-
2 Kíróníkà 17:8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Àwọn ọmọ Léfì wà pẹ̀lú wọn, àwọn ni: Ṣemáyà, Netanáyà, Sebadáyà, Ásáhélì, Ṣẹ́mírámótì, Jèhónátánì, Ádóníjà, Tóbíjà àti Tobu-ádóníjà, àwọn àlùfáà+ tó wà pẹ̀lú wọn ni Élíṣámà àti Jèhórámù. 9 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ni ní Júdà, wọ́n mú ìwé Òfin Jèhófà dání,+ wọ́n sì lọ yí ká gbogbo àwọn ìlú Júdà, wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn.
-
-
Nehemáyà 8:7, 8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Jéṣúà, Bánì, Ṣerebáyà,+ Jámínì, Ákúbù, Ṣábétáì, Hodáyà, Maaseáyà, Kélítà, Asaráyà, Jósábádì,+ Hánánì àti Pẹláyà, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì, ń ṣàlàyé Òfin náà fún àwọn èèyàn náà,+ orí ìdúró sì ni àwọn èèyàn náà wà. 8 Wọ́n ń ka ìwé náà sókè nìṣó látinú Òfin Ọlọ́run tòótọ́, wọ́n ń ṣàlàyé rẹ̀ lọ́nà tó ṣe kedere, wọ́n sì ń túmọ̀ rẹ̀; torí náà, wọ́n jẹ́ kí àwọn èèyàn náà lóye ohun tí wọ́n kà.+
-