ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • fy orí 9 ojú ìwé 103-115
  • Àwọn Ìdílé Olóbìí Kan Lè Kẹ́sẹ Járí!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìdílé Olóbìí Kan Lè Kẹ́sẹ Járí!
  • Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • MÍMỌ IṢẸ́ ILÉ DUNJÚ
  • ÌṢÒRO GBÍGBỌ́ BÙKÁTÀ
  • TA NÍ Ń BÓJÚ TÓNI?
  • PÍPÈSÈ ÌBÁWÍ
  • ṢÍṢẸ́GUN ÌDÁNÌKANWÀ
  • BÍ ÀWỌN ẸLÒMÍRÀN ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́
  • Máa Fi Ìgbatẹnirò Hàn fún Àwọn Òbí Tó Ń Dá Tọ́mọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ìṣòro Tí Àwọn Òbí Tó Ń Dá Tọ́mọ Ń Kojú Kò Níye
    Jí!—2002
  • Òbí Tó Ń Dá Tọ́mọ, àmọ́ Tí Kò Dá Wà
    Jí!—2002
  • Ṣiṣẹ́ Kára Fún Ìgbàlà Agbo-Ilé Rẹ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Àwọn Míì
Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
fy orí 9 ojú ìwé 103-115

ORÍ KẸSÀN-ÁN

Àwọn Ìdílé Olóbìí Kan Lè Kẹ́sẹ Járí!

1-3. Kí ló ti dá kún bí iye ìdílé olóbìí kan ṣe ń pọ̀ sí i, báwo ni ó sì ṣe ń nípa lórí àwọn tó kàn?

ATI pe ìdílé olóbìí kan ní “oríṣi ìdílé tí ń yára gbilẹ̀ jù lọ” ní United States. Bákan náà ló ṣe rí ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè míràn. Àìláfiwé iye ìkọ̀sílẹ̀, ifilésílẹ̀, ìyapa, àti ìbímọ àlè ti nípa kíkàmàmà lórí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ òbí àti ọmọ.

2 Òbí anìkàntọ́mọ kan kọ̀wé pé: “Mo jẹ́ opó, ẹni ọdún 28, tí ó lọ́mọ méjì. Ó ń bà mí lọ́kàn jẹ́ gan-an nítorí n kò fẹ́ẹ́ tọ́ àwọn ọmọ mi láìsí bàbá. Kò jọ pé ẹnì kankan bìkítà nípa mi. Àwọn ọmọ mi ń rí mi tí mo ń sunkún lọ́pọ̀ ìgbà, ó sì ń nípa lórí wọn.” Yàtọ̀ sí kíkojú ìmọ̀lára ìbínú, ẹ̀bi, àti ìdánìkanwà, ọ̀pọ̀ jù lọ òbí anìkàntọ́mọ ń dojú kọ ìpèníjà ṣíṣiṣẹ́ lẹ́yìn òde ilé àti bíbójú tó àwọn iṣẹ́ ilé. Ọ̀kan sọ pé: “Jíjẹ́ òbí anìkàntọ́mọ dà bíi jíjẹ́ eléré àsọhán. Lẹ́yìn dídánra wò fóṣù mẹ́fà, o ti lè sọ bọ́ọ̀lù mẹ́rin lásọhán lẹ́ẹ̀kan. Gẹ́lẹ́ tí o lè ṣe ìyẹn, ni ẹnì kan bá tún ju bọ́ọ̀lù míràn sí ọ!”

3 Àwọn ọ̀dọ́langba nínú ìdílé olóbìí kan sábà máa ń ní wàhálà tiwọn. Wọ́n lè ní láti kojú ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ bí òbí kan bá fi ilé sílẹ̀ tàbí kú lójijì. Ó jọ pé níní òbí kan ṣoṣo máa ń ní ipa búburú gidigidi lórí ọ̀pọ̀ èwe.

4. Báwo ni a ṣe mọ̀ pé Jehofa bìkítà nípa àwọn ìdílé olóbìí kan?

4 Àwọn ìdílé olóbìí kan ń bẹ ní àkókò tí a kọ Bibeli. Ìwé Mímọ́ mẹ́nu ba “aláìníbaba” àti “opó” níye ìgbà. (Eksodu 22:22; Deuteronomi 24:​19-21; Jobu 31:​16-22) Jehofa Ọlọrun kò dágunlá sí ìṣòro wọn. Onipsalmu pe Ọlọrun ní “baba àwọn aláìníbaba àti onídàájọ́ àwọn opó.” (Orin Dafidi 68:5) Ó dájú pé Jehofa bìkítà lọ́nà kan náà fún àwọn ìdílé olóbìí kan lónìí! Ní ti gidi, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pèsè àwọn ìlànà tí ó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kẹ́sẹ járí.

