Ṣọ́ra fún ‘Àwọn Epikúréì’
“Ó ṣe ọmọlúwàbí gan-an! Ó ń tẹ̀ lé ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga ní ti ìwà híhù. Kì í mu sìgá, kì í joògùn yó, kì í sì í sọ̀rọ̀ ọ̀bùn. Àní, ó ṣọmọlúwàbí ju àwọn mìíràn tí wọ́n pe ara wọn ní Kristẹni pàápàá lọ!”
ÌWỌ ha ti gbọ́ tí àwọn kan lo irú èrò bẹ́ẹ̀ láti fi hàn pé kò sí ohun tí ó burú nínú ọ̀rẹ́ tí wọ́n ń bá kẹ́gbẹ́ bí? Ó ha lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ lójú Ìwé Mímọ́ bí? Àpẹẹrẹ kan láti inú ìjọ Kristẹni ìjímìjí yóò mú kí ọ̀ràn yí túbọ̀ ṣe kedere sí i.
Ní ọ̀rúndún kìíní, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún ìjọ Kọ́ríńtì pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ṣì yín lọ́nà. Àwọn ẹgbẹ́ búburú a máa ba àwọn àṣà ìhùwà wíwúlò jẹ́.” Ó lè jẹ́ pé, àwọn Kristẹni kan ń ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú àwọn kan tí ọgbọ́n èrò orí Gíríìkì, títí kan àwọn Epikúréì, ti nípa lé lórí. Àwọn wo ni àwọn Epikúréì? Èé ṣe ti wọ́n fi lè jẹ́ ewu ńláǹlà fún ipò tẹ̀mí àwọn Kristẹni tí ń bẹ ní Kọ́ríńtì? Àwọn ènìyàn bíi tiwọn ha wà lónìí, tí ó yẹ kí a ṣọ́ra fún bí?—Kọ́ríńtì Kíní 15:33.
Àwọn Wo Ni Àwọn Epikúréì?
Àwọn Epikúréì jẹ́ àwọn ọmọlẹ́yìn ọlọ́gbọ́n èrò orí Gíríìkì náà, Epicurus, tí ó gbé ayé ní ọdún 341 sí 270 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ó kọ́ni pé adùn ni ohun pàtàkì jù lọ tàbí lájorí ohun rere nínú ìgbésí ayé. Ìyẹn ha túmọ̀ sí pé àwọn Epikúréì gbé ìgbésí ayé akótìjúbáni, aláìnípinnu, tí wọn ń lọ́wọ́ nínú àwọn ìwà tí ń rẹni nípò wálẹ̀ bí wọ́n ṣe ń wá fàájì kiri bí? Ó yani lẹ́nu pé, Epicurus kò kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbé irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀! Kàkà bẹ́ẹ̀, ó kọ́ni pé, lílo làákàyè, ìgboyà, ìkóra-ẹni-níjàánu, àti ìdájọ́ òdodo ni ọ̀nà gíga jù lọ tí ẹnì kan lè gbà rí adùn. Ó ṣalágbàwí ìlépa adùn tí ẹnì kan yóò ní jálẹ̀ àkókò ìgbésí ayé, kì í ṣe adùn ojú ẹsẹ̀ àti ti ìgbà díẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn Epikúréì lè jẹ́ oníwà funfun lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn oníwà funfun.—Fi wé Títù 1:12.
Ìgbàgbọ́ Wọn Ha Bá Ti Ẹ̀sìn Kristẹni Dọ́gba Bí?
