:2
  • +Ẹk 30:34, 35; Le 16:12
  • +Ẹk 30:9; Le 10:9; 16:1, 2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2004, ojú ìwé 22

Léfítíkù 10:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 16:35
  • +Nọ 26:61

Léfítíkù 10:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 19:22

Léfítíkù 10:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 6:18

Léfítíkù 10:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 21:10

Léfítíkù 10:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 28:41; Le 8:12; 21:11, 12

Léfítíkù 10:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 44:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2014, ojú ìwé 17

    12/1/2004, ojú ìwé 21-22

    5/15/2004, ojú ìwé 22

Léfítíkù 10:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 44:23

Léfítíkù 10:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 33:10; 2Kr 17:8, 9; Ne 8:7, 8; Mal 2:7

Léfítíkù 10:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 6:14, 16
  • +Le 21:22

Léfítíkù 10:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 6:26; Nọ 18:10

Léfítíkù 10:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 22:13; Nọ 18:11
  • +Ẹk 29:26-28; Le 7:31, 34; 9:21

Léfítíkù 10:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 9:13

Léfítíkù 10:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 9:3, 15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/2011, ojú ìwé 12

Léfítíkù 10:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 6:25, 26; Isk 44:29

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/2011, ojú ìwé 12

Léfítíkù 10:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 6:29, 30

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/2011, ojú ìwé 12

Léfítíkù 10:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 9:8, 12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/2011, ojú ìwé 12

Léfítíkù 10:20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/2011, ojú ìwé 12

Àwọn míì

Léf. 10:1Ẹk 6:23; 1Kr 24:2
Léf. 10:1Ẹk 30:34, 35; Le 16:12
Léf. 10:1Ẹk 30:9; Le 10:9; 16:1, 2
Léf. 10:2Nọ 16:35
Léf. 10:2Nọ 26:61
Léf. 10:3Ẹk 19:22
Léf. 10:4Ẹk 6:18
Léf. 10:6Le 21:10
Léf. 10:7Ẹk 28:41; Le 8:12; 21:11, 12
Léf. 10:9Isk 44:21
Léf. 10:10Isk 44:23
Léf. 10:11Di 33:10; 2Kr 17:8, 9; Ne 8:7, 8; Mal 2:7
Léf. 10:12Le 6:14, 16
Léf. 10:12Le 21:22
Léf. 10:13Le 6:26; Nọ 18:10
Léf. 10:14Le 22:13; Nọ 18:11
Léf. 10:14Ẹk 29:26-28; Le 7:31, 34; 9:21
Léf. 10:151Kọ 9:13
Léf. 10:16Le 9:3, 15
Léf. 10:17Le 6:25, 26; Isk 44:29
Léf. 10:18Le 6:29, 30
Léf. 10:19Le 9:8, 12
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Léfítíkù 10:1-20

Léfítíkù

10 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Áárónì, Nádábù àti Ábíhù,+ mú ìkóná wọn, kálukú fi iná sínú rẹ̀, wọ́n sì fi tùràrí+ sórí rẹ̀. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í rú ẹbọ tí kò yẹ+ níwájú Jèhófà, ohun tí kò pa láṣẹ fún wọn. 2 Ni iná bá bọ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà, ó sì jó wọn run,+ wọ́n sì kú níwájú Jèhófà.+ 3 Mósè wá sọ fún Áárónì pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Àwọn tó sún mọ́ mi+ yóò mọ̀ pé mímọ́ ni mí, wọ́n á sì yìn mí lógo níṣojú gbogbo èèyàn.’” Áárónì sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.

4 Mósè bá pe Míṣáẹ́lì àti Élísáfánì, àwọn ọmọ Úsíélì,+ arákùnrin bàbá Áárónì, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ wá gbé àwọn arákùnrin yín kúrò níwájú ibi mímọ́ lọ síbì kan lẹ́yìn ibùdó.” 5 Torí náà, wọ́n wá, wọ́n sì gbé àwọn ọkùnrin náà lọ sí ibì kan lẹ́yìn ibùdó pẹ̀lú aṣọ ara wọn, bí Mósè ṣe sọ fún wọn.