MÍMỌ IṢẸ́ ILÉ DUNJÚ

5. Ìṣòro wo ni àwọn òbí anìkàntọ́mọ ní láti dojú kọ níbẹ̀rẹ̀?

5 Ronú nípa ẹrù iṣẹ́ bíbójú tó ilé. Obìnrin kan tí ó ṣèkọ̀sílẹ̀ jẹ́wọ́ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìwọ́ ń dàníyàn pé kí o ní ọkọ nílé, fún àpẹẹrẹ, bí ìgbà tí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ bá ń pariwo, tí o kò sì mọ ibi tí ó ti ń wá.” Ògìdìgbó iṣẹ́ ilé tí àwọn ọkùnrin tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèkọ̀sílẹ̀ tàbí tí aya wọ́n kú ní láti máa ṣe lè kà wọ́n láyà bákan náà. Ní ti àwọn ọmọ, àìlétò nínú ilé ń fi kún ìmọ̀lára àìdúródéédéé àti àìláàbò.

6, 7. (a) Àpẹẹrẹ rere wo ni “obìnrin oníwà rere” inú ìwé Owe fi lélẹ̀? (b) Báwo ni jíjẹ́ aláápọn nídìí ẹrù iṣẹ́ ilé ṣe ń ṣèrànwọ́ nínú agbo ilé olóbìí kan?

6 Ọgbọ́n wo la lè dá? Kíyè sí àpẹẹrẹ “obìnrin oníwà rere” tí a ṣàpèjúwe nínú Owe 31:​10-31. Iṣẹ́ ìdáwọ́lé rẹ̀ gbòòrò gan-an​—rírà, títà, rírán, sísè, dídókòwò lórí dúkìá, ṣíṣọ̀gbìn, àti bíbójú tó òwò. Ọgbọ́n wo ló ń dá? Aláápọn tí ń ṣiṣẹ́ dòru, tí ó sì ń jí bẹ̀rẹ̀ ìgbòkègbodò rẹ̀ ní àfẹ̀mọ́jú ni. Ó wà létòlétò pẹ̀lú, ó ń pínṣẹ́ fúnni ṣe nígbà tí òun náà sì ń fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣe àwọn mìíràn. Abájọ tí a fi yìn ín!

7 Bí o bá jẹ́ òbí anìkàntọ́mọ, jẹ́ ẹni tí àwọn ẹrù iṣẹ́ ilé ń jẹ lọ́kàn. Ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, nítorí èyí ń fi kún ayọ̀ àwọn ọmọ rẹ púpọ̀púpọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, ìwéwèé àti ìṣètò yíyẹ ṣe kókó. Bibeli wí pé: “Ìrònú aláápọn, sí kìkì ọ̀pọ̀ ni.” (Owe 21:5) Bàbá anìkàntọ́mọ kan jẹ́wọ́ pé: “N kì í ronú nípa oúnjẹ títí dìgbà tí ebí bá ń pa mí.” Ṣùgbọ́n oúnjẹ tí a wéwèé fún máa ń ṣara lóore, a sì ń gbádùn rẹ̀ ju èyí tí a fìkánjú sè lọ. O tún lè kọ́ láti lo ọwọ́ rẹ láti ṣe àwọn nǹkan tuntun. Nípa gbígbàmọ̀ràn àwọn ọ̀rẹ́ onírìírí, àwọn ìwé bí-a-ti-í-ṣe-é, àti àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ aṣèrànwọ́, àwọn ìyá anìkàntọ́mọ kan ti lè kun ilé, fa omi sílé, kí wọ́n sì ṣàtúnṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ lára ọkọ̀.

8. Báwo ni àwọn ọmọ òbí anìkàntọ́mọ ṣe lè ṣèrànwọ́ nínú ilé?

8 Ǹjẹ́ ó tọ́ láti béèrè ìrànwọ́ àwọn ọmọ? Ìyá anìkàntọ́mọ kan ronú pé: “Ìwọ yóò fẹ́ láti dí àlàfo òbí kan tó kù nípa mímú nǹkan rọrùn fún àwọn ọmọ.” Èyí lè yéni, ṣùgbọ́n ó lè má fìgbà gbogbo ṣe ọmọ náà láǹfààní. A máa ń yanṣẹ́ yíyẹ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ fún àwọn èwe olùbẹ̀rù Ọlọrun ní àkókò tí a kọ Bibeli. (Genesisi 37:2; Orin Solomoni 1:6) Nítorí náà, bí o kò tilẹ̀ fẹ́ láti dẹ́rù pa àwọn ọmọ rẹ, yóò bọ́gbọ́n mu fún ọ láti yanṣẹ́ bíi fífọ àwo àti títún iyàrá wọn ṣe fún wọn. Ẹ kò ṣe jọ ṣe iṣẹ́ ilé díẹ̀? Èyí lè gbádùn mọ́ni gan-an ni.

