-
Ẹ́kísódù 29:26-28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 “Kí o gé igẹ̀ àgbò àfiyanni náà,+ tí o fi rúbọ torí Áárónì, kí o sì fì í síwá-sẹ́yìn bí ọrẹ fífì níwájú Jèhófà, yóò sì di ìpín tìrẹ. 27 Kí o ya igẹ̀ ọrẹ fífì náà sí mímọ́, pẹ̀lú ẹsẹ̀ ìpín mímọ́ tí o fì, èyí tí o gé lára àgbò àfiyanni náà,+ látinú ohun tí o fi rúbọ torí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀. 28 Yóò di ti Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí ó jẹ́ àṣẹ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á máa pa mọ́ títí láé, torí ìpín mímọ́ ló jẹ́, yóò sì di ìpín mímọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á máa fún wọn.+ Ìpín mímọ́ wọn fún Jèhófà ni, látinú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ wọn.+
-
-
Léfítíkù 7:34Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
34 Torí mo mú igẹ̀ ọrẹ fífì àti ẹsẹ̀ ìpín mímọ́ náà látinú àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, mo sì fún àlùfáà Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, kó jẹ́ ìlànà tó máa wà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ títí lọ.
-
-
Léfítíkù 9:21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Àmọ́ Áárónì fi àwọn igẹ̀ àti ẹsẹ̀ ọ̀tún síwá-sẹ́yìn bí ọrẹ fífì níwájú Jèhófà, bí Mósè ṣe pa á láṣẹ.+
-