Ká ní o jẹ́ mẹ́ńbà ìjọ Kọ́ríńtì ìjímìjí, ìwà àwọn Epikúréì yóò ha ti wú ọ lórí bí? Àwọn kan ti lè rò pé ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga tí ó dà bíi pé àwọn Epikúréì ń tẹ̀ lé, lè mú kí wọ́n jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ rere fún àwọn Kristẹni. Ní ríronú lọ́nà òdì síwájú sí i, àwọn ará Kọ́ríńtì ti lè kíyè sí àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n tí ó dà bíi pé ó jọra nínú ti àwọn Epikúréì àti ti Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Fún àpẹẹrẹ, àwọn Epikúréì ń lo ìwọ̀ntúnwọ̀nsì bí wọ́n ṣe ń lépa adùn. Wọ́n ka inú dídùn sí ohun pàtàkì ju adùn ti ara lọ. Oúnjẹ tí ẹnì kan jẹ kò ṣe pàtàkì tó ipò ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú ẹni tí wọ́n jọ jẹ ẹ́. Àní, àwọn Epikúréì kì í lọ́wọ́ nínú ọ̀ràn ìṣèlú, wọ́n kì í sì í yọ́lẹ̀ hùwà àìtọ́. Ẹ wo bí yóò ti rọrùn tó láti gbà pé: “Kò sí ohun tí wọ́n fi yàtọ̀ sí wa!”
Ṣùgbọ́n, òtítọ́ ha ni pé àwọn Epikúréì kò yàtọ̀ sí àwọn Kristẹni ìjímìjí bí? Rárá o. Àwọn tí wọ́n ní agbára ìwòye tí a kọ́ dáradára lè rí àwọn ìyàtọ̀ gígadabú náà. (Hébérù 5:14) Ìwọ ha lè rí i bí? Ẹ jẹ́ kí a wo ẹ̀kọ́ Epicurus láwòfín.
Ìhà Búburú Tí Ọgbọ́n Èrò Orí Epicurus Ní
Láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti borí ìbẹ̀rù àwọn ọlọ́run àjúbàfún àti ikú, Epicurus kọ́ni pé, àwọn ọlọ́run kò nífẹ̀ẹ́ nínú aráyé, wọn kì í sì í dá sí àlámọ̀rí ẹ̀dá ènìyàn. Gẹ́gẹ́ bí Epicurus ti sọ, kì í ṣe àwọn ọlọ́run ni ó dá àgbáálá ayé, ìwàláàyè kan ṣèèṣì bẹ̀rẹ̀ ni. Èyí kò ha forí gbárí pẹ̀lú ẹ̀kọ́ Bíbélì pé, “Ọlọ́run kan” ní ń bẹ, Ẹlẹ́dàá, àti pé ó bìkítà nípa àwọn ènìyàn tí ó ṣẹ̀dá?—Kọ́ríńtì Kíní 8:6; Éfésù 4:6; Pétérù Kíní 5:6, 7.
Epicurus tún kọ́ni pé kò lè sí ìwàláàyè kankan lẹ́yìn ikú. Dájúdájú, èyí ta ko ẹ̀kọ́ Bíbélì nípa àjíǹde. Àní, nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ ní Áréópágù, ó ṣeé ṣe kí àwọn Epikúréì wà lára àwọn tí ó bá Pọ́ọ̀lù jiyàn lórí ìgbàgbọ́ nípa àjíǹde.—Ìṣe 17:18, 31, 32; Kọ́ríńtì Kíní 15:12-14.
Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé apá tí ó léwu jù lọ nínú ọgbọ́n èrò orí Epicurus ni ó tún jẹ́ apá tí ó ṣòro jù lọ láti tètè fura sí. Gbígbà tí kò gbà pé pípadà wà láàyè ṣeé ṣe ni ó sún un dé orí èrò náà pé ó yẹ kí ènìyàn gbádùn ayé rẹ̀ bí ó ba ti lè ṣeé ṣe tó ní ìwọ̀nba àkókò tí yóò fi wà lórí ilẹ̀ ayé. Gẹ́gẹ́ bí àwa náà ti rí i, èrò rẹ̀ kì í kúkú ṣe láti gbé ìgbésí ayé ẹlẹ́ṣẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ láti jayé òní, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé òní nìkan náà ni a ní.