ÌṢÒRO GBÍGBỌ́ BÙKÁTÀ

9. Èé ṣe tí àwọn ìyá anìkàntọ́mọ fi ń ní ìṣòro ìṣúnná owó?

9 Awọ ìṣúnná owó kò kájú ìlù fún ọ̀pọ̀ jù lọ òbí anìkàntọ́mọ, nǹkan sì sábà máa ń le koko gan-an fún àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ ìyá tí kò ṣègbéyàwó.a Ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ìpèsè afẹ́nifẹ́re bá wà, ó lè bọ́gbọ́n mu fún wọn láti gbà á, ó kéré tán, títí wọn yóò fi rí iṣẹ́. Bibeli gba àwọn Kristian láyè láti gba irú ìpèsè bẹ́ẹ̀ nígbà tí ó bá pọn dandan. (Romu 13:​1, 6) Àwọn opó àti àwọn obìnrin tí ó ṣèkọ̀sílẹ̀ ń kojú ìṣòro jíjọra. Ọ̀pọ̀ tí ó di dandan fún láti tún padà síbi iṣẹ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún àbójútó ilé wulẹ̀ lè rí iṣẹ́ olówó pọ́ọ́kú lásán. Àwọn kan ń tiraka láti mú kí nǹkan túbọ̀ rọ̀ṣọ̀mù fún wọn nípa lílọ́wọ́ nínú àwọn ìṣètò ẹ̀kọ́ṣẹ́ tàbí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ onígbà kúkúrú.

10. Báwo ni ìyá anìkàntọ́mọ kan ṣe lè ṣàlàyé ìdí tí òún fi gbọ́dọ̀ máa ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ fún àwọn ọmọ rẹ̀?

10 Bí àwọn ọmọ rẹ kò bá láyọ̀ nígbà tí o ń wáṣẹ́, má ṣe jẹ́ kí ó yà ọ́ lẹ́nu, má sì ṣe dá ara rẹ lẹ́bi. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣàlàyé ìdí tí o fi gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ fún wọn, kí o sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye pé ìfẹ́ Jehofa ni pé kí o pèsè fún wọn. (1 Timoteu 5:8) Kì í pẹ́ tí ó fi ń mọ́ ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọ lára. Bí ó ti wù kí ó rí, gbìyànjú láti lo àkókò pẹ̀lú wọn bí o bá ṣe ráyè tó. Irú àfiyèsí onífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú lè sọ ipa tí àìtó owó èyíkéyìí ń ní lórí ìdílé di yẹpẹrẹ.​—Owe 15:​16, 17.

TA NÍ Ń BÓJÚ TÓNI?

11, 12. Àwọn ààlà wo ni àwọn òbí anìkàntọ́mọ gbọ́dọ̀ pa mọ́, báwo ni wọ́n sì ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

11 Lọ́nà ti ẹ̀dá, àwọn òbí anìkàntọ́mọ lè sún mọ́ àwọn ọmọ wọn pẹ́kípẹ́kí, síbẹ̀, ó gba ìṣọ́ra láti ka àwọn ààlà tí Ọlọrun fi lélẹ̀ láàárín òbí àti ọmọ sí. Bí àpẹẹrẹ, ìṣòro ńlá lè yọjú, bí ìyá anìkàntọ́mọ kan bá retí kí ọmọkùnrin rẹ̀ máa kó ipa baálé ilé, tàbí tí ó fi ọmọbìnrin rẹ̀ ṣe agbọ̀ràndùn, tí ó ń di ẹrù ìnira ìṣòro ọ̀ràn ara ẹni rẹ̀ lé ọmọdébìnrin náà. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ kò tọ́, ó ń máyé súni, ó sì ṣeé ṣe kí ó máa da ọmọdé lọ́kàn rú.

12 Fi dá àwọn ọmọ rẹ lójú pé ìwọ, gẹ́gẹ́ bí òbí, ni yóò bójú tó wọn​—kì í ṣe àwọn ni yóò bójú tó ọ. (Fi wé 2 Korinti 12:14.) O lè nílò ìmọ̀ràn tàbí ìtìlẹ́yìn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Wá a sọ́dọ̀ àwọn Kristian alàgbà tàbí bóyá sọ́dọ̀ àwọn obìnrin Kristian adàgbàdénú, kì í ṣe sọ́dọ̀ àwọn ọmọ rẹ kéékèèké.​—Titu 2:3.

PÍPÈSÈ ÌBÁWÍ

13. Ìṣòro wo ni ìyá anìkàntọ́mọ kan lè dojú kọ ní ti ìbáwí?