6 Mósè wá sọ fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù, Élíásárì àti Ítámárì, pé: “Ẹ má fi irun orí yín sílẹ̀ láìtọ́jú, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ ya aṣọ yín,+ kí ẹ má bàa kú, kí Ọlọ́run má bàa bínú sí gbogbo àpéjọ yìí. Àwọn arákùnrin yín ní gbogbo ilé Ísírẹ́lì máa sunkún torí àwọn tí Jèhófà fi iná pa. 7 Ẹ ò gbọ́dọ̀ jáde ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ máa kú, torí òróró àfiyanni Jèhófà wà lórí yín.”+ Torí náà, wọ́n ṣe ohun tí Mósè sọ.

8 Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún Áárónì pé: 9 “Ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ò gbọ́dọ̀ mu wáìnì tàbí àwọn ohun mímu míì tó ní ọtí nígbà tí ẹ bá wá sínú àgọ́ ìpàdé,+ kí ẹ má bàa kú. Àṣẹ tí ìran yín á máa pa mọ́ títí láé ni. 10 Èyí máa fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun mímọ́ àti ohun tó di aláìmọ́ àti sáàárín ohun tí kò mọ́ àti ohun tó mọ́,+ 11 yóò sì tún kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní gbogbo ìlànà tí Jèhófà sọ fún wọn nípasẹ̀ Mósè.”+

12 Mósè wá sọ fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù, Élíásárì àti Ítámárì pé: “Ẹ kó ọrẹ ọkà tó ṣẹ́ kù látinú àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, kí ẹ fi ṣe búrẹ́dì aláìwú, kí ẹ sì jẹ ẹ́ nítòsí pẹpẹ,+ torí pé ohun mímọ́ jù lọ ni.+ 13 Kí ẹ jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́,+ torí ìpín tìrẹ àti ìpín àwọn ọmọ rẹ látinú àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà ni, torí pé àṣẹ tí mo gbà nìyí. 14 Kí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ lọ́kùnrin àti lóbìnrin+ tún jẹ igẹ̀ ọrẹ fífì àti ẹsẹ̀ ìpín mímọ́+ ní ibi tó mọ́, torí mo ti fi ṣe ìpín rẹ àti ti àwọn ọmọ rẹ látinú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 15 Kí wọ́n mú ẹsẹ̀ ìpín mímọ́ wá pẹ̀lú igẹ̀ ọrẹ fífì àti àwọn ọrẹ ọ̀rá tí wọ́n fi iná sun, kí wọ́n lè fi ọrẹ fífì náà síwá-sẹ́yìn níwájú Jèhófà; yóò jẹ́ ìpín rẹ àti ti àwọn ọmọ+ rẹ títí lọ, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ.”

16 Mósè fara balẹ̀ wá ewúrẹ́ tí wọ́n fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ náà, ó sì rí i pé wọ́n ti sun ún. Ni inú bá bí i sí Élíásárì àti Ítámárì, àwọn ọmọ Áárónì yòókù, ó sì sọ pé: 17 “Kí ló dé tí ẹ ò jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà ní ibi mímọ́,+ ṣebí ohun mímọ́ jù lọ ni, ó sì ti fún yín, kí ẹ lè ru ẹ̀bi àpéjọ náà, kí ẹ sì ṣe ètùtù fún wọn níwájú Jèhófà? 18 Ẹ wò ó! Ẹ ò tíì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sínú ibi mímọ́.+ Ó yẹ kí ẹ ti jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́, bí àṣẹ tí mo gbà.” 19 Áárónì sọ fún Mósè pé: “Wò ó! Wọ́n mú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti ẹbọ sísun wọn wá síwájú Jèhófà+ lónìí, síbẹ̀ nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ sí mi. Ká ní mo jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ lónìí ni, ṣé inú Jèhófà máa dùn?” 20 Nígbà tí Mósè gbọ́ ọ̀rọ̀ yẹn, ó tẹ́ ẹ lọ́rùn.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́