Nípa báyìí, Epicurus kò rọni láti máa yọ́lẹ̀ hùwà àìtọ́ nítorí ìbẹ̀rù títúnifó, tí ó jẹ́ ewu tí ó dájú fún ayọ̀ òní. Ó rọni láti jẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì láti lè yẹra fún ohun tí ìkẹ́ra-ẹni-bà-jẹ́ ń yọrí sí, ohun mìíràn tí ó lè dènà ayọ̀ òní. Ó tún rọni láti ní ipò ìbátan dídán mọ́rán pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, nítorí ère rẹ̀ yóò ṣeni láǹfààní. Dájúdájú, yíyẹra fún yíyọ́lẹ̀ hùwà àìtọ́, ṣíṣe nǹkan níwọ̀ntúnwọ̀nsì, àti bíbáni dọ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ìwà rere. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, èé ṣe tí ọgbọ́n èrò orí Epicurus fi léwu fún àwọn Kristẹni? Nítorí pé ó gbé ìmọ̀ràn rẹ̀ ka ojú ìwòye aláìnígbàgbọ́ tí ó ní, ìyẹn ni pé: “Ẹ jẹ́ kí á máa jẹ kí a sì máa mu, nítorí ní ọ̀la àwa yóò kú.”—Kọ́ríńtì Kíní 15:32.
Lóòótọ́, Bíbélì fi bí àwọn ènìyàn ṣe lè gbé ìgbésí ayé aláyọ̀ nísinsìnyí hàn wọ́n. Ṣùgbọ́n, ó gbani nímọ̀ràn pé: “Ẹ pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, bí ẹ ti ń dúró de àánú Olúwa wa Jésù Kristi pẹ̀lú ìyè àìnípẹ̀kun níwájú.” (Júúdà 21) Bẹ́ẹ̀ ni, ọjọ́ ọ̀la ayérayé ni Bíbélì tẹnu mọ́ lọ́nà gíga, kì í ṣe ọjọ́ òní tí ń yára kọjá lọ. Fún Kristẹni kan, sísin Ọlọ́run ni olórí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀, ó sì ń rí i pé nígbà tí òun bá fi Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́, òun ń láyọ̀, òun sì ń ní ìtẹ́lọ́rùn. Lọ́nà kan náà, Jésù, dípò tí ì bá fi jẹ́ kí ìfẹ́ ọkàn tirẹ̀ gbà á lọ́kàn, ó lo okun rẹ̀ láìmọ tara rẹ̀ nìkan, ní sísin Jèhófà àti ní ríran àwọn ènìyàn lọ́wọ́. Ó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti ṣoore fún àwọn ẹlòmíràn, kì í ṣe pẹ̀lú ìrètí pé kí àwọn tọ̀hún lè san án pa dà, ṣùgbọ́n láti inú ojúlówó ìfẹ́ tí wọ́n ní sí wọn. Ó ṣe kedere pé, olórí ohun tí ń súnni ṣiṣẹ́ nínú ọgbọ́n èrò orí Epicurus àti ẹ̀sìn Kristẹni yàtọ̀ síra pátápátá.—Máàkù 12:28-31; Lúùkù 6:32-36; Gálátíà 5:14; Fílípì 2:2-4.
Ewu Kan Tí A Kò Lè Tètè Fura Sí
Lọ́nà títakora, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Epikúréì gbé jíjẹ́ aláyọ̀ gẹ̀gẹ̀ tó bẹ́ẹ̀, ayọ̀ wọn kì í ṣe èyí tí ó wà pẹ́ títí. Nítorí tí kò ní “ayọ̀ Olúwa,” Epicurus pe ìgbésí ayé ní “ẹ̀bùn bíbaninínújẹ́.” (Nehemáyà 8:10) Ẹ wo bí àwọn Kristẹni ìjímìjí ti láyọ̀ tó ní ìfiwéra! Kì í ṣe ìgbésí ayé ìfi-nǹkan-dura-ẹni, tí kì í mú ayọ̀ wá ni Jésù gbani nímọ̀ràn láti gbé. Ní tòótọ́, títẹ̀lé ìlànà rẹ̀ ni a fi lè rí ayọ̀ títóbi jù lọ.—Mátíù 5:3-12.