13 Ó rọrùn láti ka ọkùnrin sí olùbániwí aláìgbagbẹ̀rẹ́ ju obìnrin lọ. Ìyá anìkàntọ́mọ kan sọ pé: “Àwọn ọmọkùnrin mi ní ìrísí àti ohùn géńdé ọkùnrin. Nígbà míràn, ó rọrùn láti fara hàn bí aláìnípinnu tàbí aláìlágbára, ní ìfiwéra.” Síwájú sí i, o ṣì lè máa ṣọ̀fọ̀ àyànfẹ́ alábàáṣègbéyàwó rẹ, tàbí o lè máa nímọ̀lára ẹ̀bi tàbí ìbínú nípa ìfọ́yángá ìgbéyàwó rẹ. Bí ẹ bá ń pín àbójútó ọmọ ṣe, ẹ̀rù lè máa bà ọ́ pé ọmọ rẹ fara mọ́ wíwà pẹ̀lú alábàáṣègbéyàwó rẹ àtijọ́. Irú ipò bẹ́ẹ̀ lè mú kí ó ṣòro láti pèsè ìbáwí wíwà déédéé.

14. Báwo ni àwọn òbí anìkàntọ́mọ ṣe lè ní ojú ìwòye wíwà déédéé nípa ìbáwí?

14 Bibeli sọ pé “ọmọ tí a bá jọ̀wọ́ rẹ̀ fún ara rẹ̀, á dójú ti ìyá rẹ̀.” (Owe 29:15) Jehofa Ọlọrun ń tì ọ́ lẹ́yìn nínú ṣíṣe òfin ìdílé àti mímú wọn ṣẹ, nítorí náà, má fàyè gba ẹ̀bi, ìkárísọ, tàbí ìbẹ̀rù. (Owe 1:8) Má ṣe fi ìlànà Bibeli báni dọ́rẹ̀ẹ́. (Owe 13:24) Gbìyànjú láti jẹ́ afòyebánilò, aláìyẹhùn, àti adúróṣinṣin. Láìpẹ́, àwọn ọmọ yóò hùwà padà lọ́nà rere. Síbẹ̀, ìwọ yóò fẹ́ láti gba ti ìmọ̀lára àwọn ọmọ rẹ rò. Bàbá anìkàntọ́mọ kan sọ pé: “Mo ní láti fòye bá wọn wí nítorí ìmọ̀lára wọn lórí ikú ìyá wọn. Mo ń bá wọn sọ̀rọ̀ ní gbogbo àkókò tí ó ṣeé ṣe. A ń ní ‘àkókò ìfikùnlukùn’ nígbà tí a bá ń gbọ́únjẹ alẹ́. Nígbà yẹn ni wọ́n máa ń finú hàn mí ní ti gidi.”

15. Kí ni òbí kan tí ó ti ṣèkọ̀sílẹ̀ gbọ́dọ̀ yẹra fún nígbà tí ó bá ń sọ̀rọ̀ nípa alábàáṣègbéyàwó rẹ̀ àtijọ́?

15 Bí o bá ti ṣèkọ̀sílẹ̀, ire kan kò lè ti inú jíjin ọ̀wọ̀ fún alábàáṣègbéyàwó rẹ àtijọ́ lẹ́sẹ̀ jáde. Ìjiyàn gbígbóná janjan láàárín àwọn òbí ń ba àwọn ọmọ lọ́kàn jẹ́, yóò sì mú kí ọ̀wọ̀ wọn fún ẹ̀yin méjèèjì yìnrìn níkẹyìn. Nítorí náà, yẹra fún àwọn gbólóhùn wíwọni lára bíi: “Bàbá yín lẹ jọ!” Láburú yòówù kí alábàáṣègbéyàwó rẹ àtijọ́ ṣe fún ọ, òun ṣì ni òbí ọmọ rẹ tí ó nílò ìfẹ́, àfiyèsí, àti ìbáwí òbí méjèèjì.b

16. Àwọn ìṣètò tẹ̀mí wo ni a gbọ́dọ̀ máa ṣe déédéé gẹ́gẹ́ bí apákan ìbáwí nínú agbo ilé olóbìí kan?

16 Bí a ṣe jíròrò nínú àwọn orí ìṣáájú, ìbáwí ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti ìtọ́ni nínú, kì í wulẹ̀ ṣe ìjẹniníyà ṣáá. A lè yẹ ọ̀pọ̀ ìṣòro sílẹ̀ nípa níní ìṣètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tẹ̀mí tí ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. (Filippi 3:16) Pípésẹ̀ déédéé sí àwọn ìpàdé Kristian ṣe kókó. (Heberu 10:​24, 25) Bákan náà ni ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ìdílé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Lóòótọ́, kò rọrùn láti máa ṣe irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ déédéé. Ìyá olùfọkànsìn kan wí pé: “Lẹ́yìn iṣẹ́ òòjọ́, dandan ni kí o fẹ́ láti sinmi. Ṣùgbọ́n mo máa ń mú ìrònú mi gbara dì láti kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ọmọbìnrin mi, ní mímọ̀ pé ohun tí ó pọn dandan láti ṣe ni. Ó máa ń gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wa!”

17. Ẹ̀kọ́ wo ni a lè kọ́ nínú ìtọ́dàgbà àtàtà tí Timoteu, alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Paulu, ní?

17 Ní kedere, a dá Timoteu alábàáṣiṣẹ́pọ̀ aposteli Paulu lẹ́kọ̀ọ́, nínú ìlànà Bibeli, láti ọ̀dọ̀ ìyá àti ìyá rẹ̀ àgbà​—ó dájú pé kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ bàbá rẹ̀. Síbẹ̀, ẹ wo irú Kristian títayọ lọ́lá tí Timoteu dà! (Ìṣe 16:​1, 2; 2 Timoteu 1:5; 3:​14, 15) Lọ́nà kan náà, ìwọ́ lè retí ìyọrísí rere, bí o ti ń tiraka láti tọ́ àwọn ọmọ rẹ dàgbà “ninu ìbáwí ati ìlànà èrò-orí Jehofa.”​—Efesu 6:4.

ṢÍṢẸ́GUN ÌDÁNÌKANWÀ

18, 19. (a) Báwo ni òbí anìkàntọ́mọ ṣe lè nírìírí ìdánìkanwà? (b) Ìmọ̀ràn wo ni a fúnni láti ṣèrànwọ́ ní bíborí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara?

18 Òbí anìkàntọ́mọ kan dárò pé: “Bí mo bá ti délé, tí mo sì mọ̀ pé mo wà lémi nìkan, ní pàtàkì, bí àwọn ọmọ́ bá ti lọ sùn, mo máa ń nímọ̀lára ìdánìkanwà ní ti gidi.” Bẹ́ẹ̀ ni, ìdánìkanwà sábà ń jẹ́ ìṣòro títóbi jù lọ tí àwọn òbí anìkàntọ́mọ ń dojú kọ. Ó bá ìwà ẹ̀dá mu láti nífẹ̀ẹ́ sí ìbákẹ́gbẹ́ àti àjọṣepọ̀ ọlọ́yàyà tí ó wà nínú ìgbéyàwó. Ṣùgbọ́n ẹnì kan ha gbọ́dọ̀ yanjú ìṣòro yìí lọ́nàkọnà, láìka ohun tí yóò gbà sí bí? Nígbà ayé aposteli Paulu, àwọn opó kan tí wọ́n kéré ní ọjọ́ orí, fàyè gba “òòfà-ọkàn wọn fún ìbálòpọ̀ takọtabo [láti] wá sí àárín awọn ati Kristi.” (1 Timoteu 5:​11, 12) Fífàyè gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara láti bo ìfẹ́ ọkàn tẹ̀mí wa mọ́lẹ̀ yóò fa ìpalára.​—1 Timoteu 5:6.

19 Kristian ọkùnrin kan sọ pé: “Ìfẹ́ fún ìbálòpọ̀ lágbára gan-an, ṣùgbọ́n o lè kápá rẹ̀. Bí èrò náà bá wá sọ́kàn rẹ, má ṣe gbé e lé àyà. O gbọ́dọ̀ mú un kúrò. Ó tún ń ṣèrànwọ́ láti ronú nípa ọmọ rẹ.” Ọ̀rọ̀ Ọlọrun gbani nímọ̀ràn pé: ‘Sọ awọn ẹ̀yà ara rẹ tí ó jẹ́ ti ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo di òkú.’ (Kolosse 3:5) Bí o bá ń sapá láti sọ ìdálọ́rùn rẹ fún oúnjẹ di òkú, ìwọ yóò ha máa ka àwọn ìwé ìròyìn tí ń gbé àwọn àwòrán oúnjẹ aládùn jáde, tàbí ìwọ yóò ha máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń fìgbà gbogbo sọ̀rọ̀ nípa oúnjẹ? Rárá o! Bákan náà ni ó rí nípa àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara.

20. (a) Ewu wo ní ń bẹ fún àwọn tí ń fẹ́ aláìgbàgbọ́ sọ́nà? (b) Báwo ni àwọn tí wọ́n dá wà ní ọ̀rúndún kìíní àti lóde òní ṣe gbógun ti ìdánìkanwà?