Bí àwọn kan tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà ìjọ Kọ́ríńtì bá rò pé àwọn lè máa ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú àwọn tí ìrònú àwọn Epikúréì ti nípa lé lórí, tí èyí kò sì ní fi ìgbàgbọ́ wọn sínú ewu, àṣìṣe ńlá gbáà ni wọ́n ń ṣe. Ní àkókò tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sí àwọn ará Kọ́ríńtì, àwọn kan lára wọn ti sọ ìgbàgbọ́ nù nínú àjíǹde.—Kọ́ríńtì Kíní 15:12-19.
Ọgbọ́n Èrò Orí Epicurus Ha Wà Lónìí Bí?
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọgbọ́n èrò orí Epicurus pòórá ní ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Tiwa, àwọn kan ń bẹ lónìí tí wọ́n ní ojú ìwòye kan náà, ti màá-jayé-òní. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí kò ní ìgbàgbọ́ kankan nínú ìlérí Ọlọ́run nípa ìyè ayérayé. Síbẹ̀, àwọn kan lára wọn ní ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga ní ti ìwà híhù dé ìwọ̀n àyè kan.
Kristẹni kan lè kó sí ìdẹwò ti ṣíṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, bóyá ní ríronú pé ìwà ọmọlúwàbí tí wọ́n ní, mú kí bíbá wọn dọ́rẹ̀ẹ́ tọ̀nà. Ṣùgbọ́n, bí a kò tilẹ̀ ní ka ara wa sí ẹni tí ìwà rẹ̀ ta ti àwọn yòó kù yọ, a gbọ́dọ̀ ní i lọ́kàn pé gbogbo “ẹgbẹ́ búburú”—títí kan àwọn tí a kò lè tètè fura sí ipa tí wọ́n ń ní lórí ẹni—“a máa ba àwọn àṣà ìhùwà wíwúlò jẹ́.”
Ọgbọ́n èrò orí màá-jayé-òní tún ń jẹyọ nínú àwọn àpérò okòwò, àwọn ìwé tí ń pèsè ìmọ̀ràn bí-a-tií-ṣe-é, ìwé ìtàn, sinimá, ètò orí tẹlifíṣọ̀n, àti orin. Bí wọn kò tilẹ̀ gbé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ lárugẹ ní tààràtà, ojú ìwòye aláìnígbàgbọ́ yìí ha lè nípa lórí wa lọ́nà tí a kò lè tètè fura sí bí? Fún àpẹẹrẹ, ìtẹ́ra-ẹni-lọ́rùn ha lè gbà wá lọ́kàn débi pé a gbàgbé ọ̀ràn ipò ọba aláṣẹ Jèhófà bí? A ha lè fà wá kúrò lójú ọ̀nà sínú dídi ẹni tí ó ní ẹ̀mí ‘dẹ̀-ẹ́-jẹ́jẹ́,’ dípò kí a jẹ́ ẹni tí ó ní ẹ̀mí ‘níní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa’ bí? Àbí a lè ṣì wá lọ́nà sínú ṣíṣiyèméjì nípa bóyá àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Jèhófà tọ́ tàbí kò tọ́ àti bóyá ó ń ṣeni láǹfààní tàbí kì í ṣeni láǹfààní? A ní láti ṣọ́ra kí ìwà pálapàla ní ti gidi, ìwà ipá, àti ìbẹ́mìílò àti ojú ìwòye ti ayé má ṣe nípa lé wa lórí!—Kọ́ríńtì Kíní 15:58; Kólósè 2:8.
Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a máa kẹ́gbẹ́ pọ̀, ní pàtàkì, pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà tọkàntọkàn. (Aísáyà 48:17) Ohun tí yóò yọrí sí ni pé, a óò fún ìwà rere wa lókun. A óò gbé ìgbàgbọ́ wa ró. A óò gbé ìgbésí ayé aláyọ̀ nísinsìnyí àti ní ọjọ́ ọ̀la, a óò tún máa fojú sọ́nà fún ìyè àìnípẹ̀kun.—Orin Dáfídì 26:4, 5; Òwe 13:20.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Epicurus kọ́ni pé àwọn ọlọ́run kò nífẹ̀ẹ́ nínú aráyé
[Credit Line]
Ìyọ̀nda Onínúure ti The British Museum