20 Àwọn Kristian kan ti wọnú ìfẹ́sọ́nà pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́. (1 Korinti 7:39) Ìyẹ́n ha tán ìṣòro wọn bí? Rárá. Kristian obìnrin kan tí ó ṣèkọ̀sílẹ̀ kìlọ̀ pé: “Ohun kan tí ó burú ju àìṣègbéyàwó lọ ń bẹ. Ṣíṣègbéyàwó pẹ̀lú ẹni tí kò yẹni!” Láìsí iyè méjì, àwọn Kristian opó ní ọ̀rúndún kìíní nímọ̀lára ìdánìkanwà, ṣùgbọ́n ọwọ́ àwọn tí ó gbọ́n dí ‘nínú ṣíṣe awọn àjèjì lálejò, wíwẹ ẹsẹ̀ awọn ẹni mímọ́, àti mímú ìtura àlàáfíà bá awọn tí ń bẹ ninu ìpọ́njú.’ (1 Timoteu 5:10) Lónìí, ọwọ́ àwọn Kristian adúróṣinṣin, tí wọ́n ti fi ọ̀pọ̀ ọdún dúró láti rí alábàáṣègbéyàwó tí ó bẹ̀rù Ọlọrun, dí bákan náà. Opó Kristian ọlọ́dún 68 kan bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ àwọn opó mìíràn wò nígbàkigbà tí ó bá nímọ̀lára ìdánìkanwà. Ó sọ pé: “Mo rí i pé n kì í ní àkókò láti dá nìkan wà nígbà tí mo bá ń ṣe àwọn ìbẹ̀wò wọ̀nyí, tí mo bá ń ṣiṣẹ́ ilé, tí mo sì ń bójú tó ipò tẹ̀mí mi.” Kíkọ́ àwọn ẹlòmíràn nípa Ìjọba Ọlọrun jẹ́ iṣẹ́ rere kan tí ó ṣàǹfààní gidigidi.​—Matteu 28:​19, 20.

21. Lọ́nà wo ni àdúrà àti ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ rere fi lè ṣèrànwọ́ láti borí ìdánìkanwà?

21 A gbà pé kò sí ìwòsàn oníṣẹ́ ìyanu fún ìdánìkanwà. Ṣùgbọ́n a lè fara dà á pẹ̀lú okun tí Jehofa ń pèsè. Irú okun bẹ́ẹ̀ ń wá nígbà tí Kristian kan bá “tẹpẹlẹ mọ́ ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ ati àdúrà lóru ati lọ́sàn-án.” (1 Timoteu 5:5) Ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ ni ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ onífọkànsí, àní bíbẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́, bóyá pẹ̀lú igbe ẹkún kíkankíkan àti omijé pàápàá. (Fi wé Heberu 5:7.) Títú ọkàn rẹ jáde fún Jehofa “lóru ati lọ́sàn-án” lè ṣèrànwọ́ gidigidi. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ gbígbámúṣé lè ṣe púpọ̀ láti dí ìmọ̀lára àlàfo ṣíṣísílẹ̀ ti ìdánìkanwà. Nípa ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ rere, ẹnì kan lè rí “ọ̀rọ̀ rere” oníṣìírí tí a ṣàpèjúwe nínú Owe 12:25.

22. Àwọn nǹkan wo ni a lè gbé yẹ̀ wò, tí yóò ranni lọ́wọ́, bí ìmọ̀lára ìdánìkanwà bá ń yọjú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan?

22 Bí ìmọ̀lára ìdánìkanwà bá ń yọjú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan​—bí ó ti ṣeé ṣe kí wọ́n ṣe—​máa rántí pé kò sí ẹni tí kò ní ìṣòro nínú ìgbésí ayé. Ní ti gidi, ‘gbogbo ẹgbẹ́ awọn arákùnrin rẹ ninu ayé’ ń jìyà lọ́nà kan tàbí òmíràn. (1 Peteru 5:9) Yẹra fún ríronú nípa àwọn ìgbà tí ó ti kọjá. (Oniwasu 7:10) Bojú wo àwọn àǹfààní tí o ń gbádùn. Jù gbogbo rẹ̀ lọ, pinnu láti di ìwà títọ́ rẹ mú àti láti mú inú Jehofa dùn.​—Owe 27:11.

BÍ ÀWỌN ẸLÒMÍRÀN ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́

23. Àìgbọdọ̀máṣe wo ni àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ ẹni ní síhà àwọn òbí anìkàntọ́mọ nínú ìjọ?

23 A ko gbọdọ̀ kóyán ìtìlẹ́yìn àti ìrànlọ́wọ́ àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ ẹni kéré. Jakọbu 1:27 wí pé: “Irú ọ̀nà-ètò ìjọsìn tí ó mọ́ tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin ní ojú-ìwòye Ọlọrun ati Baba wa ni èyí: lati máa bójútó awọn ọmọ òrukàn ati awọn opó ninu ìpọ́njú wọn.” Bẹ́ẹ̀ ni, ó jẹ́ àìgbọdọ̀máṣe fún àwọn Kristian láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ìdílé olóbìí kan. Kí ni díẹ̀ nínú àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ tí a lè gbà ṣe èyí?

24. Ní àwọn ọ̀nà wo ni a ti lè ran àwọn ìdílé olóbìí kan tí ó ṣaláìní lọ́wọ́?

24 A lè ṣèrànwọ́ ohun ìní. Bibeli wí pé: “Ẹni yòówù tí ó bá ní àlùmọ́ọ́nì ayé yii fún ìtìlẹyìn ìgbésí-ayé tí ó sì rí i tí arákùnrin rẹ̀ ṣe aláìní síbẹ̀ tí ó sì sé ilẹ̀kùn ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ rẹ̀ mọ́ ọn, ní ọ̀nà wo ni ìfẹ́ fún Ọlọrun fi dúró ninu rẹ̀?” (1 Johannu 3:17) Ògidì ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì fún “rí” kò túmọ̀ sí wíwulẹ̀ kófìrí lásán, bí kò ṣe kíkíyè sí pẹ̀lú ìtẹjúmọ́. Èyí tọ́ka sí i pé Kristian onínúure kan lè kọ́kọ́ mọ̀ nípa ipò àti àìní ìdílé kan. Bóyá wọ́n ṣàìní owó. Àwọn kan lè nílò ìrànwọ́ nínu ṣíṣe àtúnṣe inú ilé. Tàbí wọ́n wulẹ̀ lè mọrírì kíké sí wọn síbi oúnjẹ tàbí àpéjọpọ̀ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà kan.

25. Báwo ni àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ ẹni ṣe lè fi ìyọ́nú hàn sí àwọn òbí anìkàntọ́mọ?

25 Ní àfikún sí i, 1 Peteru 3:8 sọ pé: “Gbogbo yín ẹ jẹ́ onínú kan naa, kí ẹ máa fi ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn, kí ẹ máa ní ìfẹ́ni ará, kí ẹ máa fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn.” Òbí anìkàntọ́mọ kan tí ó lọ́mọ mẹ́fà sọ pé: “Kò rọrùn, mo sì máa ń soríkọ́ nígbà míràn. Àmọ́, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, arákùnrin tàbí arábìnrin kan yóò sọ fún mi pé: ‘Joan, o ń gbìyànjú gan-an ni. Yóò kúkú dára.’ Wíwulẹ̀ mọ̀ pé àwọn mìíràn ń ronú nípa rẹ, pé wọ́n sì bìkítà, ń ṣèrànwọ́ púpọ̀.” Ní pàtàkì, àwọn Kristian àgbà obìnrin lè gbéṣẹ́ ní ṣíṣèrànwọ́ fún àwọn obìnrin òbí anìkàntọ́mọ tí wọn kò fi bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ lórí, nípa fífetí sí wọn nígbà tí wọ́n bá ní ìṣòro tí ó lè ṣòro fún wọn láti bá ọkùnrin jíròrò.

26. Báwo ni àwọn Kristian ọkùnrin adàgbàdénú ṣe lè ran àwọn ọmọ aláìníbaba lọ́wọ́?

26 Àwọn Kristian ọkùnrin lè ṣèrànwọ́ ní àwọn ọ̀nà míràn. Jobu, ọkùnrin olóòótọ́, sọ pé: “Mo gba . . . aláìníbaba, àti aláìní olùrànlọ́wọ́.” (Jobu 29:12) Lọ́nà kan náà, àwọn Kristian ọkùnrin kan lónìí ń fi ọkàn ìfẹ́ tòótọ́ hàn nínú àwọn ọmọ aláìníbaba, wọ́n sì ń fi ojúlówó “ìfẹ́ lati inú ọkàn-àyà tí ó mọ́” hàn, láìní ète ìsúnniṣe abẹ́nú kankan. (1 Timoteu 1:5) Láìpa ìdílé àwọn tìkalára wọn tì, wọ́n lè ṣètò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti bá àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristian, kí wọ́n sì tún ké sí wọn láti nípìn-ín nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tàbí eré ìnàjú pẹ̀lú. Irú inú rere bẹ́ẹ̀ lè gba ọmọ aláìníbaba kan lọ́wọ́ ipa ọ̀nà ìṣìnà pàápàá.

27. Ìtìlẹ́yìn wo ni a lè mú dá àwọn òbí anìkàntọ́mọ lójú?

27 Dájúdájú, ní paríparí rẹ̀, àwọn òbí anìkàntọ́mọ ní láti ‘ru ẹrù ara wọn.’ (Galatia 6:5) Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n lè jàǹfààní ìfẹ́ àwọn Kristian arákùnrin àti arábìnrin àti ti Jehofa Ọlọrun fúnra rẹ̀. Bibeli sọ nípa rẹ̀ pé: “Ó tu àwọn aláìníbaba àti opó lára.” (Orin Dafidi 146:9) Pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́ Rẹ̀, àwọn ìdílé olóbìí kan lè kẹ́sẹ járí!

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bí Kristian ọ̀dọ́ kan bá gboyún láti inú ìwà pálapàla, ìjọ Kristian kò jẹ́ fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ohun tí ó ṣe lọ́nàkọnà. Ṣùgbọ́n, bí ó bá ronú pìwà dà, àwọn alàgbà ìjọ àti àwọn mìíràn nínú ìjọ lè fẹ́ láti ràn án lọ́wọ́.

b Àwọn ipò tí ọmọ kan ti nílò ìdáàbòbò lọ́wọ́ òbí tí ń lò ó nílòkulò kọ́ ni a ń sọ̀rọ̀ lé lórí. Bákan náà, bí òbí kejì bá ń sapá láti mú kí ọlá àṣẹ rẹ yìnrìn, bóyá pẹ̀lú èrò láti mú kí àwọn ọmọ fi ọ́ sílẹ̀, ó dára kí o bá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí ó nírìírí, bí àwọn alàgbà nínú ìjọ Kristian, sọ̀rọ̀ fún ìmọ̀ràn lórí bí o ṣe lè kojú ipò náà.

BÁWO NI ÀWỌN ÌLÀNÀ BIBELI WỌ̀NYÍ ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́ FÚN . . . ÀWỌN ÒBÍ ÀTI ÀWỌN ỌMỌ LÁTI KOJÚ ÀWỌN ÌṢÒRO ÌDÍLÉ OLÓBÌÍ KAN?

Jehofa Ọlọrun jẹ́ “baba àwọn aláìníbaba àti onídàájọ́ àwọn opó.”—Orin Dafidi 68:5.

Ìwéwèé yíyẹ ṣe kókó fún ìkẹ́sẹjárí.​—Owe 21:5.

Jehofa ń ti ẹ̀tọ́ òbí láti fúnni ní ìbáwí yíyẹ lẹ́yìn.​—Owe 1:8.

Ọwọ́ àwọn Kristian opó tí ó gbọ́n ń dí nínú àwọn iṣẹ́ ìwà-bí-Ọlọ́run, wọ́n sì ń tẹpẹlẹ mọ́ àdúrà gbígbà.—1 Timoteu 5:​5, 10.

Níní ìfẹ́ ọkàn yíyẹ nínú “awọn ọmọ òrukàn àti awọn opó” jẹ́ ara ìjọsìn tòótọ́.​—Jakọbu 1:27.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 112]

OHUN TÍ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ LÈ ṢE

Ṣé òbí anìkàntọ́mọ ni bàbá tàbí ìyá rẹ? Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, ìrànwọ́ wo ni o lè ṣe? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, jẹ́ onígbọràn. Ìrísí tàbí ẹ̀yà ẹ̀dá ọmọ kan kò fún un lómìnira láti ‘kọ òfin ìyá rẹ̀ sílẹ̀.’ (Owe 1:8) Jehofa pàṣẹ fún ọ láti jẹ́ onígbọràn, ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò sì fún ọ láyọ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.​—Owe 23:22; Efesu 6:​1-3.

Máa lo àtinúdá, sì jẹ́ onímọrírì. Tony wí pé: “Màmá mi ń ṣiṣẹ́ nílé ìwòsàn, aṣọ iṣẹ́ rẹ̀ sì yẹ ní lílọ̀. Nítorí náà, mo ń bá a lọ̀ ọ́. Ó jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún màmá mi, nítorí náà, mo ń ṣe é.” Ìyá anìkàntọ́mọ kan sọ pé: “Mo sábà máa ń rí i pé, nígbà tí mo bá fi délé ní àwọn ọjọ́ tí iṣẹ́ bá pá mi lórí, tí ó rẹ̀ mí gan-an, tí inú sì ń bí mi​—irú ọjọ́ bẹ́ẹ̀ ni ọmọbìnrin mi ti máa ń gbọ́únjẹ, yóò sì ti gbé e sórí tábìlì.”

Fi sọ́kàn pé, ìfọwọ́sowọ́pọ̀ rẹ ṣe pàtàkì. Ó lè nira fún òbí rẹ láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ìdílé lẹ́yìn iṣẹ́ ojúmọ́ kan tí ó gbomi. Bí o kì í bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀, o ń mú nǹkan burú sí i ni. Sapá láti múra tán nígbà tí yóò bá fi tó àkókò tí ẹ ṣètò sí. Múra àwọn ẹ̀kọ́ rẹ sílẹ̀ ṣáájú. Nípa jíjẹ́ onígbọràn, onímọrírì, olùfọwọ́sowọ́pọ̀, ìwọ yóò tẹ́ òbí rẹ lọ́rùn, jù bẹ́ẹ̀ lọ ní pàtàkì, ìwọ yóò tẹ́ Ọlọrun lọ́rùn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 107]

Lo àkókò púpọ̀ bí ó bá ti ṣeé ṣe tó pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 109]

Ẹ̀yin ọmọ, ẹ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú òbí yín anìkàntọ́mọ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 110]

Ìjọ kì í ṣá “àwọn opó” àti “àwọn aláìníbaba” tì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́